-
Wọ́n “Fi Ìgboyà Sọ̀rọ̀ Nípasẹ̀ Àṣẹ Jèhófà”“Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
-
-
8. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà fi kúrò ní Íkóníónì, kí la sì rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ wọn?
8 Kò pẹ́ lẹ́yìn náà táwọn alátakò ní Íkóníónì fi gbìmọ̀ pọ̀ láti sọ Pọ́ọ̀lù àti Bánábà lókùúta pa. Nígbà táwọn míṣọ́nnárì yìí gbọ́ nípa èyí, ńṣe ni wọ́n lọ wàásù níbòmíì. (Ìṣe 14:5-7) Àwa tá à ń wàásù ìhìn rere lóde òní náà máa ń lo irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀. Táwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ burúkú nípa wa tàbí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe, a máa ń fìgboyà dá wọn lóhùn. (Fílí. 1:7; 1 Pét. 3:13-15) Àmọ́, tá a bá rí i pé wàhálà ń bọ̀, a máa ń yẹra fún ṣíṣe ohun tí kò bọ́gbọ́n mu tó lè fi àwa àtàwọn míì tá a jọ ń sin Jèhófà sínú ewu.—Òwe 22:3.
-