ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Mo Ké Gbàjarè sí Késárì!”
    Ilé Ìṣọ́—2001 | December 15
    • ÀWỌN jàǹdùkú ṣùrù bo ọ̀gbẹ́ni kan tí kò lólùgbèjà. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lù ú. Lílù ni wọ́n fẹ́ lù ú pa bámúbámú. Díẹ̀ ṣín-ún ló kù kí ẹ̀mí rẹ̀ bọ́, nígbà táwọn sójà rọ́ dé, tí wọ́n sì fipá já ẹni ẹlẹ́ni gbà lọ́wọ́ àwọn kàràǹbààní ẹ̀dá náà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ni ọkùnrin náà. Àwọn Júù ló fẹ́ lù ú pa. Wọ́n ní ìwàásù Pọ́ọ̀lù ń run àwọn nínú. Wọ́n tún ní ó ń ṣe ohun tó jẹ́ èèwọ̀ ní tẹ́ńpìlì. Àwọn ará Róòmù ló wá gbà á sílẹ̀. Orúkọ ọ̀gágun tó kó àwọn sójà wá ni Kilaudiu Lísíà. Gbogbo rìgbòrìyẹ̀ yẹn ló sáà jẹ́ kí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù nímùú ọ̀daràn.

      Àkọsílẹ̀ ẹjọ́ tí wọ́n ṣe lẹ́yìn tí wọ́n mú un yìí wà nínú orí ìwé méje tó gbẹ̀yìn ìwé Ìṣe. Mímọ ibi tí Pọ́ọ̀lù lóye ọ̀ràn òfin dé, mímọ àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, mímọ bó ṣe gbèjà ara rẹ̀ àti mímọ ìlànà táwọn ará Róòmù ń tẹ̀ lé nínú ọ̀ràn ìgbẹ́jọ́, á jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn orí ìwé wọ̀nyí.

  • “Mo Ké Gbàjarè sí Késárì!”
    Ilé Ìṣọ́—2001 | December 15
    • Ara ojúṣe Kilaudiu Lísíà ni láti rí sí i pé ìgboro Jerúsálẹ́mù kò dà rú. Ìlú Kesaréà ni ọ̀gá rẹ̀, ìyẹn ará Róòmù tí í ṣe gómìnà Jùdíà, ń gbé. Ìgbésẹ̀ tí Lísíà gbé nínú ọ̀ràn Pọ́ọ̀lù lè jẹ́ nítorí àtigbà á lọ́wọ́ àwọn jàǹdùkú. Ó tún lè jẹ́ nítorí pé ó fẹ́ fi ẹni tó kà sí ọ̀dàlúrú sí àtìmọ́lé. Ìhùwàpadà àwọn Júù ló jẹ́ kí Lísíà gbé ọkùnrin tó mú yìí lọ sí ibùdó ológun tó wà ní Ilé Gogoro Antonia.—Ìṣe 21:27–22:24.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́