-
Lìdíà—Aláájò Àlejò Olùjọ́sìn Ọlọ́runIlé-Ìṣọ́nà—1996 | September 15
-
-
“Ẹni Tí Ń Ta Ohun Aláwọ̀ Àlùkò”
Lìdíà gbé ní Fílípì, olú ìlú Makedóníà. Ṣùgbọ́n, Tíátírà ni ó ti wá, ìlú ńlá kan ní ẹkùn Lìdíà, ní ìwọ̀ oòrùn Éṣíà Kékeré. Fún ìdí yìí, àwọn kan sọ pé “Lìdíà” jẹ́ orúkọ ìnagijẹ tí a fún un ní Fílípì. Lọ́nà míràn, ó jẹ́ “ará Lìdíà,” gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti lè pe obìnrin tí Jésù Kristi jẹ́rìí fún ní “obìnrin ará Samáríà.” (Jòhánù 4:9) Lìdíà ń ta “ohun aláwọ̀ àlùkò” tàbí àwọn ohun èlò tí a pa láró yìí. (Ìṣe 16:12, 14) Àwọn àkọlé tí àwọn awalẹ̀pìtàn wà jáde láti inú ilẹ̀ jẹ́rìí sí i pé àwọn aláró wà ní Tíátírà àti ní Fílípì. Ó lè jẹ́ pé Lìdíà ṣí lọ nítorí iṣẹ́ rẹ̀, yálà láti máa bá iṣẹ́ rẹ̀ nìṣó tàbí gẹ́gẹ́ bí aṣojú ilé iṣẹ́ àwọn aláró ará Tíátírà.
A lè rí aró àlùkò láti inú onírúurú nǹkan. Èyí tí ó wọ́n jù lọ ní a ń mú jáde láti ara irú ìgbín òkun kan. Gẹ́gẹ́ bí akéwì ará Róòmù ọ̀rúndún kìíní, Martial ṣe sọ, ẹ̀wù àwọ̀lékè tí ó ní àwọ̀ àlùkò tí ó dára jù lọ láti Tírè (ọ̀gangan mìíràn tí a ti ń pèsè ohun èlò yìí) lè náni tó 10,000 owó sesterces, tàbí 2,500 dínárì, tí í ṣe iye owó alágbàṣe kan fún 2,500 ọjọ́. Ní kedere, irú ẹ̀wù bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun aláfẹ́ tí ó jẹ́ pé ẹni díẹ̀ ni ó lè ní in. Nítorí náà, Lìdíà ti lè rí towó ṣe. Ohun yòó wù kí ọ̀ràn náà jẹ́, ó ṣeé ṣe fún un láti fi aájò àlejò hàn sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀—Lúùkù, Sílà, Tímótì, àti bóyá, àwọn mìíràn.
-
-
Lìdíà—Aláájò Àlejò Olùjọ́sìn Ọlọ́runIlé-Ìṣọ́nà—1996 | September 15
-
-
“Olùjọ́sìn Ọlọ́run”
Lìdíà jẹ́ “olùjọ́sìn Ọlọ́run,” ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ aláwọ̀ṣe Ìsìn Àwọn Júù bí ó ti ń wá òtítọ́ ìsìn kiri. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní iṣẹ́ tí ń mówó wọlé, Lìdíà kì í ṣe onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ya àkókò sọ́tọ̀ fún àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí. “Jèhófà . . . ṣí ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ gbayawu láti fiyè sí àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ,” Lìdíà sì tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Ní tòótọ́, “a batisí òun àti agbo ilé rẹ̀.”—Ìṣe 16:14, 15.
-