ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Ikú Ni A Ó Sọ Di Asán”
    Ilé Ìṣọ́—1998 | July 1
    • 10 “Òpin” náà ni òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, nígbà tí Jésù yóò fi Ìjọba náà lé Ọlọ́run àti Baba rẹ̀ lọ́wọ́ pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ àti ìdúróṣinṣin. (Ìṣípayá 20:4) Ète Ọlọ́run “láti tún kó ohun gbogbo jọpọ̀ nínú Kristi” ni a ó ti mú ṣẹ. (Éfésù 1:9, 10) Àmọ́ ṣá o, Kristi yóò ti kọ́kọ́ run “gbogbo ìjọba àti gbogbo ọlá àṣẹ àti agbára” tí ó tako ìfẹ́ Ọlọ́run Ọba Aláṣẹ. Èyí kọjá ìparun tí yóò wáyé ní Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 16:16; 19:11-21) Pọ́ọ̀lù wí pé: “[Kristi] gbọ́dọ̀ ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí Ọlọ́run yóò fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ni a ó sọ di asán.” (1 Kọ́ríńtì 15:25, 26) Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ohun tí ó tan mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú Ádámù ni a óò ti mú kúrò. Ó dájú pé nígbà yẹn, Ọlọ́run yóò ti sọ “ibojì ìrántí” dòfìfo nípa mímú àwọn òkú padà bọ̀ sí ìyè.—Jòhánù 5:28.

  • “Ikú Ni A Ó Sọ Di Asán”
    Ilé Ìṣọ́—1998 | July 1
    • 15. Kí ni ó túmọ̀ sí pé a óò “ṣèdájọ́” àwọn tí ń padà bọ̀ “láti inú nǹkan tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà”?

      15 Báwo ni a óò ṣe “ṣèdájọ́” àwọn tí yóò padà bọ̀ “láti inú nǹkan tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn”? Àkájọ ìwé wọ̀nyí kì í ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n ṣe látẹ̀yìnwá; nígbà tí wọ́n kú, a dá wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ nígbà ayé wọn. (Róòmù 6:7, 23) Àmọ́ ṣá o, àwọn ènìyàn tí a jí dìde yóò ṣì wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù. Nítorí náà, ó ní láti jẹ́ pé àkájọ ìwé wọ̀nyí yóò lànà àwọn ìtọ́ni àtọ̀runwá sílẹ̀, tí gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé láti lè jẹ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àǹfààní láti inú ẹbọ Jésù Kristi. Bí a ti mú gbogbo ohun tí ó jẹ mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù kúrò, ‘a ó sọ ikú di asán’ pátápátá. Nígbà tí ó bá máa fi di òpin ẹgbẹ̀rún ọdún náà, Ọlọ́run yóò “jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.” (1 Kọ́ríǹtì 15:28) Àwọn ènìyàn kò tún ní nílò iṣẹ́ Àlùfáà Àgbà tàbí Olùràpadà mọ́. Gbogbo aráyé ni a óò mú padà bọ̀ sípò ìjẹ́pípé tí Ádámù gbádùn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́