-
Ṣé Iṣẹ́ Rẹ Yóò La Iná Já?Ilé Ìṣọ́—1998 | November 1
-
-
9. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù gan-an ni ó fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀, àníyàn wo ni ó ní fún àwọn tí wọ́n tẹ́wọ́ gba òtítọ́ tí ó kọ́ wọn?
9 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Wàyí o, bí ẹnikẹ́ni bá ń kọ́ wúrà, fàdákà, àwọn òkúta ṣíṣeyebíye, àwọn ohun èlò igi, koríko gbígbẹ, àgékù pòròpórò sórí ìpìlẹ̀ náà, iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò fara hàn kedere, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí a óò ṣí i payá nípasẹ̀ iná; iná náà fúnra rẹ̀ yóò sì fi ẹ̀rí irú ohun tí iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan jẹ́ hàn.” (1 Kọ́ríńtì 3:12, 13) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn? Gbé ipò tí ó yí ọ̀rọ̀ náà ká yẹ̀ wò. Lákọ̀ọ́kọ́, Pọ́ọ̀lù jẹ́ ẹni tí ń fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀. Nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀, ó rìnrìn àjò láti ìlú dé ìlú, ó sì wàásù fún ọ̀pọ̀ àwọn tí kò gbọ́ nípa Kristi rí. (Róòmù 15:20) Bí àwọn ènìyàn ti ń tẹ́wọ́ gba òtítọ́ tí ó fi kọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó ń dá ìjọ sílẹ̀. Pọ́ọ̀lù bìkítà púpọ̀ nípa àwọn olóòótọ́ wọ̀nyí. (2 Kọ́ríńtì 11:28, 29) Ṣùgbọ́n, iṣẹ́ rẹ̀ kò jẹ́ kí ó lè dúró sójú kan. Nítorí náà, lẹ́yìn tí ó ti lo oṣù 18 ní fífi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ ní Kọ́ríńtì, ó kọjá sí àwọn ìlú mìíràn láti lọ wàásù níbẹ̀. Síbẹ̀, ó ṣì fẹ́ mọ bí àwọn yòókù ṣe ń bójú tó iṣẹ́ tí òun ti ṣe sílẹ̀ níbẹ̀.—Ìṣe 18:8-11; 1 Kọ́ríńtì 3:6.
-
-
Ṣé Iṣẹ́ Rẹ Yóò La Iná Já?Ilé Ìṣọ́—1998 | November 1
-
-
11 Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ilé wọ̀nyí bí iná bá ràn mọ́ wọn? Bí ìdáhùn náà ti ṣe kedere ní ọjọ́ Pọ́ọ̀lù, bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣe kedere lónìí. Ní tòótọ́, láti ọdún 146 ṣááju Sànmánì Tiwa ni Ọ̀gágun Mummius láti Róòmù, ti ṣẹ́gun ìlú Kọ́ríńtì, tí ó sì ti finá sun ún. Ọ̀pọ̀ ilé tí a fi igi, àgékù koríko, tàbí ti pòròpórò kọ́ ni a ti run pátápátá. Àmọ́ àwọn ilé dídúró gbọn-in tí a fi òkúta kọ́, tí a sì fi fàdákà àti wúrà ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ ńkọ́? Kò sí iyèméjì pé, ìwọ̀nyí kò run. Ó ṣeé ṣe kí àwọn tí Pọ́ọ̀lù kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ní Kọ́ríńtì ti máa kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ irú àwọn ilé bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́—àwọn ilé olókùúta tí kò run nígbà jàǹbá tí wọ́n sì ti sọ àwọn ilé yẹpẹrẹ tí ó wà nítòsí wọn di ilẹ̀. Ẹ wo bí Pọ́ọ̀lù ṣe mú kí kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe kedere tó! Nígbà tí a bá ń kọ́ni, ó yẹ kí a ka ara wa sí kọ́lékọ́lé. Kí a lo àwọn ohun èlò tí ó lè wà pẹ́ títí jù lọ. Nípa bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ wa fi lè wà fún ìgbà pípẹ́. Kí ni àwọn ohun tí ó lè wà pẹ́ títí, èé sì ti ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti lò wọ́n?
-
-
Ṣé Iṣẹ́ Rẹ Yóò La Iná Já?Ilé Ìṣọ́—1998 | November 1
-
-
12. Ọ̀nà wo ni àwọn kan nínú àwọn Kristẹni tí ó wà ní Kọ́ríńtì fi ń fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú iṣẹ́ ilé kíkọ́ náà?
12 Ó ṣe kedere pé, Pọ́ọ̀lù nímọ̀lára pé àwọn Kristẹni kan ní Kọ́ríńtì ń fi ohun èlò tí kò dára kọ́lé. Kí ló fà á? Gẹ́gẹ́ bí àyíká ọ̀rọ̀ náà ti fi hàn, ìyapa wà nínú ìjọ, ìyẹn ni dídarí àfiyèsí sórí àwọn ènìyàn láìfi ewu tí ó lè ní lórí ìṣọ̀kan ìjọ pè. Àwọn kan ń wí pé, “Èmi jẹ́ ti Pọ́ọ̀lù,” nígbà tí àwọn mìíràn sì ń rin kinkin mọ́ ọn pé, “Èmi [jẹ́] ti Àpólò.” Ó dà bí pé ọgbọ́n àwọn kan jọ wọ́n lójú ju bí ó ti yẹ lọ. Kò yani lẹ́nu láti rí i pé ó yọrí sí ìrònú ti ẹran ara, àìdàgbàdénú nípa tẹ̀mí, pẹ̀lú “owú àti gbọ́nmisi-omi-ò-to.” (1 Kọ́ríńtì 1:12; 3:1-4, 18) Ìwà wọ̀nyí hàn gbangba nínú ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi kọ́ni nínú ìjọ àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé wọ́n fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, ó wá dà bí fífi àwọn ohun èlò gbàrọgùdù kọ́lé. Kò lè la “iná” já. Irú iná wo ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ bá?
13. Kí ni iná tí Pọ́ọ̀lù lò nínú àkàwé rẹ̀ túmọ̀ sí, kí sì ni ó yẹ kí gbogbo Kristẹni mọ̀?
13 Iná kan wà tí gbogbo wa dojú kọ nínú ìgbésí ayé—ìdánwò ìgbàgbọ́ wa. (Jòhánù 15:20; Jákọ́bù 1:2, 3) Bí ti àwa pẹ̀lú lónìí, ó yẹ kí àwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì mọ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí a bá kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ni a óò dán wò. Bí a kò bá kọ́ wọn dáradára, àbájáde rẹ̀ lè bani nínú jẹ́. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó ti kọ́ sórí rẹ̀ bá wà síbẹ̀, òun yóò gba èrè; bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, òun yóò pàdánù, ṣùgbọ́n òun fúnra rẹ̀ ni a ó gbà là; síbẹ̀, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, yóò jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹní la iná já.”c—1 Kọ́ríńtì 3:14, 15.
-