ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ṣó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Mu Ọtí?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • Ṣó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Mu Ọtí?

      Kárí ayé, èrò tó yàtọ̀ síra làwọn èèyàn ní nípa ọtí mímu. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn kan máa ń mu ọtí pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Àwọn kan sì wà tí wọn kì í mutí rárá. Àmọ́, ńṣe làwọn kan máa ń mutí yó. Kí ni Bíbélì sọ nípa ọtí mímu?

      1. Ṣé ó burú kéèyàn máa mu ọtí?

      Bíbélì ò sọ pé ká má mu ọtí. Dípò ìyẹn, nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún àwa èèyàn, ó ka “wáìnì tó ń mú ọkàn èèyàn yọ̀” mọ́ àwọn ẹ̀bùn náà. (Sáàmù 104:14, 15) Kódà, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan wà tí Bíbélì sọ pé wọ́n mu ọtí.—1 Tímótì 5:23.

      2. Ìmọ̀ràn wo ni Bíbélì fún wa nípa ọtí?

      Jèhófà ò fẹ́ ká máa mutí lámujù tàbí ká máa mutí yó. (Gálátíà 5:21) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Má ṣe wà lára àwọn tó ń mu wáìnì lámujù.” (Òwe 23:20) Torí náà, tá a bá fẹ́ mu ọtí, ì báà jẹ́ nínú ilé tàbí níta, kò yẹ ká ki àṣejù bọ̀ ọ́. Torí pé tá a bá mutí lámujù, a ò ní lè ronú lọ́nà tó tọ́, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ tí kò yẹ ká sọ, a lè hùwà tí kò yẹ ká hù, ó sì lè mú ká máa ṣàìsàn. Tá a bá rí i pé a ò lè mutí níwọ̀nba, á kúkú dáa ká má mutí mọ́ rárá.

      3. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún ìpinnu táwọn míì ṣe nípa ọtí mímu?

      Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa pinnu bóyá òun máa mu ọtí àbí òun ò ní mu. Tí ẹnì kan bá pinnu pé òun á mutí níwọ̀nba, kò yẹ ká fojú burúkú wo onítọ̀hún. Bákan náà, tí ẹnì kan bá sọ pé òun ò mutí, a ò gbọ́dọ̀ fipá mú un. (Róòmù 14:10) A lè yàn láti má mu ọtí láwọn ìgbà tá a bá rí i pé ó lè mú àwọn ẹlòmíì kọsẹ̀. (Ka Róòmù 14:21.) Bíbélì sọ pé “kí kálukú máa wá ire ti ẹlòmíì, kì í ṣe ti ara rẹ̀.”—Ka 1 Kọ́ríńtì 10:23, 24.

      KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

      Jẹ́ ká wo àwọn ìlànà Bíbélì tó máa jẹ́ ká lè pinnu bóyá ó yẹ ká mutí tàbí kò yẹ àti bí ọtí tá a fẹ́ mu ṣe yẹ kó pọ̀ tó. Bákan náà, wàá tún rí ohun tó o lè ṣe tó o bá níṣòro ọtí mímu.

      4. Ìwọ lo máa pinnu bóyá wàá mutí àbí o ò ní mu

      Kí ni èrò Jésù nípa ọtí mímu? Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, jẹ́ ká wo iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ tí Jésù ṣe. Ka Jòhánù 2:1-11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Kí ni iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa èrò ẹ̀ lórí ọtí àti ojú tó fi ń wo àwọn tó ń mu ọtí?

      • Nígbà tó jẹ́ pé Jésù ò sọ pé ọtí mímu ò dáa, ṣó yẹ kí Kristẹni kan máa fojú burúkú wo àwọn tó bá ń mutí?

      Àmọ́, tí Kristẹni kan bá tiẹ̀ lómìnira láti mutí, kì í ṣe gbogbo ìgbà náà ló bọ́gbọ́n mu pé kó máa mutí. Ka Òwe 22:3, lẹ́yìn náà kó o wò ó bóyá ó yẹ kó o mutí:

      • Tó o bá fẹ́ wa mọ́tò tàbí o fẹ́ fi ẹ̀rọ kan ṣiṣẹ́.

      • Tó o bá lóyún.

      • Tí dókítà bá sọ pé kó o má mutí mọ́.

      • Tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà lo máa ń mu ọtí lámujù.

      • Tí òfin ìjọba ò bá gbà ẹ́ láyè láti mutí.

      • Tó o bá wà pẹ̀lú ẹnì kan tí kì í fẹ́ mutí rárá, torí pé o ti fìgbà kan níṣòro ọtí mímu.

      Ṣó yẹ kó o fáwọn èèyàn ní ọtí níbi ìgbéyàwó ẹ tàbí níbi àpèjẹ míì? Kó o lè mọ ìpinnu ti wàá ṣe, wo FÍDÍÒ yìí.

      FÍDÍÒ: Ṣó Yẹ Kí N Fún Àwọn Èèyàn Ní Ọtí Níbi Ìgbéyàwó Mi? (2:41)

      Ka Róòmù 13:13 àti 1 Kọ́ríńtì 10:31, 32. Lẹ́yìn tó o bá ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹsẹ Bíbélì náà, dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Tó o bá ń tẹ̀ lé ìlànà yìí, báwo nìyẹn ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu táá múnú Jèhófà dùn?

      Arákùnrin kan wà nílé oúnjẹ, ó sọ pé òun ò fẹ́ ọtí. Àwọn arábìnrin méjì tó wà pẹ̀lú ẹ̀ ń mu wáìnì.

      Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bóyá òun máa mu ọtí àbí òun ò ní mu. Àwọn ìgbà míì sì wà tẹ́nì kan lè rí i pé ohun tó máa dáa jù ni pé kí òun má mu ọtí

      5. Má ṣe mu ọtí lámujù

      Tó o bá fẹ́ mu ọtí, fi sọ́kàn pé: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ò sọ pé ká má ṣe mutí, ó sọ pé a ò gbọ́dọ̀ mutí lámujù. Kí nìdí? Ka Hósíà 4:11, 18, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Tẹ́nì kan bá ń mutí lámujù, kí ló lè ṣẹlẹ̀?

      Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa mutí lámujù? A gbọ́dọ̀ mọ̀wọ̀n ara wa, ká má kọjá àyè wa. Ka Òwe 11:2, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Kí nìdí tó fi yẹ kó o mọ̀wọ̀n ara ẹ tó bá dọ̀rọ̀ ọtí mímu?

      6. Pinnu pé wàá jáwọ́ nínú ọtí àmujù

      Jẹ́ ká wo ohun tó mú kí ọkùnrin kan jáwọ́ nínú ọtí àmujù. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

      FÍDÍÒ: ‘Ọ̀rọ̀ Ara Mi Sú Mi’ (6:32)

      Àwòrán: Àwọn apá kan nínú fídíò náà ‘Ọ̀rọ̀ Ara Mi Sú Mi.’ 1. Dmitry ń wo ìgò ọtí tó wà lọ́wọ́ ẹ̀. 2. Dmitry, ìyàwó ẹ̀ àti ọmọbìnrin wọn ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀.
      • Nínú fídíò yẹn, báwo ni Dmitry ṣe máa ń ṣe tó bá ti mutí yó?

      • Ṣé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló jáwọ́ nínú ọtí mímu?

      • Kí ló ràn án lọ́wọ́ tó fi bọ́ lọ́wọ́ ọtí àmujù?

      Ka 1 Kọ́ríńtì 6:10, 11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Kí ni Bíbélì sọ nípa mímu ọtí lámujù?

      • Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn tó ń mu ọtí àmujù lè yí pa dà?

      Ka Mátíù 5:30, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Ohun tí gígé ọwọ́ sọ nù ń ṣàpẹẹrẹ ni pé kẹ́nì kan sapá gan-an láti jáwọ́ nínú àṣà kan tó ti mọ́ ọn lára kó lè múnú Jèhófà dùn. Kí lo lè ṣe tó bá ṣòro fún ẹ láti jáwọ́ nínú ọtí àmujù?a

      Ka 1 Kọ́ríńtì 15:33, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Tó bá jẹ́ pé àwọn tó ń mutí àmujù lò ń bá rìn, kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ?

      ẸNÌ KAN LÈ BÉÈRÈ PÉ: “Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ ni kéèyàn mu ọtí?”

      • Kí lo máa sọ?

      KÓKÓ PÀTÀKÌ

      Ọtí wà lára àwọn nǹkan rere tí Jèhófà fún àwa èèyàn láti máa fi gbádùn ara wa. Àmọ́, kò fẹ́ ká máa mutí lámujù tàbí ká máa mutí lámupara.

      Kí lo rí kọ́?

      • Kí ni Bíbélì sọ nípa ọtí?

      • Àkóbá wo ni ọtí àmujù lè ṣe fún wa?

      • Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún ìpinnu táwọn míì ṣe nípa ọtí mímu?

      Ohun tó yẹ kó o ṣe

      ṢÈWÁDÌÍ

      Wo fídíò yìí kó o lè mọ bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè ṣe ìpinnu tó dáa tó bá dọ̀rọ̀ ọtí mímu.

      Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọtí Di Ìdẹkùn fún Ẹ (2:31)

      Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tó yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọtí àmujù.

      “Èrò Tó Yẹ Kó O Ní Nípa Ọtí Mímu” (Ilé Ìṣọ́, January 1, 2010)

      Ṣó yẹ káwọn Kristẹni máa na ife ọtí sókè láti fi kan tí ẹlòmíì?

      “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” (Ilé Ìṣọ́, February 15, 2007)

      Ka ìtàn ọkùnrin kan tí ọtí mímu ti di bárakú fún, àmọ́ tó bọ́ lọ́wọ́ àṣà yìí nígbà tó yá. Àkòrí ìtàn náà ni “Òkú ọ̀mùtí ni mí.”

      “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” (Ilé Ìṣọ́, May 1, 2012)

      a Tí ọtí àmujù bá ti di bárakú fún ẹnì kan, ohun tó máa dáa ni pé kó lọ rí àwọn dókítà tó máa ń tọ́jú àwọn tí ọtí ti di bárakú fún. Ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn dókítà sọ ni pé tẹ́nì kan bá ti níṣòro ọtí mímu rí, kò yẹ kónítọ̀hún tún fẹnu kan ọtí mọ́ rárá.

  • Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Múra Lọ́nà Tó Bójú Mu
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • Ẹ̀kọ́ 52. Obìnrin kan ń ṣèpinnu lórí irú aṣọ tó máa wọ̀.

      Ẹ̀KỌ́ 52

      Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Múra Lọ́nà Tó Bójú Mu

      Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló nírú aṣọ tó fẹ́ràn láti máa wọ̀, ọ̀nà tá à ń gbà múra sì yàtọ̀ síra. Jèhófà fún wa láwọn ìlànà tó rọrùn láti lóye nípa bá a ṣe lè múra. Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà yìí, àá máa wọ aṣọ tó bójú mu, àá sì máa múnú Jèhófà dùn. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn ìlànà yẹn.

      1. Àwọn ìlànà wo ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá fẹ́ pinnu irú aṣọ tá a máa wọ̀ àti bá a ṣe máa múra?

      Ó yẹ ká máa wọ “aṣọ tó bójú mu . . . pẹ̀lú ìmọ̀wọ̀n ara ẹni àti àròjinlẹ̀,” ká sì máa wà ní mímọ́ tónítóní nígbà gbogbo káwọn èèyàn lè rí i pé à ń “sin Ọlọ́run tọkàntọkàn.” (1 Tímótì 2:9, 10) Ronú nípa àwọn ìlànà mẹ́rin yìí: (1) Ó yẹ ká máa wọ aṣọ tó “bójú mu.” Ó ṣeé ṣe kó o ti kíyè sí i pé àwa èèyàn Jèhófà máa ń múra lọ́nà tó yàtọ̀ síra láwọn ìpàdé wa, síbẹ̀ ìmúra wa àti bá a ṣe ń ṣerun máa ń bọ̀wọ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run tá à ń sìn. (2) Tá a bá fẹ́ kí ìmúra wa fi hàn pé a ‘mọ̀wọ̀n ara wa’ a ò ní máa wọ aṣọ tá a mú káwọn èèyàn máa ronú nípa ìṣekúṣe, a ò sì ní máa múra torí káwọn èèyàn lè rí bá a ṣe lówó tó tàbí kí wọ́n lè máa kan sárá sí wa. (3) A máa fi hàn pé a ní “àròjinlẹ̀” tá a bá ń kíyè sára ká má bàa fara mọ́ gbogbo aṣọ àti ìmúra tó wà lóde. (4) Gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa múra lọ́nà táá fi hàn pé à ń “sin Ọlọ́run tọkàntọkàn” àti lọ́nà táá jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé Ọlọ́run tòótọ́ là ń sìn.​—1 Kọ́ríńtì 10:31.

      2. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú nípa àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tá a bá fẹ́ pinnu irú aṣọ tá a máa wọ̀?

      Òótọ́ ni pé a lómìnira láti múra lọ́nà tó wù wá, síbẹ̀ ó yẹ ká máa ro tàwọn míì tá a bá fẹ́ pinnu irú aṣọ tá a máa wọ̀. Kò yẹ ká máa múnú bí àwọn èèyàn, kàkà bẹ́ẹ̀ ó yẹ ká máa “ṣe ohun tó wu ọmọnìkejì [wa] fún ire rẹ̀, láti gbé e ró.”​—Ka Róòmù 15:1, 2.

      3. Báwo ni ìmúra wa ṣe lè mú kó wu àwọn èèyàn láti wá sin Jèhófà?

      Gbogbo ìgbà la máa ń fẹ́ wọ aṣọ tó bójú mu, àmọ́ a tún máa ń kíyè sára ní pàtàkì tá a bá ń lọ sáwọn ìpàdé ìjọ àtìgbà tá a bá fẹ́ lọ wàásù. Ìdí tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a ò fẹ́ káwọn èèyàn fojú àbùkù wo ìhìn rere tá à ń wàásù torí ìmúra wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, à ń múra lọ́nà táá mú kó wu àwọn èèyàn láti wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ká sì “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa . . . lọ́ṣọ̀ọ́.”​—Títù 2:10.

      KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

      Jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tá a lè ṣe ká lè máa wọ aṣọ tó bójú mu, ká sì máa múra lọ́nà tó máa fi hàn pé Kristẹni ni wá.

      Àwọn ọkùnrin méjì wà níwájú adájọ́. Ọ̀kan lára wọn wọ súùtù, èkejì sì wọ aṣọ tó rí wúruwùru, ó kọjú fìlà rẹ̀ sẹ́yìn.

      Ìmúra wa lè fi hàn bóyá a bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ àbí a ò bọ̀wọ̀ fún wọn. Òótọ́ ni pé Jèhófà rí ohun tó wà lọ́kàn wa, síbẹ̀ ó yẹ ká máa múra lọ́nà táá fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún un

      4. À ń bọ̀wọ̀ fún Jèhófà tá a bá ń múra lọ́nà tó bójú mu

      Kí nìdí tó ṣe pàtàkì jù tó fi yẹ ká máa múra lọ́nà tó bójú mu? Ka Sáàmù 47:2, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Tá a bá ń rántí pé à ń ṣojú fún Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká ṣèpinnu tó tọ́ lórí ọ̀rọ̀ aṣọ àti ìmúra wa?

      • Ṣé o rò pé ó bọ́gbọ́n mu ká máa ronú nípa aṣọ àti ìmúra wa tá a bá ń lọ sípàdé tàbí nígbà tá a bá fẹ́ lọ wàásù? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

      5. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa wọ aṣọ tó dáa, ká sì máa múra lọ́nà tó bójú mu?

      Wo FÍDÍÒ yìí.

      FÍDÍÒ: “Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọ́run” (10:18)

      Kò pọn dandan kí aṣọ wa jẹ́ olówó ńlá, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká máa wọ aṣọ tó mọ́ tónítóní, táá sì buyì kún ohun tá à ń ṣe. Ka 1 Kọ́ríńtì 10:24 àti 1 Tímótì 2:9, 10. Lẹ́yìn náà, kó o ronú lórí ìdí tí kò fi yẹ ká máa wọ aṣọ . . .

      • tó rí wúruwùru tàbí aṣọ tí kò bá ohun tá a fẹ́ ṣe mu.

      • tó fún mọ́ra, tó ṣí ara sílẹ̀ tàbí aṣọ èyíkéyìí tó lè mú káwọn èèyàn máa ronú nípa ìṣekúṣe.

      Kò pọn dandan káwa Kristẹni máa tẹ̀ lé Òfin Mósè, àmọ́ òfin náà lè jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe ń ronú. Ka Diutarónómì 22:5, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa wọ aṣọ tó máa ń jẹ́ kí ọkùnrin jọ obìnrin tàbí èyí tó máa ń jẹ́ kí obìnrin jọ ọkùnrin?

      Ka 1 Kọ́ríńtì 10:32, 33 àti 1 Jòhánù 2:15, 16, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Kí nìdí tó fi yẹ ká kíyè sí ohun tí àwọn aládùúgbò àtàwọn ará lè máa rò nípa ìmúra wa?

      • Báwo làwọn èèyàn ṣe sábà máa ń múra ládùúgbò yín?

      • Ṣé o rò pé gbogbo ìmúra yẹn ló bójú mu fún Kristẹni? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

      Ìmúra wa lè múnú Jèhófà dùn tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé aṣọ tó yàtọ̀ síra la wọ̀

      Àwọn ọkùnrin àtobìnrin tí ọjọ́ orí wọn yàtọ̀ síra, tí wọ́n sì wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Wọ́n wọ aṣọ ìṣeré àti oríṣiríṣi aṣọ míì tó bójú mu fún Kristẹni.

      ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Aṣọ tó bá wù mí ni mo lè wọ̀.”

      • Ṣé èrò tìẹ náà nìyẹn? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

      KÓKÓ PÀTÀKÌ

      A máa fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Jèhófà tá a bá ń múra lọ́nà tó bójú mu, ìyẹn á tún fi hàn pé a gba tàwọn míì rò.

      Kí lo rí kọ́?

      • Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú nípa ohun tí Jèhófà fẹ́ tá a bá fẹ́ pinnu irú aṣọ tá a máa wọ̀?

      • Àwọn ìlànà wo ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá fẹ́ pinnu irú aṣọ tá a máa wọ̀ àti bá a ṣe máa múra?

      • Kí ni ìmúra wa máa jẹ́ káwọn èèyàn rò nípa ìjọsìn tá à ń ṣe?

      Ohun tó yẹ kó o ṣe

      ṢÈWÁDÌÍ

      Ka àpilẹ̀kọ yìí kó o lè mọ ohun tó ṣeé ṣe káwọn èèyàn máa rò nípa rẹ torí aṣọ tó ò ń wọ̀.

      “Báwo Ni Ìmúra Mi Ṣe Rí?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

      Ka àpilẹ̀kọ yìí kó o lè mọ ìdí tó fi yẹ kó o ronú dáadáa kó o tó pinnu bóyá wàá fín àmì sára.

      “Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Fínfín Àmì sí Ara?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

      Ka ìwé yìí kó o lè mọ àwọn ìlànà míì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá fẹ́ ṣèpinnu lórí aṣọ tó o máa wọ̀ àti ìmúra rẹ.

      “Ǹjẹ́ Ìmúra Rẹ Ń Fògo fún Ọlọ́run?” (Ilé Ìṣọ́, September 2016)

      Kí ló ran obìnrin olóòótọ́ kan lọ́wọ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í gba tàwọn míì rò lórí ọ̀rọ̀ aṣọ àti ìmúra?

      “Ìmúra àti Ìwọṣọ Ni Kò Jẹ́ Kí N Tètè Rí Òtítọ́” (Jí!, March 8, 2004)

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́