ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Pọ́ọ̀lù Borí Ìpọ́njú
    Ilé Ìṣọ́—1999 | May 1
    • Nígbà tó di ọjọ́ kẹrìnlá tí ìjì náà ti ń jà, ni àwọn atukọ̀ bá ṣàwárí kan tó múni ta gìrì—omi náà kò jìn ju ogún ìgbọ̀nká lọ.a Lẹ́yìn tí wọ́n tún tẹ̀ síwájú díẹ̀, wọ́n tún wọn bí omi náà ti jìn tó. Lọ́tẹ̀ yìí o, ìgbọ̀nká mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré ni omi náà fi jìn. Ilẹ̀ ò jìnnà mọ́! Ṣùgbọ́n ìhìn rere yìí ní ìtumọ̀ tó múni sorí kọ́. Bí ìjì ti ń gbé ọkọ̀ òkun náà sókè sódò lóru nínú omi tí kò jìn yìí, ó lè lọ sẹ̀ ẹ́ mọ́ àpáta, kó sì fọ́ ọ yángá. Lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, àwọn atukọ̀ náà ju ìdákọ̀ró sílẹ̀. Àwọn kan lára wọn fẹ́ rọ ọkọ̀ ìgbájá sílẹ̀ sínú òkun, kí wọ́n lè ráyè bójú òkun sá lọ ní tiwọn.b Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù dá wọn dúró. Ó sọ fún àwọn ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti àwọn ọmọ ogun pé: “Láìjẹ́ pé àwọn ènìyàn wọ̀nyí dúró sínú ọkọ̀ ojú omi, a kò lè gbà yín là.” Àwọn ọ̀gá náà fetí sí Pọ́ọ̀lù, wàyí o, gbogbo èrò náà tí wọ́n jẹ́ igba ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [276] dúró, wọ́n ń retí ìgbà tí ilẹ̀ yóò mọ́.—Ìṣe 27:27-32.

  • Pọ́ọ̀lù Borí Ìpọ́njú
    Ilé Ìṣọ́—1999 | May 1
    • b Ọkọ̀ ìgbájá jẹ́ ọkọ̀ ojú omi kékeré táa lè fi dé èbúté nígbà tí a bá dá ọkọ̀ òkun ró sí ibi tí kò jìnnà sí etíkun. Ó ṣe kedere pé, ṣe ni àwọn atukọ̀ náà fẹ́ gba ẹ̀mí ara wọn là, kí wọ́n sì fi ẹ̀mí àwọn tí wọn yóò fi sílẹ̀ wewu, àwọn tí kò mọ nǹkan kan nípa bí a ṣe lè tukọ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́