-
Ta Ni Jésù?Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
6. A máa jàǹfààní púpọ̀ tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì ká máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù àti iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un. Ka Jòhánù 14:6 àti 17:3, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká kékọ̀ọ́ nípa Jésù?
Jésù ṣí ọ̀nà sílẹ̀ ká lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ó kọ́ wa ní òtítọ́ nípa Jèhófà, ipasẹ̀ Jésù sì ni a fi máa jèrè ìyè àìnípẹ̀kun
-