ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Àwọn Ohun Ọlá Ńlá Ọlọ́run” Ń ru Wá Sókè
    Ilé Ìṣọ́—2002 | August 1
    • Ọ̀rọ̀ Náà Gbún Wọn Ní Kẹ́sẹ́!

      4. Àsọtẹ́lẹ̀ wo tí Jóẹ́lì sọ ló nímùúṣẹ ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa?

      4 Gbàrà táwọn ọmọlẹ́yìn ní Jerúsálẹ́mù rí ẹ̀mí mímọ́ gbà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ìhìn rere ìgbàlà fáwọn ẹlòmíì. Wọ́n ti ọ̀dọ̀ ogunlọ́gọ̀ tó kóra jọ ní àárọ̀ ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì yẹn bẹ̀rẹ̀. Ìwàásù wọn jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì kan tí Jóẹ́lì ọmọ Pétúélì kọ sílẹ̀ ní ọ̀rúndún mẹ́jọ ṣáájú ìgbà yẹn, pé: “Èmi yóò tú ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo onírúurú ẹran ara, àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín yóò sì máa sọ tẹ́lẹ̀ dájúdájú. Ní ti àwọn àgbà ọkùnrin yín, wọn yóò máa lá àlá. Ní ti àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín, wọn yóò máa rí ìran. Èmi yóò sì tú ẹ̀mí mi jáde àní sára àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti sára àwọn ìránṣẹ́bìnrin pàápàá ní ọjọ́ wọnnì . . . kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà tó dé.”—Jóẹ́lì 1:1; 2:28, 29, 31; Ìṣe 2:17, 18, 20.

      5. Lọ́nà wo làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní gbà sọ tẹ́lẹ̀? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

      5 Ṣé ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run máa sọ gbogbo àwọn ènìyàn kan, lọ́kùnrin àti lóbìnrin di wòlíì, gẹ́gẹ́ bó ṣe yan Dáfídì, Jóẹ́lì àti Dèbórà, kí ó sì gbẹnu wọn sọ àwọn ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀? Rárá o. Àwọn Kristẹni ‘ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin’ yóò máa sọ tẹ́lẹ̀ ní ti pé, ẹ̀mí Jèhófà yóò sún wọn láti máa polongo “àwọn ohun ọlá ńlá” tí Jèhófà ti ṣe àti èyí tí yóò ṣe lọ́jọ́ iwájú. Ìyẹn ni pé wọ́n á jẹ́ agbẹnusọ fún Ọ̀gá Ògo.a Àmọ́ o, báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára ogunlọ́gọ̀ náà?—Hébérù 1:1, 2.

  • “Àwọn Ohun Ọlá Ńlá Ọlọ́run” Ń ru Wá Sókè
    Ilé Ìṣọ́—2002 | August 1
    • a Nígbà tí Jèhófà yan Mósè àti Áárónì pé kí wọ́n ṣojú fáwọn èèyàn òun níwájú Fáráò, Ó sọ fún Mósè pé: “Mo fi ọ́ ṣe Ọlọ́run fún Fáráò, Áárónì arákùnrin rẹ gan-an yóò sì di wòlíì rẹ.” (Ẹ́kísódù 7:1) Áárónì jẹ́ wòlíì, kì í ṣe nípa sísọ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀, bí kò ṣe nípa dídi agbọ̀rọ̀sọ tàbí agbẹnusọ fún Mósè.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́