-
Ẹni Tó Mọ Ìnira WaIlé Ìṣọ́—2008 | May 1
-
-
Nígbà tí ikú dá ẹ̀mí Lásárù ọ̀rẹ́ Jésù légbodò, Jésù lọ sí abúlé táwọn arábìnrin Lásárù ń gbé. Ó dájú pé ìbànújẹ́ ńlá ni ikú Lásárù jẹ́ fáwọn arábìnrin rẹ̀, Màríà àti Màtá. Jésù nífẹ̀ẹ́ ìdílé yìí gan-an ni. (Jòhánù 11:5) Kí ni Jésù máa wá ṣe? Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí [Jésù] rí i tí [Màríà] ń sunkún àti àwọn Júù tí wọ́n bá a wá tí wọ́n ń sunkún, ó kérora nínú ẹ̀mí, ó sì dààmú; ó sì wí pé: ‘Ibo ni ẹ tẹ́ ẹ sí?’ Wọ́n wí fún un pé: ‘Olúwa, wá wò ó.’ Jésù bẹ̀rẹ̀ sí da omijé.” (Jòhánù 11:33-35) Kí nìdí tí Jésù fi sunkún? Òótọ́ ni pé Lásárù ọ̀rẹ́ Jésù àtàtà kú, àmọ́ ó máa tó jí i dìde. (Jòhánù 11:41-44) Kí ló wá mú kí Jésù sunkún?
Tún wo ohun tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì tá a fà yọ lókè yìí. Wàá rí i pé nígbà tí Jésù rí i tí Màríà àtàwọn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ń sunkún, Jésù “kérora,” ó sì “dààmú.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò níhìn-ín ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ tọ́ka sí ohun tó dun èèyàn wọra.a Ohun tí Jésù rí yẹn dun Jésù wọra gan-an. Bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára Jésù hàn kedere nígbà tí omijé bẹ̀rẹ̀ sí í dà lójú rẹ̀. Dájúdájú, Jésù máa ń mọ̀ ọ́n lára tó bá rí i táwọn èèyàn ń jẹ̀rora. Ǹjẹ́ ìwọ náà ti sunkún rí nígbà tó o rí i tí ẹnì kan tó sún mọ́ ẹ ń sunkún?—Róòmù 12:15.
-
-
Ẹni Tó Mọ Ìnira WaIlé Ìṣọ́—2008 | May 1
-
-
a Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “da omijé” sábà máa ń túmọ̀ sí kéèyàn “rọra máa sunkún.” Èyí yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún ẹkún Màríà àtàwọn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, torí ìyẹn lè túmọ̀ sí kéèyàn máa “ké tàbí kígbe gan-an.”
-