-
Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Tó Lọ́kọ Tàbí Aya Àtàwọn Tí Kò NíGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
5. Fara balẹ̀ yan ẹni tó o máa fẹ́
Ọ̀kan lára àwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù lọ tó o máa ṣe láyé ẹ ni pé kó o yan ẹni tó o máa fẹ́. Ka Mátíù 19:4-6, 9, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tó fi yẹ kí Kristẹni kan ṣe sùúrù kó tó ṣègbéyàwó?
Bíbélì á jẹ́ kó o mọ àwọn ìwà àti ìṣe tó yẹ kó o máa wá lára ẹni tó o máa fi ṣe ọkọ tàbí aya. Èyí tó sì ṣe pàtàkì jù lára àwọn nǹkan yẹn ni pé kí ẹni náà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.b Ka 1 Kọ́ríńtì 7:39 àti 2 Kọ́ríńtì 6:14. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tó fi yẹ kí Kristẹni kan fẹ́ Kristẹni bíi tiẹ̀?
Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Jèhófà tí Kristẹni kan bá fẹ́ ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
Tí wọ́n bá fi àjàgà so ẹranko kan tó tóbi tó sì lágbára mọ́ ẹranko kékeré tí ò lágbára, nǹkan máa nira fáwọn méjèèjì. Bákan náà, tí Kristẹni kan bá fẹ́ aláìgbàgbọ́, ó máa ní ìṣòro tó pọ̀ gan-an
-