ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ǹjẹ́ Ohunkóhun “Lè Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”?
    Ilé Ìṣọ́—2008 | August 1
    • Sún Mọ́ Ọlọ́run

      Ǹjẹ́ Ohunkóhun “Lè Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”?

      Róòmù 8:38, 39

      GBOGBO èèyàn ló ń fẹ́ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òun. Ká sòótọ́, ọkàn wa máa ń balẹ̀ gan-an tá a bá mọ̀ pé àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ wa fẹ́ràn wa. Àmọ́, ó dunni pé àjọṣe àárín àwa ọmọ èèyàn jẹ́ ohun tó gbẹgẹ́, tó sì lè yí padà láìròtẹ́lẹ̀. Àwọn ọ̀rẹ́, ẹbí tàbí ojúlùmọ̀ lè ṣẹ̀ wá, wọ́n lè pa wá tì tàbí kí wọ́n tiẹ̀ kọ̀ wá sílẹ̀. Àmọ́, ẹnì kan wà tí ìfẹ́ rẹ̀ sí wa kì í ṣá. Ẹni náà ni Jèhófà Ọlọ́run, ìwé Róòmù 8:38, 39 sì sọ ohun tó wúni lórí nípa irú ìfẹ́ tó ní sáwọn olùjọ́sìn rẹ̀.

  • Ǹjẹ́ Ohunkóhun “Lè Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”?
    Ilé Ìṣọ́—2008 | August 1
    • “Tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn.” Kò sípò táwọn èèyàn Jèhófà wà tí Jèhófà kò ní nífẹ̀ẹ́ wọn, ì báà jẹ́ inú ìdùnnú tàbí ìbànújẹ́.

      “Tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn.” Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ tó tọ́ka sí ẹ̀dá èyíkéyìí náà láti fi hàn dájú pé, kò sóhun tó lè ya àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.

      Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sáwọn tó gbà á gbọ́ kò dà bí ìfẹ́ àwa èèyàn tó lè yí padà tàbí kó ṣá. Ìfẹ́ Ọlọ́run kì í yí padà, títí láé ni. Ó dájú pé mímọ̀ tá a mọ èyí ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ká sì máa sa gbogbo ipá wa láti fi hàn pé àwa náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́