ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ohun Kan Tó Níye Lórí Ju Àwọn Ìṣúra Íjíbítì Lọ
    Ilé Ìṣọ́—2002 | June 15
    • Nígbà tí wọ́n dá a padà sọ́dọ̀ ọmọbìnrin Fáráò, wọ́n kọ́ Mósè “nínú gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì.” (Ìṣe 7:22) Ìyẹn túmọ̀ sí pé wọ́n fún Mósè ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó máa jẹ́ kó tóótun fún iṣẹ́ ìjọba. Lára àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ni ní Íjíbítì ni ẹ̀kọ́ ìṣirò, ìyàwòrán ilé, ìmọ̀ ìkọ́lé, àti àwọn ẹ̀kọ́ mìíràn tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ọnà àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Ó sì ṣeé ṣe kí ìdílé ọba fẹ́ kó gba ìtọ́ni nínú ìsìn àwọn ará Íjíbítì.

      Ó lè jẹ́ Mósè àtàwọn ọmọ mìíràn láàfin ni wọ́n jọ gba ẹ̀kọ́ àrà ọ̀tọ̀ yìí. Lára àwọn tí wọ́n máa ń gba irú ẹ̀kọ́ ńláńlá bẹ́ẹ̀ ni “ọmọ àwọn alákòóso láti ilẹ̀ òkèèrè tí wọ́n rán wá tàbí tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ìgbèkùn sí Íjíbítì kí ‘ojú wọn lè là,’ lẹ́yìn náà tí wọ́n á dá wọn padà láti lọ máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba dọ̀bọ̀sìyẹsà” fún Fáráò. (The Reign of Thutmose IV, látọwọ́ Betsy M. Bryan) Àwọn iléèwé àwọn ọmọdé tó wà láàfin jẹ́ ibi tí wọ́n ti ń múra àwọn ọ̀dọ́ sílẹ̀ láti sìn gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ láàfin.a Àwọn àkọsílẹ̀ kan tó ti wà láti sáà Agbedeméjì àti sáà Ìjọba Tuntun ti Íjíbítì fi hàn pé àwọn bíi mélòó kan lára àwọn ìránṣẹ́ Fáráò àtàwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba nígbà yẹn ṣì ń fi àpèlé náà “Ọmọ Iléèwé Àwọn Ọmọdé” yangàn, kódà nígbà tí wọ́n di àgbàlagbà.

  • Ohun Kan Tó Níye Lórí Ju Àwọn Ìṣúra Íjíbítì Lọ
    Ilé Ìṣọ́—2002 | June 15
    • a Ẹ̀kọ́ yìí lè dà bí irú èyí tí Dáníẹ́lì àtàwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ gbà kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ìjọba ní Bábílónì. (Dáníẹ́lì 1:3-7) Fi wé ìwé Fiyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!, orí kẹta, èyí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́