-
“A Gbọ́dọ̀ Ṣègbọràn sí Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Alákòóso Dípò Èèyàn”“Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
-
-
Bíi tàwọn àpọ́sítélì, à ń wàásù “láti ilé dé ilé”
16. Báwo làwọn àpọ́sítélì ṣe fi hàn pé wọ́n ti pinnu láti jẹ́rìí kúnnákúnná, báwo làwa náà sì ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn?
16 Àwọn àpọ́sítélì ò fàkókò ṣòfò rárá, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Wọ́n ń fìgboyà ‘kéde ìhìn rere nípa Kristi lójoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé.’d (Ìṣe 5:42) Àwọn àpọ́sítélì náà ń fìtara wàásù, wọ́n sì ń jẹ́rìí kúnnákúnná. Kíyè sí i pé ńṣe ni wọ́n lọ ń wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn nínú ilé wọn bí Jésù Kristi ṣe sọ pé kí wọ́n ṣe. (Mát. 10:7, 11-14) Ó dájú pé èyí ló mú kí wọ́n lè fi ẹ̀kọ́ wọn kún Jerúsálẹ́mù. Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ pé bíi tàwọn àpọ́sítélì làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ṣe ń wàásù. Bá a ṣe ń dé gbogbo ilé tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa fi hàn pé àwa náà fẹ́ ṣiṣẹ́ ìwàásù yìí kúnnákúnná, kí gbogbo èèyàn lè gbọ́ ìhìn rere. Ṣé Jèhófà sì ń bù kún iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé tá à ń ṣe? Ó dájú pé ó ń ṣe bẹ́ẹ̀! Àìmọye èèyàn ló ti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì jẹ́ pé ìgbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ wàásù nílé wọn ni wọ́n kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere.
-