ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Fílípì Kéde “Ìhìn Rere Nípa Jésù”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
    • c Ìrìbọmi yẹn ò yá jù. Ó ṣe tán, aláwọ̀ṣe Júù ni ará Etiópíà yìí, ó sì ti ní ìmọ̀ Ìwé Mímọ́, títí kan àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà. Ní báyìí tó ti wá mọ ipa tí Jésù kó láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ, ó lè ṣèrìbọmi lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

  • Fílípì Kéde “Ìhìn Rere Nípa Jésù”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
    • FÍLÍPÌ “AJÍHÌNRERE”

      Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi tú ká nítorí inúnibíni, Fílípì lọ sí Samáríà. Ó dájú pé, ó fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìgbìmọ̀ olùdarí ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, torí pé “nígbà tí àwọn àpọ́sítélì tó wà ní Jerúsálẹ́mù gbọ́ pé Samáríà ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n rán Pétérù àti Jòhánù sí wọn.” Ìyẹn sì mú kó ṣeé ṣe fáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni níbẹ̀ láti gba ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́.​—Ìṣe 8:14-17.

      Fílípì jókòó sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin pẹ̀lú ìwẹ̀fà ará Etiópíà.

      Ẹ̀ẹ̀kan péré ni wọ́n tún dárúkọ Fílípì nínú ìwé Ìṣe lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Ìṣe orí 8 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Èyí sì jẹ́ ní nǹkan bí ogún ọdún lẹ́yìn tí Fílípì kọ́kọ́ wàásù ní Samáríà. Ìgbà yẹn ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó bá a rìnrìn àjò ń pa dà lọ sí Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta. Wọ́n yà ní Tólémáísì. Lúùkù sọ pé: “Lọ́jọ́ kejì, a gbéra, a sì dé Kesaríà, a wọ ilé Fílípì ajíhìnrere, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin méje náà, a sì dúró lọ́dọ̀ rẹ̀. Ọkùnrin yìí ní àwọn ọmọbìnrin mẹ́rin tí kò tíì lọ́kọ, tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀.”​—Ìṣe 21:8, 9.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́