ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ Máa Rìn Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ẹ̀mí Kẹ́ ẹ Lè Jogún Ìyè Àti Àlàáfíà
    Ilé Ìṣọ́—2011 | November 15
    • 8 Òfin dá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lẹ́bi torí pé kò ṣeé ṣe fún wọn láti pa gbogbo ohun tó sọ mọ́. Síwájú sí i, aláìpé ni àwọn àlùfáà àgbà orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí wọ́n ń tẹ̀ lé Òfin, wọn kò sì lè rú ẹbọ tó péye fún ẹ̀ṣẹ̀. Torí náà, Òfin “jẹ́ aláìlera nípasẹ̀ ẹran ara.” Nígbà tí Ọlọ́run ‘rán Ọmọ tirẹ̀ ní ìrí ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀’ tó sì yọ̀ǹda pé kó kú ikú ìrúbọ, Ó “dá ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́bi nínú ẹran ara,” ó sì tipa bẹ́ẹ̀ borí ‘àìgbéṣẹ́ tó wà níhà ti Òfin.’ Látàrí èyí, Ọlọ́run ka àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn sí olódodo nítorí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. A rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa “rìn, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara, bí kò ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí.” (Ka Róòmù 8:3, 4.) Wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ láìyẹsẹ̀ títí tí wọ́n máa fi parí iṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé kí wọ́n lè gba “adé ìyè.”—Ìṣí. 2:10.

  • Ẹ Máa Rìn Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ẹ̀mí Kẹ́ ẹ Lè Jogún Ìyè Àti Àlàáfíà
    Ilé Ìṣọ́—2011 | November 15
    • 10. Kí ló fi hàn pé a kò bọ́ lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú?

      10 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Kò sẹ́ni tó bọ́ lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú nínú gbogbo wa torí pé àtọmọdọ́mọ Ádámù ni wá. Ìgbà gbogbo ni ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ tá a gbé wọ̀ máa ń sún wa láti ṣe àwọn nǹkan tí Ọlọ́run kò fẹ́, ikú ló sì máa ń yọrí sí. Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Gálátíà, ó pe àwọn nǹkan tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń fẹ́ ká ṣe yìí ní “àwọn iṣẹ́ ti ara.” Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Àwọn tí ń fi irúfẹ́ nǹkan báwọ̀nyí ṣe ìwà hù kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” (Gál. 5:19-21) Ìwé Róòmù tún sọ pé àwọn tó ń fi irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣèwà hù ń rìn ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara. (Róòmù 8:4) Ohun ‘tó ń sún wọn láti hùwà’ àti ‘ìlànà tí wọ́n gbà kó máa darí àwọn’ jẹ́ ti ẹran ara látòkèdélẹ̀. Àmọ́, ṣé àwọn tó ń ṣe panṣágà, tí wọ́n ń bọ̀rìṣà, tí wọ́n ń bẹ́mìí lò tàbí tí wọ́n ń dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ míì tó burú jáì nìkan ni wọ́n ń rìn ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara? Rárá o, torí pé ohun táwọn míì lè kà sí àléébù pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ náà wà lára àwọn iṣẹ́ ti ara, irú bí owú, ìrufùfù ìbínú, asọ̀ àti ìlara. Tá lo lè fọwọ́ sọ̀yà pé kò sí ohun tó lè mú kóun rìn ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara?

  • Ẹ Máa Rìn Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ẹ̀mí Kẹ́ ẹ Lè Jogún Ìyè Àti Àlàáfíà
    Ilé Ìṣọ́—2011 | November 15
    • 12 Ńṣe lọ̀rọ̀ wa dà bí ìgbà tá à ń ṣàìsàn gan-an tí dókítà sì ń tọ́jú wa. Kí àìsàn náà lè lọ kúrò lára wa, a gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí dókítà bá sọ pé ká ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tá a bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà, ó lè mú ká bọ́ lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, síbẹ̀ aláìpé àti ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wé mọ́ níní àjọṣe rere pẹ̀lú Jèhófà àti bá a ṣe lè máa gbádùn ojú rere Ọlọ́run àti ìbùkún rẹ̀. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè ṣe “ohun òdodo tí Òfin béèrè,” ó tún mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí.

      Báwo La Ṣe Lè Máa Rìn Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ẹ̀mí?

      13. Kí ló túmọ̀ sí láti máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí?

      13 Tá a bá ń rìn ńṣe la máa ń gbé ẹsẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé títí tá a fi máa débi tá à ń lọ tàbí tọ́wọ́ wa fi máa tẹ ohun tá a fẹ́. Torí náà, ká lè máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ síwájú ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ká lè ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn ò túmọ̀ sí pé a kò lè ṣe àṣìṣe. (1 Tím. 4:15) Lójoojúmọ́, a gbọ́dọ̀ máa sa gbogbo ipá wa ká lè máa rìn tàbí ká lè máa gbé ìgbé ayé wa ní ìbámu pẹ̀lú ibi tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń darí wa sí. A máa rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run tá a bá ń “rìn nípa ẹ̀mí.”—Gál. 5:16.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́