-
Ẹ Máa Wá “Òdodo Rẹ̀” Lákọ̀ọ́kọ́Ilé Ìṣọ́—2010 | October 15
-
-
Ewu Tó Wà Nínú Dídi Olódodo Lójú Ara Ẹni
5. Ewu wo la gbọ́dọ̀ yẹra fún?
5 Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni tó wà nílùú Róòmù, ó sọ ewu tó yẹ kí gbogbo wa yẹra fún, tá a bá fẹ́ kẹ́sẹ járí nínú wíwá òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Júù, ó sọ pé: “Mo jẹ́rìí wọn pé wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye; nítorí, fún ìdí náà pé wọn kò mọ òdodo Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti gbé tiwọn kalẹ̀, wọn kò fi ara wọn sábẹ́ òdodo Ọlọ́run.” (Róòmù 10:2, 3) Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, àwọn olùjọsìn yẹn kò mọ òdodo Ọlọ́run torí pé bí wọ́n ṣe máa gbé òdodo tara wọn kalẹ̀ ni wọ́n ń lépa.a
-
-
Ẹ Máa Wá “Òdodo Rẹ̀” Lákọ̀ọ́kọ́Ilé Ìṣọ́—2010 | October 15
-
-
a Bí ọ̀mọ̀wé kan ṣe sọ, ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n túmọ̀ sí “gbé kalẹ̀” tún lè túmọ̀ sí ‘láti gbé ère ìrántí kalẹ̀.’ Torí náà, a kúkú lè sọ pé ńṣe làwọn Júù wọ̀nyẹn ń gbé ère ìrántí kan kalẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ fún ìyìn ara wọn, kì í ṣe láti yin Ọlọ́run.
-