ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Sọdá Wá sí Makedóníà”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
    • 16. Báwo ni nǹkan ṣe yí pa dà lọ́jọ́ kejì tí wọ́n na Pọ́ọ̀lù àti Sílà?

      16 Lọ́jọ́ kejì tí wọ́n na Pọ́ọ̀lù àti Sílà, àwọn adájọ́ yẹn wá pàṣẹ pé kí wọ́n tú wọn sílẹ̀. Àmọ Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Wọ́n nà wá lẹ́gba ní gbangba láìdá wa lẹ́bi, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ará Róòmù ni wá, wọ́n jù wá sẹ́wọ̀n. Ṣé wọ́n wá fẹ́ tì wá jáde ní bòókẹ́lẹ́ ni? Rárá o! Kí àwọn fúnra wọn wá mú wa jáde.” Nígbà táwọn adájọ́ yẹn gbọ́ pé ará Róòmù ni Pọ́ọ̀lù àti Sílà, “ẹ̀rù bà wọ́n,” torí pé wọ́n ti fi ẹ̀tọ́ àwọn ọkùnrin náà dù wọ́n.d Nǹkan ti wá yí pa dà báyìí. Gbangba ni wọ́n ti fìyà jẹ àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà, àfi káwọn adájọ́ yẹn tọrọ ìdáríjì ní gbangba. Wọ́n bẹ Pọ́ọ̀lù àti Sílà pé kí wọ́n kúrò nílùú Fílípì. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì yẹn gbà láti kúrò níbẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n kọ́kọ́ fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn níṣìírí. Lẹ́yìn náà, wọ́n kúrò níbẹ̀.

  • “Sọdá Wá sí Makedóníà”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
    • d Òfin àwọn ará Róòmù ni pé kí wọ́n gbọ́ ẹjọ́ ẹni tó bá jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ lọ́nà tó tọ́, wọn ò sì gbọ́dọ̀ fìyà jẹ ẹ́ ní gbangba láìjẹ́ pé ó jẹ̀bi.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́