-
Ó ‘Ń Mú Inú Wa Dùn’Ilé Ìṣọ́—2013 | July 1
-
-
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ wa jẹ Jèhófà lógún? Àbí kò tiẹ̀ sí èyí tó kàn án nínú gbogbo ìṣòro tó ń dé bá àwa èèyàn láyé ni? Bí Bíbélì ṣe dáhùn ìbéèrè yẹn tù wá nínú, ó sì múnú wa dùn. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé lóòótọ́ ni ọ̀rọ̀ wa jẹ Ọlọ́run lógún, àti pé ó fẹ́ ká gbádùn ayé wa. Lójoojúmọ́ ni Ọlọ́run ń jẹ́ kí gbogbo èèyàn jàǹfààní oore rẹ̀, kódà títí kan àwọn tí kò moore Ọlọ́run. Wo ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ.—Ka Ìṣe 14:16, 17.
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́ ní ìlú Lísírà sọ̀rọ̀, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ní ìgbà ayé àwọn tí ó ti kọjá, [Ọlọ́run] jẹ́ kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè máa ṣe ohun tí ó wù wọ́n. Síbẹ̀ kò ṣàìfi àmì ara rẹ̀ hàn: ó ń ṣe iṣẹ́ rere, ó ń rọ òjò fún yín láti ọ̀run, ó ń mú èso jáde lásìkò, ó ń fún yín ní ońjẹ, ó tún ń mú inú yín dùn.” (Ìròhìn Ayọ̀) Kí ni ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí gbé wá sọ́kàn àwọn olùgbọ́ rẹ̀?
-
-
Ó ‘Ń Mú Inú Wa Dùn’Ilé Ìṣọ́—2013 | July 1
-
-
Jèhófà fún wa lómìnira láti yan ohun tá a bá fẹ́. Kíyè sí i pé Jèhófà fún àwọn èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè láyè láti “máa ṣe ohun tí ó wù wọ́n.” Ìwé kan táwọn atúmọ̀ Bíbélì máa ń ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé ọ̀rọ̀ yìí lè túmọ̀ sí pé “kí wọ́n ṣe bí ó bá ṣe tẹ́ wọn lọ́rùn” tàbí “kí wọ́n ṣe ohun tó bá ṣáà ti tọ́ lójú wọn.” Jèhófà kì í fipá mú ẹnikẹ́ni pé kó wá sin òun. Ṣe ló fún wa lómìnira láti fúnra wa yan bí a ṣe máa gbé ìgbésí ayé wa.—Diutarónómì 30:19.
-