ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ‘A Óò Gbé Àwọn Òkú Dìde’
    Ilé Ìṣọ́—1998 | July 1
    • 7. (a) Ọ̀ràn pàtàkì wo ni Pọ́ọ̀lù darí àfiyèsí sí? (b) Àwọn wo ni ó rí Jésù lẹ́yìn tí a jí i dìde?

      7 Nínú ẹsẹ méjì àkọ́kọ́ nínú 1 Kọ́ríńtì orí 15, Pọ́ọ̀lù gbé ẹṣin ọ̀rọ̀ tí ó fẹ́ jíròrò kalẹ̀, ó ní: “Ẹ̀yin ará, mo sọ ìhìn rere náà di mímọ̀ fún yín, èyí tí mo polongo fún yín, tí ẹ̀yin pẹ̀lú gbà, nínú èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú dúró, nípasẹ̀ èyí tí a tún ń gbà yín là, . . . àyàfi bí ó bá jẹ́ pé, ní ti tòótọ́, ẹ di onígbàgbọ́ lásán.” Bí àwọn ará Kọ́ríńtì bá kùnà láti dúró ṣinṣin nínú ìhìn rere, lásán ni wọ́n tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Pọ́ọ̀lù ń bá a lọ pé: “Mo fi lé yín lọ́wọ́, lára àwọn ohun àkọ́kọ́, èyíinì tí èmi pẹ̀lú gbà, pé Kristi kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí; àti pé a sin ín, bẹ́ẹ̀ ni, pé a ti gbé e dìde ní ọjọ́ kẹta gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí; àti pé ó fara han Kéfà, lẹ́yìn náà, àwọn méjìlá náà. Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han èyí tí ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, púpọ̀ jù lọ nínú àwọn tí wọ́n ṣì wà títí di ìsinsìnyí, ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ ti sùn nínú ikú. Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han Jákọ́bù, lẹ́yìn náà, gbogbo àpọ́sítélì; ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn gbogbo rẹ̀, ó fara han èmi pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a bí ní kògbókògbó.”—1 Kọ́ríńtì 15:3-8.

  • ‘A Óò Gbé Àwọn Òkú Dìde’
    Ilé Ìṣọ́—1998 | July 1
    • 10. (a) Kí ni ìyọrísí ìpàdé tí Jésù bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe gbẹ̀yìn? (b) Báwo ni Jésù ṣe fara han Pọ́ọ̀lù “gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a bí ní kògbókògbó”?

      10 Ẹlẹ́rìí títayọ mìíràn sí àjíǹde Jésù ni Jákọ́bù, ọmọ Jósẹ́fù àti Màríà, ìyá Jésù. Ṣáájú àjíǹde náà, ó hàn gbangba pé Jákọ́bù kò tíì di onígbàgbọ́. (Jòhánù 7:5) Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí Jésù fara han Jákọ́bù, ó di onígbàgbọ́, ó sì jọ pé ó kó ipa pàtàkì nínú yíyí àwọn arákùnrin rẹ̀ yòókù lọ́kàn padà. (Ìṣe 1:13, 14) Nínú ìpàdé tí Jésù bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe gbẹ̀yìn, nígbà tí ó fẹ́ gòkè re ọ̀run, ó yanṣẹ́ fún wọn láti “jẹ́ ẹlẹ́rìí . . . títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:6-11) Lẹ́yìn náà, ó fara han Sọ́ọ̀lù ará Tásù, ẹni tí ń ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni. (Ìṣe 22:6-8) Jésù fara han Sọ́ọ̀lù “gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a bí ní kògbókògbó.” Ṣe ni ó dà bí pé a ti jí Sọ́ọ̀lù dìde sí ìyè ti ẹ̀mí ná, tí ó sì lè rí Olúwa ògo náà ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún kí àjíǹde àwọn ẹni àmì òróró tó bẹ̀rẹ̀. Ìrírí yìí bẹ́gi dínà àtakò oníkúpani tí Sọ́ọ̀lù ń ṣe sí ìjọ Kristẹni, ó sì mú ìyípadà ńláǹlà wá. (Ìṣe 9:3-9, 17-19) Sọ́ọ̀lù di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ọ̀kan lára àwọn òléwájú olùgbèjà ìgbàgbọ́ Kristẹni.—1 Kọ́ríńtì 15:9, 10.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́