ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Wákàtí Rẹ̀ Kò Tíì Dé”
    Ilé Ìṣọ́—2000 | September 15
    • 17. (a) Iṣẹ́ pàjáwìrì wo ni wọ́n rán sí Jésù bó ṣe ń wàásù ní Pèríà? (b) Kí ló fi hàn pé Jésù mọ ète ìgbésẹ̀ tóun gbọ́dọ̀ gbé àti àkókò tí àwọn nǹkan gbọ́dọ̀ wáyé?

      17 Màtá àti Màríà, ìyẹn àwọn arábìnrin Lásárù, tí ń gbé ní Bẹ́tánì ti Jùdíà, ló rán iṣẹ́ pàjáwìrì ọ̀hún. Ońṣẹ́ náà ròyìn pé: “Olúwa, wò ó! ẹni tí ìwọ ní ìfẹ́ni fún ń ṣàìsàn.” Jésù fèsì pé: “Ikú kọ́ ni ìgbẹ̀yìn àìsàn yìí, ṣùgbọ́n ó jẹ́ fún ògo Ọlọ́run, kí a lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.” Láti lè mú ète yìí ṣẹ, Jésù mọ̀ọ́mọ̀ dúró síbi tó wà fún ọjọ́ méjì. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ló wá sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí a tún lọ sí Jùdíà.” Kàyéfì gbáà lèyí jẹ́ fún wọn, ni wọ́n bá dáhùn pé: “Rábì, àìpẹ́ yìí ni àwọn ará Jùdíà ń wá ọ̀nà láti sọ ọ́ ní òkúta, ìwọ ha sì tún ń lọ sí ibẹ̀ bí?” Ṣùgbọ́n Jésù mọ̀ pé ìyókù ‘wákàtí ojúmọmọ,’ ìyẹn àkókò tí Ọlọ́run yàn kálẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun lórí ilẹ̀ ayé, ti fẹ́ parí. Ó mọ ohun náà gan-an tó yẹ kóun ṣe àti ìdí tóun fi gbọ́dọ̀ ṣe é.—Jòhánù 11:1-10.

  • “Wákàtí Rẹ̀ Kò Tíì Dé”
    Ilé Ìṣọ́—2000 | September 15
    • 21. Iṣẹ́ ìyanu àjíǹde Lásárù jẹ́ àkókò ìyípadà wo?

      21 Bó ṣe jẹ́ nìyẹn o, tó fi di pé nítorí àìtètèdé sí Bẹ́tánì, ó ṣeé ṣe fún Jésù láti ṣe iṣẹ́ ìyanu tí ẹnikẹ́ni kò lè fojú pa rẹ́. Nípasẹ̀ agbára tí Ọlọ́run fún Jésù, ó jí ọkùnrin kan tó ti kú fún ọjọ́ mẹ́rin dìde. Kódà ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn ọlọ́lá kò lè sẹ́ iṣẹ́ ìyanu náà, ṣebí ìyẹn ló jẹ́ kí wọ́n dá ẹjọ́ ikú fún Oníṣẹ́ Ìyanu náà! Iṣẹ́ ìyanu náà wá tipa báyìí dúró gẹ́gẹ́ bí ohun tó mú àkókò ìyípadà ńlá bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù—ìyẹn ìyípadà láti ìgbà tí “wákàtí rẹ̀ kò tíì dé” sí ìgbà tí “wákàtí náà ti dé.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́