ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ṣíṣàjọpín Ìtùnú Tí Jèhófà Ń Pèsè
    Ilé-Ìṣọ́nà—1996 | November 1
    • “Ìrètí wa fún yín dúró láìmì, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ ní tòótọ́ pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti jẹ́ alájọpín àwọn ìjìyà náà, ní ọ̀nà kan náà ni ẹ̀yin yóò ṣàjọpín ìtùnú pẹ̀lú.”—KỌ́RÍŃTÌ KEJÌ 1:7.

  • Ṣíṣàjọpín Ìtùnú Tí Jèhófà Ń Pèsè
    Ilé-Ìṣọ́nà—1996 | November 1
    • 4. Ní àwọn ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wo ni àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fi ìfẹ́ hàn fi lè hùwà padà sí ìpọ́njú?

      4 Ó bani nínú jẹ́ pé, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀, ìpọ́njú ń mú kí àwọn kan kọsẹ̀, kí wọ́n sì dá ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ wọn pẹ̀lú ìjọ Kristẹni dúró. (Mátíù 13:5, 6, 20, 21) Àwọn mìíràn fara da ìpọ́njú nípa pípa ọkàn wọn pọ̀ sórí àwọn ìlérí tí ń tuni nínú tí wọ́n ń kọ́. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n sì ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Ọmọkùnrin rẹ̀, Jésù Kristi. (Mátíù 28:19, 20; Máàkù 8:34) Àmọ́ ṣáá o, ìpọ́njú kì í dáwọ́ dúró nígbà tí Kristẹni kan bá ṣe batisí. Fún àpẹẹrẹ, wíwà láìlábàwọ́n lè jẹ́ ìjàkadì líle koko fún ẹnì kan tí ó ti ń gbé ìgbésí ayé oníwà pálapàla látilẹ̀wá. Àwọn mìíràn ní láti dojú kọ àtakò àtìgbàdégbà láti ọ̀dọ̀ àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí kò gbà gbọ́. Ohun yòó wù kí ìpọ́njú náà jẹ́, gbogbo àwọn tí wọ́n bá fi ìṣòtítọ́ lépa ìgbésí ayé oníyàsímímọ́ sí Ọlọ́run lè ní ìdánilójú ohun kan. Ní ọ̀nà kan tí ó jẹ́ tí ara ẹni gan-an, wọn yóò rí ìtùnú àti ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run gbà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́