-
“Kò sí Ìkankan Lára Yín Tó Máa Ṣègb锓Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
-
-
“Gbogbo Wa Dórí Ilẹ̀ Láìséwu” (Ìṣe 27:27-44)
“Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run níwájú gbogbo wọn.”—Ìṣe 27:35
16, 17. (a) Ìgbà wo ní Pọ́ọ̀lù gbàdúrà, kí ló sì yọrí sí? (b) Báwo lọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ṣe ṣẹ?
16 Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tí wọ́n ti wà lórí omi, tẹ́rù ń bà wọ́n, tí ìjì líle náà sì ti ń gbé ọkọ̀ wọn fún nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti àádọ́rin (870) kìlómítà, àwọn atukọ̀ náà rí ohun kan tó fi hàn pé wọ́n ti ń sún mọ́ èbúté. Wọ́n wá ju ìdákọ̀ró sínú omi láti ẹ̀yìn ọkọ̀ náà, kí ọkọ̀ náà má bàa tún lọ síbòmíì, kí wọ́n sì lè darí ẹ̀ sí etíkun. Lẹ́yìn náà, àwọn atukọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n ṣe máa sá lọ, àmọ́ àwọn ọmọ ogun ò gbà kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ fún ọ̀gá àwọn ọmọ ogun àtàwọn ọmọ ogun náà pé: “Láìjẹ́ pé àwọn èèyàn yìí dúró sínú ọkọ̀ òkun yìí, ẹ ò lè yè bọ́ o.” Ní báyìí tí ìgbì òkun ò gbé ọkọ̀ náà mọ́, Pọ́ọ̀lù rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n jẹun, ó fi dá wọn lójú pé kò séwu mọ́, ó sì “dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run níwájú gbogbo wọn.” (Ìṣe 27:31, 35) Bí Pọ́ọ̀lù ṣe gbàdúrà yẹn jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa fún Lúùkù, Àrísítákọ́sì àtàwọn Kristẹni lóde òní. Tó o bá ń gbàdúrà níwájú àwọn èèyàn, ṣé àdúrà ẹ máa ń tù wọ́n nínú, ṣó sì máa ń fún wọn lókun?
-