ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Dídúró Pẹ̀lú “Ìfojúsọ́nà Oníhàáragàgà”
    Ilé Ìṣọ́—1998 | September 15
    • “Ìfojúsọ́nà Oníhàáragàgà Ìṣẹ̀dá”

      12, 13. Báwo ni a ṣe “tẹ” ẹ̀dá ènìyàn “lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo,” kí sì ni àwọn àgùntàn mìíràn ń yán hànhàn fún?

      12 Àwọn àgùntàn mìíràn pẹ̀lú ha ní ohun kan tí wọ́n lè máa fi ìháragàgà fojú sọ́nà fún? Dájúdájú wọ́n ní. Lẹ́yìn sísọ̀rọ̀ nípa ìrètí ológo ti àwọn tí Jèhófà sọ dọmọ gẹ́gẹ́ bí “àwọn ọmọ” rẹ̀ tí a fi ẹ̀mí bí àti “àwọn ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi” nínú Ìjọba ọ̀run, Pọ́ọ̀lù wí pé: “Ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà ìṣẹ̀dá ń dúró de ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run. Nítorí a tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo, kì í ṣe nípasẹ̀ ìfẹ́ òun fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹni tí ó tẹ̀ ẹ́ lórí ba, nítorí ìrètí pé a óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:14-21; 2 Tímótì 2:10-12.

  • Dídúró Pẹ̀lú “Ìfojúsọ́nà Oníhàáragàgà”
    Ilé Ìṣọ́—1998 | September 15
    • 14. Kí ni ‘ṣíṣí àwọn ọmọ Ọlọ́run payá’ yóò ní nínú, báwo sì ni èyí yóò ṣe yọrí sí ‘dídá aráyé sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́’?

      14 A gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ‘ṣí àṣẹ́kù ẹni àmì òróró, àwọn ọmọ Ọlọ́run payá.’ Kí ni èyí yóò ní nínú? Nígbà tí ó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run, yóò hàn gbangba sí àwọn àgùntàn mìíràn pé a ti fi “èdìdì di” àwọn ẹni àmì òróró nígbẹ̀yìngbẹ́yín, a sì ti ṣe wọ́n lógo láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi. (Ìṣípayá 7:2-4) A óò tún ‘ṣí àwọn ọmọ Ọlọ́run’ tí a jí dìde ‘payá’ nígbà tí wọ́n bá bá Kristi lọ́wọ́ nínú pípa ètò àwọn nǹkan búburú ti Sátánì run. (Ìṣípayá 2:26, 27; 19:14, 15) Lẹ́yìn náà, nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, a óò túbọ̀ ‘ṣí wọn payá’ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tí a ń lò fún pípín àǹfààní ẹbọ ìràpadà Jésù fún “ìṣẹ̀dá” tí ó jẹ́ ènìyàn. Èyí yóò yọrí sí ‘dídá aráyé sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́,’ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ wọn yóò sì wọnú “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21; Ìṣípayá 20:5; 22:1, 2) Bí a ti ní irú ìrètí kíkọyọyọ bẹ́ẹ̀, ó ha yani lẹ́nu pé àwọn àgùntàn mìíràn “ń dúró de ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run” pẹ̀lú “ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà” bí?—Róòmù 8:19.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́