ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Ọlọ́run Ìtùnú Gbogbo”
    Ilé Ìṣọ́—2008 | September 1
    • Ọ̀PỌ̀ nǹkan ló lè fa ìbànújẹ́, kó sì mú kéèyàn sọ̀rètí nù nígbèésí ayé. Lára wọn ni ìyà, ìjákulẹ̀, ìdánìkanwà. Nígbà tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí wa, a lè béèrè pé, ‘Ta ló máa ràn mí lọ́wọ́ báyìí?’ Ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tá a rí nínú 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4 jẹ́ ká mọ ibi tá a ti lè rí ìtùnú tí kò lè jáni kulẹ̀, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run.

      Ní ẹsẹ kẹta, ó pe Ọlọ́run ní “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́.” Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Èrò tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” lè gbé síni lọ́kàn ni ìyọ́nú téèyàn ń ní sáwọn èèyàn nítorí ìyà tó ń jẹ wọ́n.a Ìwé kan tá a ṣèwádìí ọ̀rọ̀ Bíbélì nínú rẹ̀ sọ pé a lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ yẹn sí “àánú tó ń ṣeni” tàbí “bí ọ̀rọ̀ ṣe ń káni lára.” “Àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” Ọlọ́run ń mú kó gbégbèésẹ̀ lórí ọ̀ràn kan. Mímọ̀ tá a mọ ànímọ́ Ọlọ́run yìí ń fà wá sún mọ́ ọn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

      Pọ́ọ̀lù tún sọ pé Jèhófà ni “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò níbí yìí nasẹ̀ dórí “títu ẹnì kan tó wà nínú ìdààmú tàbí ìbànújẹ́ nínú, ó tún ní èrò ṣíṣe ohun tó máa fún ẹni náà níṣìírí.” Bíbélì The Interpreter’s Bible ṣàlàyé pé: “À ń tu ẹni tíyà ń jẹ nínú nígbà tá a bá fún un nígboyà tó máa mú kó lè fara da ìrora rẹ̀.”

      O lè wá béèrè pé: ‘Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń tù wá nínú tó sì ń fún wa ní ìgboyà láti fara da ìrora wa?’ Ohun pàtàkì tó ń lò ni Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti àǹfààní tá a ní láti gbàdúrà. Pọ́ọ̀lù sọ fún wa pé Ọlọ́run fi ìfẹ́ fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀ “pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” Yàtọ̀ síyẹn, nípasẹ̀ àdúrà àtọkànwá, a lè ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.”—Róòmù 15:4; Fílípì 4:7.

  • “Ọlọ́run Ìtùnú Gbogbo”
    Ilé Ìṣọ́—2008 | September 1
    • a Pọ́ọ̀lù pe Ọlọ́run ní “Baba [tàbí orísun] àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àánú ti wá, ó sì jẹ́ ara ànímọ́ Ọlọ́run.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́