-
Báwo Ló Ṣe Ṣe Pàtàkì Tó Láti Di Àtúnbí?Ilé Ìṣọ́—2009 | April 1
-
-
Jésù sọ pé: “Láìjẹ́ pé a tún ẹnikẹ́ni bí, kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.” (Jòhánù 3:3) Àwọn ọ̀rọ̀ yìí “láìjẹ́” àti “kò lè” jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó fáwọn kan láti di àtúnbí. Wo àpèjúwe yìí ná: Bẹ́nì kan bá sọ pé, “Láìjẹ́ pé oòrùn ràn, ojú ọjọ́ kò lè mọ́lẹ̀,” ohun tó ń sọ ni pé ìmọ́lẹ̀ ṣe pàtàkì kójú ọjọ́ tó lè mọ́lẹ̀. Ohun tí Jésù náà ń sọ ni pé kéèyàn di àtúnbí ṣe pàtàkì kéèyàn tó lè rí Ìjọba Ọlọ́run.
-
-
Ṣéèyàn Fúnra Ẹ̀ Ló Máa Pinnu Póun Fẹ́ Di Àtúnbí?Ilé Ìṣọ́—2009 | April 1
-
-
Tá a bá fara balẹ̀ ka ọ̀rọ̀ Jésù dáadáa, a máa rí i pé Jésù ò kọ́ni pé ọwọ́ èèyàn ló kù sí láti pinnu bóyá òun máa di àtúnbí tàbí òun ò ní dì í. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Lédè Gíríìkì, gbólóhùn tá a tú sí “tún ẹnikẹ́ni bí” tún lè túmọ̀ sí “ó yẹ kí Ọlọ́run tún ẹ bí.”a Torí náà, a lè sọ pé “láti òkè,” ìyẹn “láti ọ̀run” tàbí “láti ọ̀dọ̀ Baba” lẹnì kan ti lè dí àtúnbí. (Jòhánù 19:11; àlàyé ìsàlẹ̀ NW; Jákọ́bù 1:17) Èyí fi hàn pé Ọlọ́run ló ń pinnu ẹni tó máa di àtúnbí.—1 Jòhánù 3:9.
-
-
Ṣéèyàn Fúnra Ẹ̀ Ló Máa Pinnu Póun Fẹ́ Di Àtúnbí?Ilé Ìṣọ́—2009 | April 1
-
-
a Bí èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ìtumọ̀ Bíbélì ṣe tú Jòhánù 3:3 nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, bí Bíbélì A Literal Translation of the Bible ṣe túmọ̀ ẹsẹ Bíbélì yìí rèé: “Bí Ọlọ́run ò bá tún ẹnì kan bí, kò lè wọ Ìjọba Ọlọ́run.”
-