ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Àwọn Àkókò Ìmúpadàbọ̀sípò” Ti Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    Ilé Ìṣọ́—2000 | September 1
    • IṢẸ́ yẹn kì í ṣe iṣẹ́ tí wọ́n á lè parí láàárín ọjọ́ díẹ̀, ọ̀sẹ̀ díẹ̀, tàbí oṣù díẹ̀. Àmọ́, ojú ẹsẹ̀ làwọn ọmọlẹ́yìn bẹ̀rẹ̀ sí wàásù. Bíṣẹ́ ò kúkú pẹ́ni, a kì í pẹ́ṣẹ́. Ṣùgbọ́n wọn ò mú ọkàn kúrò lórí ọ̀ràn ìmúpadàbọ̀sípò. Àpọ́sítélì Pétérù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tó ń bá ogunlọ́gọ̀ ńlá kan tó kóra jọ ní Jerúsálẹ́mù sọ̀rọ̀, ó wí pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì yí padà, kí a lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àwọn àsìkò títunilára lè wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, kí ó sì lè rán Kristi tí a yàn sípò jáde fún yín, Jésù, ẹni tí ọ̀run, ní tòótọ́, gbọ́dọ̀ gbà sínú ara rẹ̀ títí di àwọn àkókò ìmúpadàbọ̀sípò ohun gbogbo èyí tí Ọlọ́run sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ ti ìgbà láéláé.”—Ìṣe 3:19-21.

      “Àwọn àkókò ìmúpadàbọ̀sípò” yìí ni yóò mú “àsìkò títunilára” wọlé dé látọ̀dọ̀ Jèhófà. Ìmúpadàbọ̀sípò táa sọ tẹ́lẹ̀ yóò dé ní ipele méjì. Ipele àkọ́kọ́ yóò jẹ́ ìmúpadàbọ̀sípò títunilára nípa tẹ̀mí, èyí tó ti bẹ̀rẹ̀ nísinsìnyí. Ipele kejì yóò tẹ̀ lé e nígbà tí párádísè gidi bá dé sórí ilẹ̀ ayé.

  • “Àwọn Àkókò Ìmúpadàbọ̀sípò” Ti Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    Ilé Ìṣọ́—2000 | September 1
    • Wọ́n dáwọ́ lé iṣẹ́ ìpolongo ńlá kan láti kọ́ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè láti máa tẹ̀ lé gbogbo ohun tí Kristi ti pa láṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ṣe. (Mátíù 28:20) Ẹ wo bó ti ń tuni lára tó láti rí i tí àwọn kan tí wọ́n ń hùwà bí ẹranko tẹ́lẹ̀ wá ń yí ìwà wọn padà! Wọ́n ti bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ń fa àwọn ìṣarasíhùwà bí “ìbínú,” “ọ̀rọ̀ èébú,” àti “ọ̀rọ̀ rírùn,” wọ́n sì ti gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, “èyí tí a ń sọ di tuntun nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán [Ọlọ́run] tí ó dá a.” Lọ́nà tẹ̀mí, ọ̀rọ̀ wòlíì Aísáyà tilẹ̀ ti ń ní ìmúṣẹ báyìí, ó sọ pé: “Ìkookò [ìyẹn, èèyàn oníwà bí ìkookò tẹ́lẹ̀] yóò sì máa gbé ní ti tòótọ́ fún ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn [ìyẹn, èèyàn oníwà pẹ̀lẹ́], àmọ̀tẹ́kùn pàápàá yóò sì dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́, àti ọmọ màlúù àti ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ àti ẹran tí a bọ́ dáadáa, gbogbo wọn pa pọ̀.”—Kólósè 3:8-10; Aísáyà 11:6, 9.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́