-
Wọ́n ní “Ìdùnnú àti Ẹ̀mí Mímọ́ ní Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́”“Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
-
-
1, 2. Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ìrìn àjò tí Bánábà àti Sọ́ọ̀lù fẹ́ rìn, báwo ni iṣẹ́ wọn sì ṣe máa mú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Ìṣe 1:8 ṣẹ?
ỌJỌ́ ayọ̀ lọjọ́ náà jẹ́ fáwọn ará ìjọ tó wà ní Áńtíókù. Nínú gbogbo àwọn wòlíì àtàwọn olùkọ́ tó wà níbẹ̀, Bánábà àti Sọ́ọ̀lù ni ẹ̀mí mímọ́ yàn láti mú ìhìn rere lọ sáwọn ibi tó jìnnà.a (Ìṣe 13:1, 2) Òótọ́ ni pé wọ́n ti rán àwọn ọkùnrin kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn jáde lọ sáwọn ibì kan ṣáájú ìgbà yẹn, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lára ibi tí wọ́n rán wọn lọ làwọn Kristẹni ti wà. (Ìṣe 8:14; 11:22) Ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n máa rán Bánábà àti Sọ́ọ̀lù lọ sáwọn ilẹ̀ tí ìhìn rere ò tíì dé, Jòhánù tó tún jẹ́ Máàkù máa wà pẹ̀lú wọn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́.
2 Ní nǹkan bí ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn, Jésù ti sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù, ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:8) Ní báyìí tí wọ́n ti yan Bánábà àti Sọ́ọ̀lù láti jẹ́ míṣọ́nnárì, ìyẹn máa mú kí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù yẹn ṣẹ!b
-
-
Wọ́n ní “Ìdùnnú àti Ẹ̀mí Mímọ́ ní Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́”“Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
-
-
4. (a) Kí ló darí àwọn tó yan Bánábà àti Sọ́ọ̀lù, ojú wo sì làwọn onígbàgbọ́ yòókù fi wo bí wọ́n ṣe yàn wọ́n? (b) Báwo la ṣe lè máa ṣètìlẹyìn fáwọn tó bá ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ?
4 Àmọ́, kí nìdí tí ẹ̀mí mímọ́ fi dìídì sọ pé kí wọ́n ‘ya Bánábà àti Sọ́ọ̀lù sọ́tọ̀ láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run pè wọ́n sí’? (Ìṣe 13:2) Bíbélì ò sọ fún wa. Ohun tá a mọ̀ ni pé ẹ̀mí mímọ́ ló ní kí wọ́n yan àwọn ọkùnrin náà. Kò sì sóhun tó fi hàn pé àwọn wòlíì àtàwọn olùkọ́ tó wà ní Áńtíókù ta ko ìpinnu yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ṣètìlẹyìn fáwọn ọkùnrin náà. Fojú inú wo bọ́rọ̀ náà ṣe máa rí lára Bánábà àti Sọ́ọ̀lù báwọn arákùnrin wọn ṣe ‘gbààwẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn, tí wọ́n sì rán wọn lọ’ láìsí pé wọ́n ń jowú wọn. (Ìṣe 13:3) Àwa náà gbọ́dọ̀ máa ṣètìlẹyìn fáwọn tó bá ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ, títí kan àwọn tá a yàn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó. Dípò tí àá fi máa jowú àwọn tó nírú àǹfààní bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa “kà wọ́n sí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ nínú ìfẹ́ nítorí iṣẹ́ wọn.”—1 Tẹs. 5:13.
-