ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ Wá Ọlọ́run, Kẹ́ Ẹ sì Rí I Ní Ti Gidi
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
    • 17, 18. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn èèyàn fẹ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run, kí la sì lè rí kọ́ látinú bí Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ lọ́kàn?

      17 Ó yẹ káwọn èèyàn fẹ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù sọ pé, nípasẹ̀ Ọlọ́run ni “a fi ní ìyè, tí à ń rìn, tí a sì wà.” Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ọ̀rọ̀ Epimenides, ìyẹn akéwì ọmọ ilẹ̀ Kírétè tó gbáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí, “àwọn ará Áténì ò sì kóyán rẹ̀ kéré nínú ààtò ẹ̀sìn wọn.” Pọ́ọ̀lù tún sọ ìdí míì tó fi yẹ kéèyàn fẹ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run, ó sọ pé: “Bí ọ̀rọ̀ àwọn kan lára àwọn akéwì yín tó sọ pé, ‘Nítorí àwa náà jẹ́ ọmọ rẹ̀.’ ” (Ìṣe 17:28) Àwa èèyàn gbọ́dọ̀ máa wo ara wa bí ẹni tó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, torí pé òun ló dá baba ńlá wa. Kí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù lè wọ àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ lọ́kàn, ó fa ọ̀rọ̀ yọ ní tààràtà látinú ìwé Gíríìkì tí kò sí àní-àní pé àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ náà mọ̀ nípa ẹ̀.e Bíi ti Pọ́ọ̀lù, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwa náà lè fa ọ̀rọ̀ yọ látinú àwọn ìwé ìtàn, ìwé gbédègbẹ́yọ̀, tàbí àwọn ìwé míì téèyàn lè ṣèwádìí nínú ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá mú ọ̀rọ̀ tó bá ohun tá à ń jíròrò mu látinú ìwé kan táwọn èèyàn fojú pàtàkì wò, ó lè mú kí àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà yí èrò wọn pa dà nípa àwọn àṣà ẹ̀sìn èké kan tí wọ́n ń lọ́wọ́ sí.

  • Ẹ Wá Ọlọ́run, Kẹ́ Ẹ sì Rí I Ní Ti Gidi
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
    • e Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú àwọn ewì nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà, ìyẹn Phaenomena, tí akéwì onímọ̀ ọgbọ́n orí Sítọ́íkì náà Aratus kọ. Lára àwọn ọ̀rọ̀ yìí wà nínú àwọn ìwé míì táwọn Gíríìkì kọ, títí kan ìwé orin tí wọ́n pè ní Hymn to Zeus, tí onímọ̀ ọgbọ́n orí Sítọ́íkì náà Cleanthes kọ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́