ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • 7. Àwọn òfin Ìjọba Ọlọ́run dáa ju ti ìjọba èèyàn lọ

      Ìjọba èèyàn máa ń ṣe àwọn òfin tí wọ́n gbà pé ó máa ṣe aráàlú láǹfààní tó sì máa dáàbò bò wọ́n. Bákan náà, Ìjọba Ọlọ́run ní àwọn òfin tí àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run náà gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé. Ka 1 Kọ́ríńtì 6:9-​11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Báwo lo ṣe rò pé ayé máa rí lọ́jọ́ iwájú nígbà tí gbogbo èèyàn bá ń tẹ̀ lé àwọn òfin Ọlọ́run?a

      • Ṣé o rò pé ó bọ́gbọ́n mu bí Jèhófà ṣe sọ pé káwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run máa tẹ̀ lé àwọn òfin yìí? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

      • Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn tí kì í tẹ̀ lé àwọn òfin yìí lè yí pa dà?​—Wo ẹsẹ 11.

      Ọlọ́pàá kan dá mọ́tò dúró ní oríta kan táwọn èèyàn ti ń lọ tí wọ́n ń bọ̀. Àwọn èèyàn lọ́mọdé àti lágbá ń sọdá títì.

      Ìjọba èèyàn máa ń ṣe àwọn òfin tí wọ́n gbà pé ó máa ṣe aráàlú láǹfààní tó sì máa dáàbò bò wọ́n. Àmọ́ àwọn òfin Ìjọba Ọlọ́run ṣàǹfààní gan-an ju ti ìjọba èèyàn lọ

  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìbálòpọ̀?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • Ẹ̀kọ́ 41. Ọkùnrin kan àti obìnrin kan di ara wọn lọ́wọ́ mú.

      Ẹ̀KỌ́ 41

      Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìbálòpọ̀?

      Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀. Àmọ́ Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ dáadáa, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó fọ̀wọ̀ hàn. Ohun tí Bíbélì bá sọ máa ń ṣe wá láǹfààní gan-an. Bó sì ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn, torí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa. Ó mọ ohun tó dáa jù fún wa. Ó sọ bá a ṣe lè fi ìwà àti ìṣe wa múnú òun dùn àti ohun tó yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ gbádùn ayé wa títí láé.

      1. Kí ni Jèhófà sọ nípa ìbálòpọ̀?

      Ìbálòpọ̀ jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà. Àwọn tọkọtaya sì ni Jèhófà fẹ́ kí wọ́n máa ní ìbálòpọ̀. Kì í ṣe torí ọmọ bíbí nìkan ni Jèhófà ṣe fún wọn lẹ́bùn yìí, àmọ́ ó tún jẹ́ ọ̀nà láti gbà fìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn sí ara wọn, kí wọ́n sì gbádùn ara wọn. Ìdí nìyẹn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi sọ pé: “Máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ.” (Òwe 5:18, 19) Jèhófà fẹ́ káwọn tọkọtaya Kristẹni jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn, ìyẹn ni kò ní jẹ́ kí wọ́n ṣe àgbèrè.​—Ka Hébérù 13:4.

      2. Kí ni ìṣekúṣe?

      Bíbélì sọ pé “àwọn oníṣekúṣe . . . kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Ọ̀rọ̀ náà por·neiʹa ni àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì lò nígbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣekúṣe. Lára ohun tó túmọ̀ sí ni (1) kí àwọn tí kì í ṣe tọkọtaya máa bá ara wọn lò pọ̀,a (2) kí ọkùnrin àti ọkùnrin tàbí obìnrin àti obìnrin máa bá ara wọn lò pọ̀, àti (3) kí èèyàn máa bá ẹranko lò pọ̀. Tá a bá ń “ta kété sí ìṣekúṣe,” a máa jàǹfààní púpọ̀, a sì máa múnú Jèhófà dùn.​—1 Tẹsalóníkà 4:3.

      KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

      Jẹ́ ká wo bá a ṣe lè máa sá fún ìṣekúṣe àti àǹfààní tó o máa rí tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀.

      Jósẹ́fù ń sá fún ìyàwó Pọ́tífárì. Ìyàwó Pọ́tífárì di aṣọ Jósẹ́fù mú.

      3. Máa sá fún ìṣekúṣe

      Ńṣe ni ọkùnrin olóòótọ́ náà Jósẹ́fù jà fitafita kó lè sá fún ìṣekúṣe. Ka Jẹ́nẹ́sísì 39:1-12, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Kí nìdí pàtàkì tí Jósẹ́fù fi sá fún ìṣekúṣe?​—Wo ẹsẹ 9.

      • Ṣé o rò pé ó bọ́gbọ́n mu bí Jósẹ́fù ṣe sá fún ìṣekúṣe? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

      Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè sá fún ìṣekúṣe bíi ti Jósẹ́fù? Wo FÍDÍÒ yìí.

      FÍDÍÒ: Sá fún Ìṣekúṣe (5:06)

      Jèhófà fẹ́ ká máa sá fún ìṣekúṣe. Ka 1 Kọ́ríńtì 6:18, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Àwọn nǹkan wo ló lè mú kéèyàn jìn sọ́fìn ìṣekúṣe?

      • Báwo lo ṣe lè máa sá fún ìṣekúṣe?

      4. O lè borí ìdẹwò!

      Kí ló lè mú kó nira láti sá fún ìṣekúṣe? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

      FÍDÍÒ: Máa Ka Bíbélì Kó O Lè Borí Ìdẹwò (3:02)

      • Nínú fídíò yẹn, kí ni arákùnrin yẹn ṣe nígbà tó rí i pé àwọn nǹkan tí òun ń rò àtàwọn nǹkan tí òun ń ṣe lè mú kóun ṣe ìṣekúṣe?

      Àwọn Kristẹni olóòótọ́ náà máa ń jà fitafita kí èrò tí kò dáa má bàa jọba lọ́kàn wọn. Kí lo lè ṣe kí èròkérò má bàa jọba lọ́kàn ẹ? Ka Fílípì 4:8, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká máa ronú lé lórí?

      • Tá a bá ń ka Bíbélì tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà báwo nìyẹn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa jìn sọ́fìn ẹ̀ṣẹ̀?

      5. Àwọn ìlànà Jèhófà máa ń ṣe wá láǹfààní

      Jèhófà mọ ohun tó dáa jù fún wa. Ó sọ bá a ṣe lè sá fún ìṣekúṣe àti àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ka Òwe 7:7-27 tàbí kó o wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

      FÍDÍÒ: Ẹni Tí Kò Ní Làákàyè (9:31)

      • Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin yẹn ṣe kó ara ẹ̀ síṣòro?​—Wo Òwe 7:8, 9.

      • Òwe 7:23, 26 jẹ́ ká mọ̀ pé ìṣekúṣe lè kó wa síṣòro ńlá. Tá a bá ń sá fún ìṣekúṣe, àwọn ìṣòro wo la ò ní kó sí?

      • Tá a bá ń sá fún ìṣekúṣe, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká gbádùn ayé wa títí láé?

      Bíbélì sọ pé àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀ àti àwọn obìnrin tó ń bá obìnrin lò pọ̀ kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn kan gbà pé ohun tí Bíbélì sọ yìí kò bọ́gbọ́n mu. Àmọ́, Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an ni, ó sì fẹ́ kí gbogbo wa máa gbádùn ayé wa títí láé. Torí náà, tá a bá fẹ́ gbádùn ayé wa títí láé, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà ẹ̀. Ka 1 Kọ́ríńtì 6:9-11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Ṣé kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lò pọ̀ tàbí kí obìnrin máa bá obìnrin lò pọ̀ nìkan ni Ọlọ́run sọ pé kò dáa?

      Tá a bá fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn, gbogbo wa la gbọ́dọ̀ ṣe àwọn àyípadà kan tàbí òmíì. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa sapá gan-an láti ṣe àwọn àyípadà náà? Ka Sáàmù 19:8, 11, kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Ṣé o rò pé àwọn ìlànà Jèhófà bọ́gbọ́n mu? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

      Àwòrán: 1. Ọmọbìnrin kan àti ọ̀rẹ́kùnrin ẹ̀ jọ jókòó, inú ọmọbìnrin náà ò dùn. Òun àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ ń mu ọtí àti sìgá nílé fàájì lọ́wọ́ alẹ́. 2. Ọmọbìnrin yẹn ń rẹ́rìn-ín bó ṣe ń bá arábìnrin kan sọ̀rọ̀ ní ilé ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

      Jèhófà ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Ó lè ran ìwọ náà lọ́wọ́

      ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Táwọn méjì bá ṣáà ti nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kò burú tí wọ́n bá bá ara wọn lò pọ̀.”

      • Kí lèrò tìẹ?

      KÓKÓ PÀTÀKÌ

      Ìbálòpọ̀ jẹ́ ẹ̀bùn tí Jèhófà fún àwọn tọkọtaya kí wọ́n lè máa fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn sí ara wọn, kí wọ́n sì máa gbádùn ara wọn.

      Kí lo rí kọ́?

      • Àwọn apá wo ni àgbèrè pín sí?

      • Tá ò bá fẹ́ jìn sọ́fìn ìṣekúṣe, kí ló yẹ ká máa ṣe?

      • Tá a bá ń sá fún ìṣekúṣe bí Jèhófà ṣe sọ, àǹfààní wo ló máa ṣe wá?

      Ohun tó yẹ kó o ṣe

      ṢÈWÁDÌÍ

      Ka ìwé yìí, kó o lè mọ̀ bóyá ó ṣe pàtàkì sí Ọlọ́run pé kí ọkùnrin àti obìnrin ṣègbéyàwó kí wọ́n tó máa gbé pọ̀.

      “Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Gbígbé Pọ̀ Láìṣègbéyàwó?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

      Ka ìwé yìí kó o lè rí i pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kí ọkùnrin àti ọkùnrin máa bá ara wọn lò pọ̀ tàbí kí obìnrin àti obìnrin máa bá ara wọn lò pọ̀ kò dáa rárá, síbẹ̀ èyí ò túmọ̀ sí pé ká kórìíra àwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀.

      “Ṣó Burú Kí Ọkùnrin Máa Fẹ́ Ọkùnrin àbí Kí Obìnrin Máa Fẹ́ Obìnrin?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

      Ka ìwé yìí kó o lè rí i pé ńṣe ni àwọn ìlànà Ọlọ́run nípa ìbálòpọ̀ ń dáàbò bò wá.

      “Ṣé A Lè Ka Fífi Ẹnu Lá Ẹ̀yà Ìbímọ Ẹlòmíì sí Ìbálòpọ̀?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

      Ka ìtàn tí àkòrí ẹ̀ sọ pé “Wọ́n Bọ̀wọ̀ Fún Mí,” kó o lè rí ohun tó mú kí ọkùnrin kan tó máa ń bá ọkùnrin bíi tiẹ̀ lò pọ̀ ṣe àyípadà kó lè máa múnú Ọlọ́run dùn.

      “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” (Ilé Ìṣọ́, April 1, 2011)

      a Lára àwọn apá tí àgbèrè pín sí ni ìbálòpọ̀ ní tààràtà, fífi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì, ìbálòpọ̀ láti ihò ìdí àti kéèyàn máa fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì.

  • Ṣó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Mu Ọtí?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • Ẹ̀kọ́ 43. Ọtí líle àti ọtí ẹlẹ́rìndòdò wà lórí tábìlì níbi àpèjẹ kan.

      Ẹ̀KỌ́ 43

      Ṣó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Mu Ọtí?

      Kárí ayé, èrò tó yàtọ̀ síra làwọn èèyàn ní nípa ọtí mímu. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn kan máa ń mu ọtí pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Àwọn kan sì wà tí wọn kì í mutí rárá. Àmọ́, ńṣe làwọn kan máa ń mutí yó. Kí ni Bíbélì sọ nípa ọtí mímu?

      1. Ṣé ó burú kéèyàn máa mu ọtí?

      Bíbélì ò sọ pé ká má mu ọtí. Dípò ìyẹn, nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún àwa èèyàn, ó ka “wáìnì tó ń mú ọkàn èèyàn yọ̀” mọ́ àwọn ẹ̀bùn náà. (Sáàmù 104:14, 15) Kódà, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan wà tí Bíbélì sọ pé wọ́n mu ọtí.—1 Tímótì 5:23.

      2. Ìmọ̀ràn wo ni Bíbélì fún wa nípa ọtí?

      Jèhófà ò fẹ́ ká máa mutí lámujù tàbí ká máa mutí yó. (Gálátíà 5:21) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Má ṣe wà lára àwọn tó ń mu wáìnì lámujù.” (Òwe 23:20) Torí náà, tá a bá fẹ́ mu ọtí, ì báà jẹ́ nínú ilé tàbí níta, kò yẹ ká ki àṣejù bọ̀ ọ́. Torí pé tá a bá mutí lámujù, a ò ní lè ronú lọ́nà tó tọ́, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ tí kò yẹ ká sọ, a lè hùwà tí kò yẹ ká hù, ó sì lè mú ká máa ṣàìsàn. Tá a bá rí i pé a ò lè mutí níwọ̀nba, á kúkú dáa ká má mutí mọ́ rárá.

      3. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún ìpinnu táwọn míì ṣe nípa ọtí mímu?

      Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa pinnu bóyá òun máa mu ọtí àbí òun ò ní mu. Tí ẹnì kan bá pinnu pé òun á mutí níwọ̀nba, kò yẹ ká fojú burúkú wo onítọ̀hún. Bákan náà, tí ẹnì kan bá sọ pé òun ò mutí, a ò gbọ́dọ̀ fipá mú un. (Róòmù 14:10) A lè yàn láti má mu ọtí láwọn ìgbà tá a bá rí i pé ó lè mú àwọn ẹlòmíì kọsẹ̀. (Ka Róòmù 14:21.) Bíbélì sọ pé “kí kálukú máa wá ire ti ẹlòmíì, kì í ṣe ti ara rẹ̀.”—Ka 1 Kọ́ríńtì 10:23, 24.

      KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

      Jẹ́ ká wo àwọn ìlànà Bíbélì tó máa jẹ́ ká lè pinnu bóyá ó yẹ ká mutí tàbí kò yẹ àti bí ọtí tá a fẹ́ mu ṣe yẹ kó pọ̀ tó. Bákan náà, wàá tún rí ohun tó o lè ṣe tó o bá níṣòro ọtí mímu.

      4. Ìwọ lo máa pinnu bóyá wàá mutí àbí o ò ní mu

      Kí ni èrò Jésù nípa ọtí mímu? Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, jẹ́ ká wo iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ tí Jésù ṣe. Ka Jòhánù 2:1-11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Kí ni iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa èrò ẹ̀ lórí ọtí àti ojú tó fi ń wo àwọn tó ń mu ọtí?

      • Nígbà tó jẹ́ pé Jésù ò sọ pé ọtí mímu ò dáa, ṣó yẹ kí Kristẹni kan máa fojú burúkú wo àwọn tó bá ń mutí?

      Àmọ́, tí Kristẹni kan bá tiẹ̀ lómìnira láti mutí, kì í ṣe gbogbo ìgbà náà ló bọ́gbọ́n mu pé kó máa mutí. Ka Òwe 22:3, lẹ́yìn náà kó o wò ó bóyá ó yẹ kó o mutí:

      • Tó o bá fẹ́ wa mọ́tò tàbí o fẹ́ fi ẹ̀rọ kan ṣiṣẹ́.

      • Tó o bá lóyún.

      • Tí dókítà bá sọ pé kó o má mutí mọ́.

      • Tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà lo máa ń mu ọtí lámujù.

      • Tí òfin ìjọba ò bá gbà ẹ́ láyè láti mutí.

      • Tó o bá wà pẹ̀lú ẹnì kan tí kì í fẹ́ mutí rárá, torí pé o ti fìgbà kan níṣòro ọtí mímu.

      Ṣó yẹ kó o fáwọn èèyàn ní ọtí níbi ìgbéyàwó ẹ tàbí níbi àpèjẹ míì? Kó o lè mọ ìpinnu ti wàá ṣe, wo FÍDÍÒ yìí.

      FÍDÍÒ: Ṣó Yẹ Kí N Fún Àwọn Èèyàn Ní Ọtí Níbi Ìgbéyàwó Mi? (2:41)

      Ka Róòmù 13:13 àti 1 Kọ́ríńtì 10:31, 32. Lẹ́yìn tó o bá ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹsẹ Bíbélì náà, dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Tó o bá ń tẹ̀ lé ìlànà yìí, báwo nìyẹn ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu táá múnú Jèhófà dùn?

      Arákùnrin kan wà nílé oúnjẹ, ó sọ pé òun ò fẹ́ ọtí. Àwọn arábìnrin méjì tó wà pẹ̀lú ẹ̀ ń mu wáìnì.

      Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bóyá òun máa mu ọtí àbí òun ò ní mu. Àwọn ìgbà míì sì wà tẹ́nì kan lè rí i pé ohun tó máa dáa jù ni pé kí òun má mu ọtí

      5. Má ṣe mu ọtí lámujù

      Tó o bá fẹ́ mu ọtí, fi sọ́kàn pé: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ò sọ pé ká má ṣe mutí, ó sọ pé a ò gbọ́dọ̀ mutí lámujù. Kí nìdí? Ka Hósíà 4:11, 18, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Tẹ́nì kan bá ń mutí lámujù, kí ló lè ṣẹlẹ̀?

      Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa mutí lámujù? A gbọ́dọ̀ mọ̀wọ̀n ara wa, ká má kọjá àyè wa. Ka Òwe 11:2, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Kí nìdí tó fi yẹ kó o mọ̀wọ̀n ara ẹ tó bá dọ̀rọ̀ ọtí mímu?

      6. Pinnu pé wàá jáwọ́ nínú ọtí àmujù

      Jẹ́ ká wo ohun tó mú kí ọkùnrin kan jáwọ́ nínú ọtí àmujù. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

      FÍDÍÒ: ‘Ọ̀rọ̀ Ara Mi Sú Mi’ (6:32)

      Àwòrán: Àwọn apá kan nínú fídíò náà ‘Ọ̀rọ̀ Ara Mi Sú Mi.’ 1. Dmitry ń wo ìgò ọtí tó wà lọ́wọ́ ẹ̀. 2. Dmitry, ìyàwó ẹ̀ àti ọmọbìnrin wọn ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀.
      • Nínú fídíò yẹn, báwo ni Dmitry ṣe máa ń ṣe tó bá ti mutí yó?

      • Ṣé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló jáwọ́ nínú ọtí mímu?

      • Kí ló ràn án lọ́wọ́ tó fi bọ́ lọ́wọ́ ọtí àmujù?

      Ka 1 Kọ́ríńtì 6:10, 11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Kí ni Bíbélì sọ nípa mímu ọtí lámujù?

      • Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn tó ń mu ọtí àmujù lè yí pa dà?

      Ka Mátíù 5:30, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Ohun tí gígé ọwọ́ sọ nù ń ṣàpẹẹrẹ ni pé kẹ́nì kan sapá gan-an láti jáwọ́ nínú àṣà kan tó ti mọ́ ọn lára kó lè múnú Jèhófà dùn. Kí lo lè ṣe tó bá ṣòro fún ẹ láti jáwọ́ nínú ọtí àmujù?a

      Ka 1 Kọ́ríńtì 15:33, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Tó bá jẹ́ pé àwọn tó ń mutí àmujù lò ń bá rìn, kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ?

      ẸNÌ KAN LÈ BÉÈRÈ PÉ: “Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ ni kéèyàn mu ọtí?”

      • Kí lo máa sọ?

      KÓKÓ PÀTÀKÌ

      Ọtí wà lára àwọn nǹkan rere tí Jèhófà fún àwa èèyàn láti máa fi gbádùn ara wa. Àmọ́, kò fẹ́ ká máa mutí lámujù tàbí ká máa mutí lámupara.

      Kí lo rí kọ́?

      • Kí ni Bíbélì sọ nípa ọtí?

      • Àkóbá wo ni ọtí àmujù lè ṣe fún wa?

      • Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún ìpinnu táwọn míì ṣe nípa ọtí mímu?

      Ohun tó yẹ kó o ṣe

      ṢÈWÁDÌÍ

      Wo fídíò yìí kó o lè mọ bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè ṣe ìpinnu tó dáa tó bá dọ̀rọ̀ ọtí mímu.

      Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọtí Di Ìdẹkùn fún Ẹ (2:31)

      Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tó yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọtí àmujù.

      “Èrò Tó Yẹ Kó O Ní Nípa Ọtí Mímu” (Ilé Ìṣọ́, January 1, 2010)

      Ṣó yẹ káwọn Kristẹni máa na ife ọtí sókè láti fi kan tí ẹlòmíì?

      “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” (Ilé Ìṣọ́, February 15, 2007)

      Ka ìtàn ọkùnrin kan tí ọtí mímu ti di bárakú fún, àmọ́ tó bọ́ lọ́wọ́ àṣà yìí nígbà tó yá. Àkòrí ìtàn náà ni “Òkú ọ̀mùtí ni mí.”

      “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” (Ilé Ìṣọ́, May 1, 2012)

      a Tí ọtí àmujù bá ti di bárakú fún ẹnì kan, ohun tó máa dáa ni pé kó lọ rí àwọn dókítà tó máa ń tọ́jú àwọn tí ọtí ti di bárakú fún. Ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn dókítà sọ ni pé tẹ́nì kan bá ti níṣòro ọtí mímu rí, kò yẹ kónítọ̀hún tún fẹnu kan ọtí mọ́ rárá.

  • Kí Lo Lè Ṣe Tó O Bá Dá Ẹ̀ṣẹ̀ Tó Burú Gan-an?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • Ó dájú pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, o sì ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kó o má bàa rú òfin rẹ̀. Síbẹ̀, kò sí bó o ṣe lè ṣe é tó ò ní ṣàṣìṣe. Àmọ́, nígbà míì ohun tó o ṣe lè burú gan-an. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, rántí pé ìyẹn ò ní kí Jèhófà má nífẹ̀ẹ́ rẹ mọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ó ṣe tán láti dárí jì ẹ́, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́.

      1. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dárí jì wá?

      Inú àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà máa ń bà jẹ́ tí wọ́n bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an. Àmọ́, ìlérí tí Jèhófà ṣe fáwọn èèyàn rẹ̀ máa ń fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sọ pé: “Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tiẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, wọ́n máa di funfun bíi yìnyín.” (Àìsáyà 1:18) Jèhófà máa dárí jì wá pátápátá tá a bá ronú pìwà dà látọkàn wá. Báwo la ṣe lè ronú pìwà dà? A máa kábàámọ̀ ohun tá a ṣe, ìyẹn á mú ká jáwọ́ nínú ìwà tí ò dáa náà, àá sì bẹ Jèhófà pé kó dárí jì wá. Lẹ́yìn ìyẹn, àá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè borí ohunkóhun tó mú ká hu ìwà tí ò dáa náà, àá sì gbìyànjú láti máa tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà nígbà gbogbo.​—Ka Àìsáyà 55:6, 7.

      2. Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo àwọn alàgbà láti ràn wá lọ́wọ́ tá a bá dẹ́ṣẹ̀?

      Tá a bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, Jèhófà sọ fún wa pé ká “pe àwọn alàgbà ìjọ.” (Ka Jémíìsì 5:14, 15.) Àwọn alàgbà yìí nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ará. Torí náà, Jèhófà ti kọ́ wọn lóhun tí wọ́n máa ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú òun.​—Gálátíà 6:1.

      Báwo làwọn alàgbà ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ tá a bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an? Àwọn alàgbà méjì sí mẹ́tà máa fi Bíbélì tọ́ wa sọ́nà ká lè mọ̀ pé ohun tá a ṣe ò dáa. Wọ́n máa jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tá a lè ṣe ká má bàa hu irú ìwà yẹn mọ́, wọ́n sì máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè lókun pa dà. Tẹ́ni tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú gan-an náà ò bá ronú pìwà dà, àwọn alàgbà máa yọ ọ́ kúrò nínú ìjọ kí wọ́n lè dáàbò bo ìjọ.

      KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

      Jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ tá a bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, kó o lè túbọ̀ rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.

      3. Ara máa tù wá tá a bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa

      Ó máa ń dun Jèhófà gan-an tá a bá ṣe ohun tí kò dáa, torí náà a gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa fún un. Ka Sáàmù 32:1-5, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa fún Jèhófà dípò ká máa bò ó mọ́lẹ̀?

      Lẹ́yìn tá a bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa fún Jèhófà, ó tún yẹ ká jẹ́ káwọn alàgbà ràn wá lọ́wọ́ kí ara lè tù wá. Wo FÍDÍÒ yìí, kó o sì dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

      FÍDÍÒ: “Àwọn Tí Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Ló Máa Ń Bá Wí” (3:01)

      • Nínú fídíò yẹn, báwo làwọn alàgbà ṣe ran Canon lọ́wọ́ kó lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà?

      Ó yẹ ká sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn alàgbà, láìfi nǹkan kan pa mọ́. Ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́. Ka Jémíìsì 5:16, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Àǹfààní wo la máa rí tá ò bá fọ̀rọ̀ pa mọ́ fáwọn alàgbà?

      Àwòrán: 1. Ẹ̀dùn ọkàn bá arákùnrin kan, ó sì fọwọ́ bojú. 2. Arákùnrin náà gbàdúrà sí Jèhófà. 3. Arákùnrin náà ń bá alàgbà kan sọ̀rọ̀ lórí fóònù. 4. Àwọn alàgbà mẹ́tà ń bá arákùnrin náà sọ̀rọ̀. 5. Arákùnrin náà ń rẹ́rìn-ín músẹ́ torí pé ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ ti mọ́.

      Jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ẹ fáwọn alàgbà láìfi ohunkóhun pa mọ́, kó o sì jẹ́ kí Jèhófà fìfẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́

      4. Jèhófà máa ń ṣàánú àwọn tó bá dẹ́ṣẹ̀

      Tẹ́nì kan bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú gan-an, tó sì kọ̀ láti tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà, a máa yọ ọ́ kúrò nínú ìjọ, a ò sì ní bá a ṣe wọléwọ̀de mọ́. Ka 1 Kọ́ríńtì 5:6, 11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Bó ṣe jẹ́ pé ìwúkàrà máa ń mú kí ìyẹ̀fun wú, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará ìjọ tí wọ́n bá ń ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí kò ronú pìwà dà?

      Bí Jèhófà ṣe máa ń ṣàánú àwa èèyàn aláìpé, àwọn alàgbà náà máa ń fàánú hàn sáwọn tá a ti yọ kúrò nínú ìjọ. Wọ́n máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìbáwí ò rọrùn, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti yọ kúrò nínú ìjọ ló ti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, tí wọ́n sì gbà pé bí wọ́n ṣe yọ àwọn ló ran àwọn lọ́wọ́ láti tún èrò àwọn ṣe.—Sáàmù 141:5.

      • Báwo ni ọwọ́ tí Jèhófà fi ń mú àwọn tó bá dẹ́ṣẹ̀ ṣe fi hàn pé ó ń fòye báni lò, ó jẹ́ aláàánú, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa?

      5. Jèhófà máa dárí jì wá tá a bá ronú pìwà dà

      Jésù sọ àpèjúwe tó jẹ́ ká mọ bó ṣe máa ń rí lára Jèhófà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà. Ka Lúùkù 15:1-7, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Kí ni àpèjúwe yìí jẹ́ kó o mọ̀ nípa Jèhófà?

      Ka Ìsíkíẹ́lì 33:11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè fi hàn pé a ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn?

      Olùṣọ́ àgùntàn kan rọra ń fi aṣọ di ojú ibi tí àgùntàn rẹ̀ ti fara pa.

      Bíi ti olùṣọ́ àgùntàn kan, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀, ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ ẹ́ lógún gan-an

      ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Mi ò fẹ́ sọ ẹ̀ṣẹ̀ tí mo dá fáwọn alàgbà, kí wọ́n má bàa yọ mí kúrò nínú ìjọ.”

      • Kí lo lè sọ fún ẹni tó bá sọ irú ọ̀rọ̀ yìí?

      KÓKÓ PÀTÀKÌ

      Tá a bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, àmọ́ tá a kábàámọ̀, tá a sì pinnu pé a ò ní hùwà náà mọ́, Jèhófà máa dárí jì wá.

      Kí lo rí kọ́?

      • Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa fún Jèhófà?

      • Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dárí jì wá?

      • Tá a bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ káwọn alàgbà ràn wá lọ́wọ́?

      Ohun tó yẹ kó o ṣe

      ṢÈWÁDÌÍ

      Wo fídíò yìí kó o lè mọ bí ọkùnrin kan ṣe rí i pé aláàánú ni Jèhófà nígbà tí Jèhófà ṣe ohun tó wà nínú Àìsáyà 1:18 fún un.

      Aláàánú Ni Jèhófà (5:02)

      Ka àpilẹ̀kọ yìí kó o lè mọ ohun táwọn alàgbà máa ń ṣe kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú gan-an.

      “Bá A Ṣe Lè Ṣàánú Ẹni Tó Dẹ́ṣẹ̀, Ká sì Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Ẹ̀” (Ilé Ìṣọ́, August 2024)

      Ka àpilẹ̀kọ yìí kó o lè mọ bá a ṣe ń fi ìfẹ́ àti àánú hàn sáwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà.

      “Báwọn Alàgbà Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tí Wọ́n Mú Kúrò Nínú Ìjọ” (Ilé Ìṣọ́, August 2024)

      Ka ìtàn yìí kó o lè mọ ohun tó mú kí ọkùnrin kan gbà pé Jèhófà ló fa òun pa dà sínú òtítọ́. Àkòrí ìtàn náà ni “Mo Ní Láti Pa Dà Sọ́dọ̀ Jèhófà.”

      “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” (Ilé Ìṣọ́, April 1, 2012)

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́