-
Báwo La Ṣe Lè Mọ Ìjọsìn Tí Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
2. Báwo ló ṣe yẹ ká máa jọ́sìn Jèhófà?
Nítorí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, a ò gbọ́dọ̀ mú nǹkan míì mọ́ ìjọsìn rẹ̀. (Ìfihàn 4:11) Ìyẹn ni pé a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ká máa sin òun nìkan ṣoṣo, ká má ṣe sin òrìṣà èyíkéyìí, ká má sì lo ère nínú ìjọsìn wa.—Ka Àìsáyà 42:8.
Ìjọsìn wa gbọ́dọ̀ jẹ́ ‘mímọ́, kó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà’ lójú Jèhófà. (Róòmù 12:1) Ìyẹn ni pé a gbọ́dọ̀ máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá àwọn ìlànà rẹ̀ mu. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà máa ń nífẹ̀ẹ́ ìlànà rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó, wọ́n sì máa ń tẹ̀ lé e. Wọn kì í ṣe ohun tó máa pa wọ́n lára, irú bíi mímu sìgá, mímu igbó, fífín tábà tàbí aáṣà, lílo oògùn olóró tàbí mímu ọtí lámujù.a
-
-
Fi Hàn Pé O Mọyì Ẹ̀míGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
3. Máa tọ́jú ara ẹ
Àwọn Kristẹni tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà máa ń lo gbogbo àkókò àti okun wọn láti sin Jèhófà. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n fi ara wọn rúbọ sí i. Ka Róòmù 12:1, 2, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí pàtàkì tó fi yẹ kó o máa tọ́jú ara ẹ?
Àwọn ọ̀nà wo lo lè máa gbà tọ́jú ara ẹ?
-