ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ta Ló Ń Darí Èrò Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́—1999 | April 1
    • Fún ìdí yìí, Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n “jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí.” (Róòmù 12:2) Ọ̀gbẹ́ni olùtúmọ̀ Bíbélì kan tún ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù sọ lọ́nà yìí: “Má ṣe jẹ́ kí ayé tó yí ẹ ká mú ẹ bá bátànì tirẹ̀ mu.” (Róòmù 12:2, Phillips) Sátánì yóò dá gbogbo àrà tó bá lè dá láti mú ẹ bá bátànì tirẹ̀ mu, gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò láyé àtijọ́ ti máa ń ṣu amọ̀ sínú bátànì kan kí ìkòkò náà lè rí bó ti fẹ́. Iṣẹ́ yẹn ni Sátánì ń fi ìṣèlú, iṣẹ́ ajé, ẹ̀sìn, àti eré ìtura ayé ṣe. Báwo tilẹ̀ ni agbára Sátánì ti rinlẹ̀ tó? Bó ṣe gbèèràn lọ́jọ́ àpọ́sítélì Jòhánù ló rí lónìí. Jòhánù sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19; tún wo 2 Kọ́ríńtì 4:4.) Bóo bá ń ṣiyèméjì nípa bí agbára Sátánì ti pọ̀ tó láti tan àwọn èèyàn jẹ, kí ó sì sọ ìrònú wọn dìbàjẹ́, rántí bó ṣe tan odindi orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì jẹ pátápátá, orílẹ̀-èdè tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 10:6-12) Ohun kan náà ha lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ bí? Ó lè ṣẹlẹ̀, bóo bá ṣí èrò inú rẹ sílẹ̀ fún agbára ẹ̀tàn Sátánì.

  • Ta Ló Ń Darí Èrò Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́—1999 | April 1
    • Ìwọ ni yóò pinnu ohun tóo fẹ́ ṣe. O lè yàn láti máa ‘dáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí,’ nípa jíjẹ́ kí ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ojú ìwòye ayé yìí jọba lé ìrònú rẹ. (Róòmù 12:2) Ṣùgbọ́n ayé yìí kò ro rere sí ẹ. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi kì wá nílọ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn.” (Kólósè 2:8) Kò ná Sátánì ní ohunkóhun láti tipa báyìí mú wa bá bátànì tirẹ̀ mu, tàbí kó ‘gbé wa lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀.’ Bí èéfín sìgá tí afẹ́fẹ́ gbé wá sọ́dọ̀ ẹni ló rí. Wíwulẹ̀ mí afẹ́fẹ́ burúkú náà símú lè nípa lórí rẹ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́