-
Lìdíà—Aláájò Àlejò Olùjọ́sìn Ọlọ́runIlé-Ìṣọ́nà—1996 | September 15
-
-
Ìwàásù Pọ́ọ̀lù ní Fílípì
Ní nǹkan bí 50 ọdún Sànmánì Tiwa, Pọ́ọ̀lù dé Europe fún ìgbà àkọ́kọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i wàásù ní Fílípì.a Nígbà tí ó bá dé ìlú tuntun kan, ó jẹ́ àṣà Pọ́ọ̀lù láti ṣèbẹ̀wò sí sínágọ́gù láti kọ́kọ́ wàásù fún àwọn Júù àti aláwọ̀ṣe tí wọ́n péjọ síbẹ̀. (Fi wé Ìṣe 13:4, 5, 13, 14; 14:1.) Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti sọ, òfin Róòmù kà á léèwọ̀ fún àwọn Júù láti ṣe ìsìn wọn láàárín “àwọn ibi ìyàsọ́tọ̀ mímọ́” ti Fílípì. Nítorí náà, lẹ́yìn lílo “àwọn ọjọ́ díẹ̀” níbẹ̀, ní ọjọ́ Sábáàtì, àwọn míṣọ́nnárì náà wá ibì kan lẹ́bàá odò kan lẹ́yìn òde ìlú náà níbi ti ‘wọn ronú pé ibi àdúrà wà.’ (Ìṣe 16:12, 13) Dájúdájú, èyí jẹ́ Odò Gangites. Níbẹ̀, àwọn míṣọ́nnárì rí kìkì àwọn obìnrin, tí Lìdíà jẹ́ ọ̀kan lára wọn.
-