ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́—2010 | March 1
    • Àwọn wo ni “àwọn ọkùnrin ọlọ́bẹ aṣóró” tí wọ́n mẹ́nu kàn nígbà táwọn ará Róòmù mú Pọ́ọ̀lù?

      ▪ Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó wà nínú ìwé Ìṣe inú Bíbélì ṣe sọ, nígbà rúkèrúdò kan ní tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù, ọ̀gágun ará Róòmù fi àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sínú àhámọ́ nítorí èrò rẹ̀ ni pé Pọ́ọ̀lù ni olórí “ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àwọn ọkùnrin ọlọ́bẹ aṣóró,” tí wọ́n ń dìtẹ̀ sí ìjọba. (Ìṣe 21:30-38) Kí làwọn èèyàn mọ̀ nípa àwọn ọkùnrin ọlọ́bẹ aṣóró yìí?

      Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí “ọkùnrin ọlọ́bẹ aṣóró” wá látinú ọ̀rọ̀ Látìn tó ń jẹ́ àwọn Síkárì tó túmọ̀ sí “àwọn tó ń lo síkà,” tàbí ọ̀bẹ aṣóró. Òpìtàn ọ̀gọ́rùn-ún ọdún kìíní tó ń jẹ́ Flavius Josephus sọ pé àwọn Síkárì jẹ́ àwọn Júù onítara tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè wọn bí nǹkan míì, alénimádẹ̀yìn ọ̀tá Róòmù ni wọ́n, tí wọ́n máa ń pa àwọn olóṣèlú.

      Ọ̀gbẹ́ni Josephus ròyìn pé àwọn Síkárì “máa ń pa àwọn èèyàn ní ọ̀sán gan-gan, láàárín ìlú; wọ́n máa ń ṣe èyí, pàápàá nígbà àjọyọ̀, nígbà tí wọ́n bá kó sáàárín ogunlọ́gọ̀ àwọn èèyàn, tí wọ́n á sì tọ́jú ọ̀bẹ aṣóró wọn sábẹ́ aṣọ wọn, ọ̀bẹ yẹn ni wọ́n fi ń gún àwọn ọ̀tá wọn.” Nígbà tẹ́ni tí àwọn Síkárì gún bá ṣubú lulẹ̀ tó sì kú, wọ́n máa ń díbọ́n bíi pé inú ń bí àwọn sẹ́ni tó pa ẹni náà, kí wọ́n má bàa fura sí wọn. Josephus fi kún un pé àwọn Síkárì ló múpò iwájú nínú ọ̀tẹ̀ táwọn Júù dì sáwọn ará Róòmù ní ọdún 66 sí 70 Sànmánì Kristẹni. Ìdí nìyẹn tí ọ̀gágun ará Róòmù náà kò fi fẹ́ dá ẹni táwọn èèyàn pè ní olórí irú àwọn èèyànkéèyàn bẹ́ẹ̀ sílẹ̀.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́—2010 | March 1
    • [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

      Bí ayàwòrán kan ṣe ya ọkùnrin ọlọ́bẹ aṣóró rèé

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́