ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ‘Ẹ Jẹ́ Kí Iná Ẹ̀mí Máa Jó Nínú Yín’
    Ilé Ìṣọ́—2009 | October 15
    • 9. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi fàwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí bí wé àwọn ẹ̀yà tó wà nínú ara kan?

      9 Ka Róòmù 12:4, 5, 9, 10. Pọ́ọ̀lù fi àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wé àwọn ẹ̀yà tó wà nínú ara kan, ó ní wọ́n ń sìn níṣọ̀kan lábẹ́ Kristi tó jẹ́ Orí wọn. (Kól. 1:18) Ó rán àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí bí yìí létí pé oríṣiríṣi ẹ̀yà ló wà nínú ara, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní iṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Pọ́ọ̀lù sọ pé bákan náà “bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé [àwọn ẹni àmì òróró náà] pọ̀, [wọ́n] jẹ́ ara kan ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi.” Lọ́nà kan náà, ó gba àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà ní Éfésù níyànjú pé: “Ẹ jẹ́ kí a fi ìfẹ́ dàgbà sókè nínú ohun gbogbo sínú ẹni tí í ṣe orí, Kristi. Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni gbogbo ara náà, nípa síso wọ́n pọ̀ ní ìṣọ̀kan àti mímú kí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nípasẹ̀ gbogbo oríkèé tí ń pèsè ohun tí a nílò, ní ìbámu pẹ̀lú ìṣiṣẹ́ olúkúlùkù ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan ní ìwọ̀n yíyẹ, ń mú kí ara náà dàgbà fún gbígbé ara rẹ̀ ró nínú ìfẹ́.”—Éfé. 4:15, 16.

  • ‘Ẹ Jẹ́ Kí Iná Ẹ̀mí Máa Jó Nínú Yín’
    Ilé Ìṣọ́—2009 | October 15
    • 11. Kí ló ń jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà láàárín wa, ìmọ̀ràn míì wo ni Pọ́ọ̀lù sì fún wa?

      11 Ìfẹ́ tó jẹ́ “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé” ló ń jẹ́ ká ní irú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀. (Kól. 3:14) Pọ́ọ̀lù gbé kókó yìí jáde nínú Róòmù orí 12, ó ní ìfẹ́ wa gbọ́dọ̀ wà “láìsí àgàbàgebè” àti pé “nínú ìfẹ́ ará” a gbọ́dọ̀ ní “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara [wa] lẹ́nì kìíní-kejì.” Èyí máa ń jẹ́ ká bọ̀wọ̀ fún ara wa. Ó tún sọ pé: “Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” Àmọ́ ṣá o, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ ru bò wá lójú débi tá ò fi ní mọ ohun tó tọ́. A gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti jẹ́ kí ìjọ wà ní mímọ́. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń fúnni nímọ̀ràn nípa ìfẹ́, ó ní: “Ẹ fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú, ẹ rọ̀ mọ́ ohun rere.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́