-
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn ÒǹkàwéIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018 | December
-
-
“Párádísè” wo ni Pọ́ọ̀lù sọ pé òun rí?
Ọ̀rọ̀ náà “Párádísè” ní ìtúmọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀: (1) Ó lè tọ́ka sí ìgbà tí ayé wa yìí máa di Párádísè bíi ti ọgbà Édẹ́nì. (2) Ó lè túmọ̀ sí Párádísè tẹ̀mí táwa èèyàn Ọlọ́run máa gbádùn nínú ayé tuntun. (3) Bákan náà, ó lè túmọ̀ sí àwọn àǹfààní àgbàyanu tó wà lọ́run, ìyẹn “párádísè Ọlọ́run” bó ṣe wà nínú Ìṣípayá 2:7.—Wo Ilé Ìṣọ́, July 15, 2015, ojú ìwé 8, ìpínrọ̀ 8.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìtumọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ni ìran tí Pọ́ọ̀lù rí ń tọ́ka sí, bó ṣe ròyìn rẹ̀ nínú 2 Kọ́ríńtì 12:4.
-
-
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn ÒǹkàwéIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018 | December
-
-
“Párádísè” tí Pọ́ọ̀lù rí nínú ìran náà ṣeé ṣe kó jẹ́ (1) Párádísè tá à ń retí lórí ilẹ̀ ayé, (2) Párádísè tẹ̀mí tá a máa gbádùn nígbà yẹn, èyí táá gbòòrò ju Párádísè tẹ̀mí tá à ń gbádùn báyìí lọ àti (3) “párádísè Ọlọ́run” tó wà lọ́run lásìkò kan náà pẹ̀lú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.
-