-
“O Jẹ́ Obìnrin Kan Tí Ó Lẹ́wà Ní Ìrísí”Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017 | No. 3
-
-
Ábúráhámù sáré wá sọ́dọ̀ Sárà, inú rẹ̀ sì ń dùn. Àfi bí àlá lohun tó ṣẹlẹ̀ rí lójú rẹ̀. Ọlọ́run tòótọ́ tí wọ́n ń sìn ṣẹ̀ṣẹ̀ bá a sọ̀rọ̀ tán ni. Kódà, ńṣe ló fara hàn án nípasẹ̀ ańgẹ́lì kan! Fojú inú wo bí Sára ṣe tẹjú mọ́ ọkọ rẹ̀, tó ń béèrè lemọ́lemọ́ pé: “Kí ló sọ fún yín? Ẹ jọ̀ọ́, ẹ sọ fún mi!” Ó ṣeé ṣe kí Ábúráhámù kọ́kọ́ jọ́kòó ná, kó wá máa ro ibi tó ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó wá sọ ohun tí Jèhófà sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé: “Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, kí o sì wá sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́.” (Ìṣe 7:2, 3) Nígbà tára wọn balẹ̀, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa iṣẹ́ tí Jèhófà gbé síwájú wọn. Wọ́n máa fi ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ tí wọ́n ń gbé sílẹ̀, wọ́n á sì dẹni tó ń ṣí kiri! Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára Sárà? Ó dájú pé ńṣe ni Ábúráhámù á tẹ́jú mọ́ Sárà. Á máa ronú pé ṣé ìyàwó mi á gbà tinútinú láti ṣe àyípadà ńlá yìí?
Ìpinnu tí Sárà fẹ́ ṣe yìí lè máa yé wa. A lè máa rò ó pé, ‘Ọlọ́run ò tíì ní kí èmí tàbí ẹnì kejì mi ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀!’ Àmọ́, gbogbo wa la máa ń ṣe irú ìpinnu tó jọ ọ́? Àwọn èèyàn fẹ́ràn kíkó ohun ìní jọ báyìí, èyí sì lè mú kó máa wu àwa náà pé ká gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ, ká ní ohun ìní, kọ́kàn wa sì balẹ̀. Àmọ́ Bíbélì rọ̀ wá pé ká fi àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run ṣáájú àwọn nǹkan yẹn, ìyẹn ni pé ká sapá láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ dípò ohun tá a fẹ́. (Mátíù 6:33) Bá a ṣe ń ronú nípa ohun tí Sárà ṣe, a lè bi ara wa pé, ‘Kí ni màá fi sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé mi?’
-
-
“O Jẹ́ Obìnrin Kan Tí Ó Lẹ́wà Ní Ìrísí”Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017 | No. 3
-
-
Àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ńkọ́? Àwọn wo ni Sárà máa fi sílẹ̀? Ó lè ṣòro fún Sárà láti tẹ̀ lé àṣẹ tí Ọlọ́run pa pé “jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ.” Ó dájú pé obìnrin onínuúre, tó sì kóòyàn mọ́ra yìí máa ní láti fi àwọn ẹ̀gbọ́n, àbúrò, àtàwọn mọ̀lẹ́bí míì sílẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kó má tún pa dà fojú kàn wọ́n mọ́. Síbẹ̀, Sárà ò lọ́ tìkọ̀, ó ṣáà ń palẹ̀ ẹrù rẹ̀ mọ́.
-