ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ọlọ́run Dámọ̀ràn Ìfẹ́ Rẹ̀ Fún Wa
    Ilé Ìṣọ́—2011 | June 15
    • 7, 8. Báwo ni ọ̀nà tí àwọn ọkùnrin pípé méjì gbà gbé ìgbé ayé wọn ṣe já sí ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀?

      7 Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí àwa èèyàn mú kó ṣe ohun tó lè mú ká borí ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé ńṣe ni Ọlọ́run lo ọkùnrin míì, tó jẹ́ ẹni pípé bíi ti Ádámù àkọ́kọ́. (1 Kọ́r. 15:45) Àmọ́, ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ọ̀nà tí àwọn ọkùnrin pípé méjì yìí gbà gbé ìgbé ayé wọn já sí. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?—Ka Róòmù 5:15, 16.

      8 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti rí pẹ̀lú ẹ̀bùn náà ni ó rí pẹ̀lú àṣemáṣe.” Ádámù jẹ̀bi àṣemáṣe, ó sì gba ìdájọ́ tó tọ́ sí i, èyí tí í ṣe ikú. Àmọ́, ikú náà kò mọ sórí òun nìkan. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ . . . kú nípasẹ̀ àṣemáṣe ọkùnrin kan.” Ìdájọ́ òdodo Jèhófà gba pé kó dẹ́bi ikú fún ẹni tó bá dẹ́ṣẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀ràn ikú Ádámù kan àwa ọmọ wọn náà torí pé àìpé tá a jogún látọ̀dọ̀ wọn ti sọ wá di ẹlẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀, ó tù wá nínú láti mọ̀ pé ohun tí Jésù, ọkùnrin pípé náà, ṣe máa yọrí sí ohun tó yàtọ̀ sí ìyẹn. Kí ló yọrí sí? A rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé Ọlọ́run máa ‘polongo onírúurú èèyàn ní olódodo fún ìyè.’—Róòmù 5:18.

      9. Ìwé Róòmù 5:16, 18 sọ pé Ọlọ́run polongo àwọn èèyàn ní olódodo, kí ni ìyẹn túmọ̀ sí?

      9 Kí ni ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ lédè Yorùbá sí “ìpolongo òdodo” àti “pípolongo wọn ní olódodo”? Ọ̀mọ̀wé Williams tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Àfiwé ni. Wọ́n máa ń lò ó láti ṣàlàyé ọ̀rọ̀ tó bá jẹ mọ́ òfin. Gbólóhùn náà ṣàlàyé ìyípadà tí Ọlọ́run mú kó wáyé nínú ìgbésí ayé ẹnì kan, kì í wulẹ̀ ṣe bí èèyàn ṣe yí ọ̀nà tó gbà ń hùwà pa dà . . . Àfiwé náà fi Ọlọ́run sípò adájọ́ tó ti ṣe tán láti dá ẹni tí wọ́n gbé wá sí kóòtù rẹ̀ láre lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ẹ̀sùn kan onítọ̀hún pé ó hùwà àìṣòdodo. Àmọ́, Ọlọ́run dá ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn náà sílẹ̀ pátápátá.”

  • Ọlọ́run Dámọ̀ràn Ìfẹ́ Rẹ̀ Fún Wa
    Ilé Ìṣọ́—2011 | June 15
    • 14, 15. Èrè wo ló ń dúró de àwọn tí Ọlọ́run polongo ní olódodo, àmọ́ kí ni wọ́n ṣì ní láti ṣe?

      14 Rò ó wò ná: Olódùmarè ṣe tán láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnì kan jogún àti àwọn àṣìṣe rẹ̀ jì í. Ẹ̀bùn ńlá mà nìyẹn o! Ó ṣòro láti ka iye ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnì kan ti dá kó tó di Kristẹni; síbẹ̀, Ọlọ́run lè dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ náà jì í lọ́lá ẹbọ ìràpadà náà. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ̀bùn náà yọrí láti inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣemáṣe sí ìpolongo òdodo.” (Róòmù 5:16) Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn míì tí wọ́n rí ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fìfẹ́ pèsè yìí gbà (bó ṣe polongo wọn ní olódodo) ní láti máa bá a nìṣó láti máa fi ìgbàgbọ́ sin Ọlọ́run tòótọ́. Èrè wo ló ń dúró dè wọ́n? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwọn tí ń gba ọ̀pọ̀ yanturu inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ òdodo yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba nínú ìyè nípasẹ̀ ènìyàn kan, Jésù Kristi.” Dájúdájú, ẹ̀bùn òdodo ń ṣiṣẹ́ lọ́nà kan tó yàtọ̀. Ìyè ló máa yọrí sí fún àwọn tó bá gba ẹ̀bùn náà.—Róòmù 5:17; ka Lúùkù 22:28-30.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́