ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ṣé Iṣẹ́ Rẹ Yóò La Iná Já?
    Ilé Ìṣọ́—1998 | November 1
    • Fífi Àwọn Ohun Èlò Yíyẹ Kọ́lé

      9. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù gan-an ni ó fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀, àníyàn wo ni ó ní fún àwọn tí wọ́n tẹ́wọ́ gba òtítọ́ tí ó kọ́ wọn?

      9 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Wàyí o, bí ẹnikẹ́ni bá ń kọ́ wúrà, fàdákà, àwọn òkúta ṣíṣeyebíye, àwọn ohun èlò igi, koríko gbígbẹ, àgékù pòròpórò sórí ìpìlẹ̀ náà, iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò fara hàn kedere, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí a óò ṣí i payá nípasẹ̀ iná; iná náà fúnra rẹ̀ yóò sì fi ẹ̀rí irú ohun tí iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan jẹ́ hàn.” (1 Kọ́ríńtì 3:12, 13) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn? Gbé ipò tí ó yí ọ̀rọ̀ náà ká yẹ̀ wò. Lákọ̀ọ́kọ́, Pọ́ọ̀lù jẹ́ ẹni tí ń fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀. Nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀, ó rìnrìn àjò láti ìlú dé ìlú, ó sì wàásù fún ọ̀pọ̀ àwọn tí kò gbọ́ nípa Kristi rí. (Róòmù 15:20) Bí àwọn ènìyàn ti ń tẹ́wọ́ gba òtítọ́ tí ó fi kọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó ń dá ìjọ sílẹ̀. Pọ́ọ̀lù bìkítà púpọ̀ nípa àwọn olóòótọ́ wọ̀nyí. (2 Kọ́ríńtì 11:28, 29) Ṣùgbọ́n, iṣẹ́ rẹ̀ kò jẹ́ kí ó lè dúró sójú kan. Nítorí náà, lẹ́yìn tí ó ti lo oṣù 18 ní fífi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ ní Kọ́ríńtì, ó kọjá sí àwọn ìlú mìíràn láti lọ wàásù níbẹ̀. Síbẹ̀, ó ṣì fẹ́ mọ bí àwọn yòókù ṣe ń bójú tó iṣẹ́ tí òun ti ṣe sílẹ̀ níbẹ̀.—Ìṣe 18:8-11; 1 Kọ́ríńtì 3:6.

      10, 11. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi ìyàtọ̀ tí ó wà nínú onírúurú ohun èlò ìkọ́lé hàn? (b) Irú àwọn ilé gidi wo ni ó ṣeé ṣe kí ó ti wà ní Kọ́ríńtì ìgbàanì? (d) Irú àwọn ilé wo ni ó ṣeé ṣe jù lọ kí ó má gbiná, ẹ̀kọ́ wo sì ni èyí kọ́ àwọn Kristẹni tí ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn?

      10 Ó dà bíi pé díẹ̀ lára àwọn tí ń kọ́lé sórí ìpìlẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ ní Kọ́ríńtì kò ṣiṣẹ́ náà dáradára. Kí wọ́n lè mọ ohun tí ó jẹ́ ìṣòro náà, Pọ́ọ̀lù fi oríṣi ohun èlò ìkọ́lé méjì wéra: ọ̀kan ni wúrà, fàdákà, àti àwọn òkúta ṣíṣeyebíye; èkejì ni igi, koríko gbígbẹ, àti àgékù pòròpórò. Ẹnì kan lè fi àwọn ohun èlò dáradára, tí ó lè wà fún ìgbà pípẹ́, tí kò sì ní gbiná kọ́lé; ẹnì kan sì lè kánjú fi àwọn ohun èlò tí kò ní pẹ́ bà jẹ́, tí ó wà fún ìgbà díẹ̀, tí ó sì lè tètè gbiná kọ́lé. Ó dájú pé irú ọ̀nà ìkọ́lé méjèèjì ló wà ní ìlú Kọ́ríńtì. Àwọn tẹ́ńpìlì ràgàjì tí a fi búlọ́ọ̀kù olókùúta ńláńlá, tí ó tún jẹ́ olówó gọbọi kọ́, tí ó sì ṣeé ṣe kí a fi wúrà àti fàdákà bò tàbí kí a fi ṣe apá kan rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ wà níbẹ̀.b Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ẹ̀gbẹ́ àwọn ilé kéékèèké, ilé gẹ̀rẹ̀jẹ̀, àwọn káńtà ìtajà tí a fi igi ṣágiṣàgi kọ́, tí a sì fi koríko bò, ni àwọn ilé ńlá tí ó lè wà fún ìgbà pípẹ́ yìí wà.

  • Ṣé Iṣẹ́ Rẹ Yóò La Iná Já?
    Ilé Ìṣọ́—1998 | November 1
    • 12. Ọ̀nà wo ni àwọn kan nínú àwọn Kristẹni tí ó wà ní Kọ́ríńtì fi ń fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú iṣẹ́ ilé kíkọ́ náà?

      12 Ó ṣe kedere pé, Pọ́ọ̀lù nímọ̀lára pé àwọn Kristẹni kan ní Kọ́ríńtì ń fi ohun èlò tí kò dára kọ́lé. Kí ló fà á? Gẹ́gẹ́ bí àyíká ọ̀rọ̀ náà ti fi hàn, ìyapa wà nínú ìjọ, ìyẹn ni dídarí àfiyèsí sórí àwọn ènìyàn láìfi ewu tí ó lè ní lórí ìṣọ̀kan ìjọ pè. Àwọn kan ń wí pé, “Èmi jẹ́ ti Pọ́ọ̀lù,” nígbà tí àwọn mìíràn sì ń rin kinkin mọ́ ọn pé, “Èmi [jẹ́] ti Àpólò.” Ó dà bí pé ọgbọ́n àwọn kan jọ wọ́n lójú ju bí ó ti yẹ lọ. Kò yani lẹ́nu láti rí i pé ó yọrí sí ìrònú ti ẹran ara, àìdàgbàdénú nípa tẹ̀mí, pẹ̀lú “owú àti gbọ́nmisi-omi-ò-to.” (1 Kọ́ríńtì 1:12; 3:1-4, 18) Ìwà wọ̀nyí hàn gbangba nínú ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi kọ́ni nínú ìjọ àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé wọ́n fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, ó wá dà bí fífi àwọn ohun èlò gbàrọgùdù kọ́lé. Kò lè la “iná” já. Irú iná wo ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ bá?

  • Ṣé Iṣẹ́ Rẹ Yóò La Iná Já?
    Ilé Ìṣọ́—1998 | November 1
    • 14. (a) Báwo ni àwọn Kristẹni tí ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn ṣe lè “pàdánù,” síbẹ̀, báwo ni a ṣe lè gbà wọ́n là bí ẹni la iná já? (b) Báwo ni a ṣe lè dín ewu pípàdánù kù?

      14 Ọ̀rọ̀ tí ó gbàrònú jinlẹ̀ nìyí lóòótọ́! Ó máa ń dunni púpọ̀ láti sapá gidigidi láti ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn, kìkì láti wá rí i pé ó juwọ́ sílẹ̀ fún ìdánwò tàbí inúnibíni, tí ó sì wá fi ọ̀nà òtítọ́ sílẹ̀ níkẹyìn. Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú gbà bẹ́ẹ̀ nígbà tí ó fi sọ pé a pàdánù nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Ìrírí náà máa ń dunni gan-an débi tí a fi ṣàpèjúwe ìgbàlà wa gẹ́gẹ́ bí “ẹni la iná já”—bí ẹnì kan tí ó pàdánù gbogbo ohun tí ó ní nínú iná, tí ó jẹ́ pé díẹ̀ báyìí ni òun alára fi rù ú là. Ní tiwa, báwo ni a ṣe lè dín ewu pípàdánù kù? Ẹ jẹ́ kí a fi ohun èlò tí ó lè wà pẹ́ títí kọ́lé! Bí a bá kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ láti lè dé inú ọkàn-àyà wọn, tí a sún wọn láti mọyì àwọn ànímọ́ Kristẹni ṣíṣeyebíye bí ọgbọ́n, ìfòyemọ̀, ìbẹ̀rù Jèhófà, àti ojúlówó ìgbàgbọ́, a jẹ́ pé a ń fi ohun èlò tí ó lè wà pẹ́ títí, tí kò lè gbiná kọ́lé. (Sáàmù 19:9, 10; Òwe 3:13-15; 1 Pétérù 1:6, 7) Àwọn tí wọ́n bá ní irú àwọn ànímọ́ wọ̀nyí yóò máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nìṣó; wọ́n ní ìrètí tí ó dájú láti wà láàyè títí láé. (1 Jòhánù 2:17) Ṣùgbọ́n, báwo ni a ṣe lè fi àkàwé Pọ́ọ̀lù sílò? Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

      15. Àwọn ọ̀nà wo ni a lè gbà rí i dájú pé a yẹra fún fífọwọ́ dẹngbẹrẹ mú iṣẹ́ ìkọ́lé tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa?

      15 Nígbà tí a bá ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a kò gbọ́dọ̀ gbé ènìyàn ga ju Jèhófà Ọlọ́run lọ. Góńgó wa kì í ṣe láti kọ́ wọn láti máa wò wá gẹ́gẹ́ bí orísun ìpìlẹ̀ ọgbọ́n. A fẹ́ kí wọ́n máa yíjú sí Jèhófà, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti ètò àjọ rẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà. Láti ṣe èyí, a kò ní wulẹ̀ máa gbé èrò tiwa kalẹ̀ láti dáhùn ìbéèrè wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, a óò kọ́ wọn láti wá ìdáhùn náà, nípa lílo Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti pèsè. (Mátíù 24:45-47) Fún ìdí kan náà, a óò ṣọ́ra, kí a má ra kaka lé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lórí. Dípò tí a kò fi ní fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn fi ọkàn-ìfẹ́ hàn sí wọn, ó yẹ kí a fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa níṣìírí láti “gbòòrò síwájú” nínú ìfẹ́ni wọn, kí wọ́n túbọ̀ dojúlùmọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ sí i nínú ìjọ, kí wọ́n sì mọyì wọn, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó.—2 Kọ́ríńtì 6:12, 13.

      16. Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè lo àwọn ohun èlò tí kò lè gbiná?

      16 Àwọn Kristẹni alàgbà pẹ̀lú ń kó ipa pàtàkì nínú sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ni nínú ìjọ, wọ́n ń wọ́nà àtilo àwọn ohun èlò tí kò lè gbiná. Agbára ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wọn, ìrírí wọn, àti irú ẹni tí wọ́n jẹ́ lè yàtọ̀ síra púpọ̀púpọ̀, ṣùgbọ́n wọn kì í lo àwọn ìyàtọ̀ wọ̀nyí láti fa ọmọ ẹ̀yìn sẹ́yìn ara wọn. (Fi wé Ìṣe 20:29, 30.) A kò mọ ìdí náà gan-an tí àwọn kan ní Kọ́ríńtì fi ń sọ pé: “Èmi jẹ́ ti Pọ́ọ̀lù” tàbí, “Èmi ni ti Àpólò.” Ṣùgbọ́n ó dá wa lójú pé kò sí èyíkéyìí lára àwọn alàgbà olóòótọ́ wọ̀nyí tí ó gbé èrò ìyapa yìí lárugẹ. Irú èrò bẹ́ẹ̀ kò wú Pọ́ọ̀lù lórí; ó ta kò wọ́n pátápátá. (1 Kọ́ríńtì 3:5-7) Bákan náà lónìí, àwọn alàgbà ń fi í sọ́kàn pé àwọn ń ṣolùṣọ́ àgùntàn “agbo Ọlọ́run.” (1 Pétérù 5:2) Agbo àgùntàn kì í ṣe ti ènìyàn kankan. Nítorí náà, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ dúró gbọn-in láìfàyè gba ìtẹ̀sí náà pé kí ọkùnrin kan fẹ́ jẹ gàba lórí agbo tàbí lórí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà. Àwọn ohun èlò tí kò lè gbiná ni àwọn alàgbà fi ń kọ́lé nígbà tí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bá ń sún wọn láti sin ìjọ, láti dé inú ọkàn-àyà wọn, kí wọ́n sì ran àwọn àgùntàn lọ́wọ́ láti fi gbogbo ọkàn sin Jèhófà.

      17. Báwo ni àwọn Kristẹni òbí ṣe lè sapá láti lo àwọn ohun èlò tí kò lè gbiná?

      17 Ọ̀ràn yìí náà kan àwọn Kristẹni òbí gbọ̀ngbọ̀n. Ẹ wo bí wọ́n ti ṣe ń yán hànhàn tó pé kí àwọn ọmọ wọn wà láàyè títí láé! Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń sa gbogbo ipá wọn láti “gbin” ìlànà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “sínú” ọkàn-àyà àwọn ọmọ wọn. (Diutarónómì 6:6, 7) Wọ́n fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn mọ òtítọ́, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí àkójọ òfin tàbí kókó tí a tò jọ gìn-ìn-rìn, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó ní ìtumọ̀, tí ó mú èrè wá, tí ó sì láyọ̀. (1 Tímótì 1:11) Láti lè mú kí àwọn ọmọ wọn di olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi, àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ ń sakun láti lo àwọn ohun èlò tí kò lè gbiná. Wọ́n ń fi sùúrù bá àwọn ọmọ wọn ṣiṣẹ́, nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú àwọn ànímọ́ tí Jèhófà kórìíra kúrò nínú wọn, kí wọ́n sì gbin àwọn ànímọ́ tí ó nífẹ̀ẹ́ síbẹ̀.—Gálátíà 5:22, 23.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́