-
“Ẹ Tu Àwọn Ènìyàn Mi Nínú”Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
-
-
5, 6. (a) Èé ṣe tí jíjìn tí ọ̀nà jìn láti Bábílónì sí Jerúsálẹ́mù kò fi ní ṣèdíwọ́ fún ìmúṣẹ ìlérí Ọlọ́run? (b) Ipa wo ni ìmúbọ̀sípò àwọn Júù sí ìlú ìbílẹ̀ wọn yóò ní lórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù?
5 Ìrìn ẹgbẹ̀rin sí ẹgbẹ̀jọ kìlómítà ni wọn yóò rìn láti Bábílónì sí Jerúsálẹ́mù, ó sinmi lórí ọ̀nà tí wọ́n bá gbà. Ṣé jíjìn tí ọ̀nà yẹn jìn yóò wá ṣèdíwọ́ fún ìmúṣẹ ìlérí Ọlọ́run? Àgbẹdọ̀! Aísáyà kọ̀wé pé: “Ẹ fetí sílẹ̀! Ẹnì kan ń ké ní aginjù: ‘Ẹ tún ọ̀nà Jèhófà ṣe! Ẹ mú kí òpópó fún Ọlọ́run wa, èyí tí ó la pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ kọjá, jẹ́ títọ́. Gbogbo àfonífojì ni kí a gbé sókè, gbogbo òkè ńlá àti òkè kéékèèké sì ni kí a sọ di rírẹlẹ̀. Ilẹ̀ págunpàgun sì gbọ́dọ̀ di ilẹ̀ títẹ́jú pẹrẹsẹ, ilẹ̀ kángunkàngun sì gbọ́dọ̀ di pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì. Dájúdájú, a ó sì ṣí ògo Jèhófà payá, gbogbo ẹran ara yóò sì rí i pa pọ̀, nítorí pé ẹnu Jèhófà gan-an ni ó sọ ọ́.’”—Aísáyà 40:3-5.
6 Kí àwọn ọba ìhà Ìlà Oòrùn Ayé tó gbéra ìrìn àjò, wọ́n sábà máa ń rán àwọn èèyàn lọ tún ọ̀nà ṣe nípa kíkó àwọn òkúta ńláńlá kúrò, wọn a tilẹ̀ tẹ́ afárá, wọn a sì sọ àwọn òkè kéékèèké di ibi tó tẹ́jú. Ní ti àwọn Júù tó ń padà bọ̀ wálé yìí, ńṣe ni yóò rí bí ẹni pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló ṣáájú wọn, tó ń kó gbogbo ohun ìdìgbòlù kúrò lọ́nà. Ó ṣe tán, Jèhófà ni wọ́n ń jẹ́ orúkọ mọ́, ńṣe ni ìmúṣẹ ìlérí tó ṣe pé òun yóò mú wọn padà bọ̀ sí ìlú ìbílẹ̀ wọn yóò mú kí ògo rẹ̀ hàn kedere sí gbogbo orílẹ̀-èdè. Bí àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn fẹ́ bí wọ́n kọ̀ o, wọn yóò rí i ní túláàsì pé Jèhófà ni Ẹni tí ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ.
7, 8. (a) Ìmúṣẹ wo ni ọ̀rọ̀ Aísáyà 40:3 ní ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa? (b) Ìmúṣẹ tó gbòòrò wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ní lọ́dún 1919?
7 Ìmúbọ̀sípò ti ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa nìkan kọ́ ni ìmúṣẹ tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní. Ó tún ṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa pẹ̀lú. Jòhánù Oníbatisí ni ohùn ẹnì kan tí “ń ké jáde ní aginjù,” ní ìmúṣẹ Aísáyà 40:3. (Lúùkù 3:1-6) Jòhánù sì lo ọ̀rọ̀ Aísáyà fún ara rẹ̀ nípa ìmísí. (Jòhánù 1:19-23) Ọdún 29 Sànmánì Tiwa ni Jòhánù ti bẹ̀rẹ̀ sí palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún Jésù Kristi.a Ṣe ni kíkéde tí Jòhánù ti kéde ṣáájú mú kí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí wá Mèsáyà táa ti ṣèlérí náà, kí àwọn náà lè gbọ́rọ̀ rẹ̀ kí wọ́n sì tẹ̀ lé e. (Lúùkù 1:13-17, 76) Jèhófà yóò wá lo Jésù láti ṣamọ̀nà àwọn tó ronú pìwà dà lọ sínú òmìnira tó jẹ́ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè fúnni, ìyẹn ìdáǹdè kúrò nínú ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Jòhánù 1:29; 8:32) Ọ̀rọ̀ Aísáyà ṣẹ lọ́nà tó túbọ̀ gbòòrò sí i nígbà tí àwọn àṣẹ́kù Ísírẹ́lì tẹ̀mí rí ìdáǹdè gbà kúrò nínú Bábílónì Ńlá lọ́dún 1919, àti nígbà ìmúbọ̀sípò wọn sínú ìjọsìn tòótọ́.
-
-
“Ẹ Tu Àwọn Ènìyàn Mi Nínú”Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
-
-
a Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa pípalẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún Jèhófà. (Aísáyà 40:3) Ṣùgbọ́n àwọn ìwé Ìhìn Rere lo àsọtẹ́lẹ̀ yẹn fún ohun tí Jòhánù Oníbatisí ṣe, bó ṣe ń palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún Jésù Kristi. Ohun tó jẹ́ kí àwọn òǹkọ̀wé onímìísí tó kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì lò ó lọ́nà bẹ́ẹ̀ ni pé ńṣe ni Jésù ṣojú fún Bàbá rẹ̀, tó sì tún wá lórúkọ Bàbá rẹ̀.—Jòhánù 5:43; 8:29.
-