-
Ẹ Ní Ìfẹ́ Tí Kì Í Kùnà LáéIlé Ìṣọ́—2009 | December 15
-
-
13. (a) Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2010? (b) Ọ̀nà wo ni ìfẹ́ kò fi ní kùnà láé?
13 Pọ́ọ̀lù wá jẹ́ ká mọ ohun tí ìfẹ́ máa ń ṣe àti ohun tí kì í ṣe. (Ka 1 Kọ́ríńtì 13:4-8.) Nínú ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn, fara balẹ̀ wo bó o ṣe ń hu àwọn ìwà tó ń fi hàn pé èèyàn ní ìfẹ́. Ìlà tó gbẹ̀yìn ẹsẹ keje àti gbólóhùn tó bẹ̀rẹ̀ ẹsẹ kẹjọ ni kó o kíyè sí jù lọ, èyí tó sọ pé: ‘Ìfẹ́ a máa fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í kùnà láé.’ Òun la fi ṣe ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2010. Wàá kíyè sí i pé ní ẹsẹ kẹjọ, Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí, irú bí ìsọtẹ́lẹ̀ àti ahọ́n àjèjì, yóò wá sópin. Àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí yìí ni wọ́n ń lò nígbà tí ìjọ Kristẹni ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Àmọ́ ìfẹ́ ní tiẹ̀ yóò máa wà títí lọ. Jèhófà fúnra rẹ̀ ni olú ìfẹ́, Jèhófà sì wà títí láé. Torí náà, ìfẹ́ kò ní kùnà láé, kò ní dópin láé. Títí láé ni yóò máa wà gẹ́gẹ́ bí ànímọ́ Ọlọ́run ayérayé.—1 Jòh. 4:8.
-
-
Ẹ Ní Ìfẹ́ Tí Kì Í Kùnà LáéIlé Ìṣọ́—2009 | December 15
-
-
Ìfẹ́ Kì Í Kùnà Láé
20, 21. (a) Kí nìdí tí ìfẹ́ fi ta yọ lọ́lá? (b) Kí nìdí tó o fi pinnu láti máa lépa ọ̀nà ìfẹ́ tó ta yọ ré kọjá?
20 Àwa èèyàn Jèhófà lóde òní ti rí ọgbọ́n tó wà nínú lílépa ìfẹ́ tó jẹ́ ọ̀nà títayọ ré kọjá. Ní tòótọ́, ìfẹ́ máa ń ta yọ nínú ohun gbogbo. Kíyè sí bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fa kókó yìí yọ. Lákọ̀ọ́kọ́, ó sọ pé àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí yóò dópin àti pé ìjọ Kristẹni tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ nígbà yẹn yóò fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa. Lẹ́yìn náà, ó wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Nísinsìnyí, bí ó ti wù kí ó rí, àwọn tí ó ṣì wà ni ìgbàgbọ́, ìrètí, ìfẹ́, àwọn mẹ́ta wọ̀nyí; ṣùgbọ́n èyí tí ó tóbi jù lọ nínú ìwọ̀nyí ni ìfẹ́.”—1 Kọ́r. 13:13.
21 Bó pẹ́ bó yá, àwọn ohun tá a ti ní ìgbàgbọ́ nínú wọn yóò ṣẹlẹ̀, táá sì wá di pé a ò ní láti nígbàgbọ́ nínú wọn mọ́. Bákan náà, nígbà tá a bá ti rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí tá a ti ń retí tipẹ́, tí ohun gbogbo sì ti dọ̀tun, a ò ní nílò ìrètí nínú wọn mọ́. Àmọ́ ìfẹ́ ńkọ́? Kò ní kùnà láé. Títí láé ló máa wà. Torí pé a máa wà láàyè títí láé, ó dájú pé a óò túbọ̀ máa rí oríṣiríṣi ọ̀nà tí ìfẹ́ Ọlọ́run pín sí, bẹ́ẹ̀ la ó sì máa lóye wọn. Tó o bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nípa lílépa ọ̀nà ìfẹ́ tó ta yọ ré kọjá, tí kì í kùnà láé, yóò ṣeé ṣe fún ọ láti dúró títí láé.—1 Jòh. 2:17.
-