-
Wọ́n “Kún fún Ẹ̀mí Mímọ́”“Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
-
-
16. Báwo làwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe fi hàn pé àwọn lẹ́mìí ìfara-ẹni-rúbọ?
16 Ó dájú pé Jèhófà bù kún àwọn èèyàn yẹn. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Gbogbo àwọn tó di onígbàgbọ́ wà pa pọ̀, wọ́n sì jọ ń lo gbogbo ohun tí wọ́n ní, wọ́n ń ta àwọn ohun ìní àti dúkìá wọn, wọ́n sì ń pín owó tí wọ́n rí níbẹ̀ fún gbogbo wọn, bí ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nílò bá ṣe pọ̀ tó.”f (Ìṣe 2:44, 45) Ó dájú pé, gbogbo Kristẹni tòótọ́ ló yẹ kó fara wé ẹ̀mí ìfẹ́ àti ti ìfara-ẹni-rúbọ tí wọ́n ní.
-