-
Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Bíbélì Ti WáGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
6. Ìwé kan tó wà fún gbogbo èèyàn
Nínú gbogbo ìwé tó wà láyé, Bíbélì ni ìwé tó dé ibi tó pọ̀ jù lọ, òun ló sì wà ní èdè tó pọ̀ jù lọ! Ka Ìṣe 10:34, 35, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí wọ́n túmọ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí èdè tó pọ̀ gan-an, tó sì tún dé ibi tó pọ̀ jù lọ láyé?
Kí ló mú kó o fẹ́ràn Bíbélì?
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé
gbogbo èèyàn
tó wà láyé
ló ní Bíbélì lédè tó yé wọn
Bíbélì wà ní
èdè tó lé ní
3,000
lódindi tàbí lápá kan
5,000,000,000
Èyí ni iye tí wọ́n ṣírò pé wọ́n ti tẹ̀ jáde,
kò sí ìwé míì láyé tí iye ẹ̀ pọ̀ tó yẹn
-
-
Bó O Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ JèhófàGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
3. Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ṣe?
Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn, “ṣùgbọ́n àwọn adúróṣinṣin ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́.” (Òwe 3:32) Jèhófà fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa sapá láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, kí wọ́n sì máa sá fún ìwà burúkú. Àwọn kan rò pé agbára àwọn ò lè gbé e láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. Àmọ́, Jèhófà máa ń gba tiwa rò. Ó máa ń tẹ́wọ́ gba gbogbo ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tó sì ń sapá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—Sáàmù 147:11; Ìṣe 10:34, 35.
-
-
Máa Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Àlàáfíà àti Ìṣọ̀kan Wà Nínú ÌjọGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
4. Gbìyànjú láti borí ẹ̀tanú
Ó máa ń wù wá láti nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Àmọ́, ó lè má rọrùn fún wa láti nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan tí èdè tàbí àṣà ẹ̀ yàtọ̀ sí tiwa. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́? Ka Ìṣe 10:34, 35, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Onírúurú èèyàn ni Jèhófà fún láǹfààní láti di Ẹlẹ́rìí òun. Kí ni àpẹẹrẹ Jèhófà kọ́ ẹ nípa bó ṣe yẹ kó o máa ṣe sí àwọn tí àṣà tàbí èdè wọn yàtọ̀ sí tìẹ?
Kí làwọn èèyàn tó wà ládùúgbò ẹ sábà máa ń ṣe láti fi hàn pé wọ́n kórìíra àwọn tí àṣà tàbí èdè wọn yàtọ̀ sí tiwọn? Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o máa hu irú ìwà bẹ́ẹ̀?
Ka 2 Kọ́ríńtì 6:11-13, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Àwọn nǹkan wo lo rò pé o lè ṣe tó o bá fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará tí àṣà tàbí èdè wọn yàtọ̀ sí tìẹ?
-