ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 5/15 ojú ìwé 21-23
  • “Ìgba Dídákẹ́, àti Ìgba Fífọhùn”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ìgba Dídákẹ́, àti Ìgba Fífọhùn”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọ̀nà Láti Gbà Rọ Ahọ́n Lójú
  • Ṣíṣàkóso Ahọ́n Wa Nígbà Tí A Bá Ń Bínú
  • Ìgbà Tí Dídákẹ́ Kì Í Ṣe Ojútùú
  • “Ìgba Fífọhùn” Nípa Ìjọba Ọlọrun
  • Máa Fi Ahọ́n Rẹ Sọ̀rọ̀ Tó Ń Gbéni Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Kí Ló Dé Tó Jẹ́ Ọ̀rọ̀ Tí Ò Dáa Ló Máa Ń Jáde Lẹ́nu Mi Ṣáá?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ẹ Máa Fi Ìfẹ́ Àti Ọ̀wọ̀ Hàn Fún Ara Yín Nípa Kíkó Ahọ́n Yín Níjàánu
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ọ̀rọ̀ Tútù Máa Ń mú Kí Àjọṣe Wa Pẹ̀lú Àwọn Míì Sunwọ̀n Sí I
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 5/15 ojú ìwé 21-23

“Ìgba Dídákẹ́, àti Ìgba Fífọhùn”

ÌGBÀ mélòó ni o ti kédàárò pé, “Ká ní mo mọ̀ ni, ǹ bá má ti sọ bẹ́ẹ̀”? Síbẹ̀, o lè rántí àwọn àkókò míràn tí o kò fọhùn. Ní ríronú lórí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, o lè ronú pé, ‘Ká ní mo mọ̀ ni, ǹ bá tí sọ̀rọ̀.’

Bibeli sọ pé “ìgba dídákẹ́, àti ìgba fífọhùn” ń bẹ. (Oniwasu 3:7) Nítorí náà, níhìn-ín ni ìṣòro náà wà—láti pinnu ìgba fífọhùn àti ìgba dídákẹ́. Àbùdá ẹ̀dá ènìyàn aláìpé wa máa ń sún wa nígbà gbogbo láti ṣe ohun kan tàbí sọ̀rọ̀ ní àkókò tí kò tọ́. (Romu 7:19) Báwo ni a ṣe lè ṣàkóso ahọ́n wa tí ó ṣòro láti darí?—Jakọbu 3:2.

Àwọn Ọ̀nà Láti Gbà Rọ Ahọ́n Lójú

Láti ràn wá lọ́wọ́ láti pinnu ìgba fífọhùn àti ìgba dídákẹ́, a kò nílò àkọsílẹ̀ jàn-ànràn jan-anran tí a wéwèé láti ní gbogbo ipò tí ó bá ṣeé ṣe nínú. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ní láti jẹ́ kí àwọn ànímọ́ apá pàtàkì àkópọ̀ ìwà Kristian ṣamọ̀nà wa. Kí ni àwọn ànímọ́ wọ̀nyí?

Jesu Kristi ṣàlàyé pé, ìfẹ́ ni olórí ànímọ́ tí ń sún àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ṣiṣẹ́. Ó wí pé: “Nipa èyí ni gbogbo ènìyàn yoo fi mọ̀ pé ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Johannu 13:35) Bí a bá ṣe ń fi irú ìfẹ́ ará bẹ́ẹ̀ hàn tó, ni a óò lè máa ṣàkóso ahọ́n wa tó.

Àwọn ànímọ́ méjì tí wọ́n ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ara wọn yóò tún ràn wá lọ́wọ́ gidigidi. Ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí ni ìrẹ̀lẹ̀. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti ‘máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù wá lọ.’ (Filippi 2:3) Òmíràn ni ìwà tútù, tí ń mú kí a lè ‘ko ara wa ní ìjánu lábẹ́ ibi.’ (2 Timoteu 2:24, 25) Jesu Kristi jẹ́ àpẹẹrẹ pípé fún wa nípa bí a ṣe lè lo àwọn ànímọ́ wọ̀nyí.

Níwọ̀n bí ó ti túbọ̀ máa ń ṣòro láti ṣàkóso ahọ́n wa nígbà tí a bá wà lábẹ́ pákáǹleke, ẹ jẹ́ kí a gbé òru tí ó ṣáájú ikú Jesu yẹ̀ wò—àkókò kan tí ó “dààmú gidigidi.” (Matteu 26:37, 38) Kò yani lẹ́nu pé, Jesu nímọ̀lára lọ́nà yìí, níwọ̀n bí ayérayé ọjọ́ ọ̀la fún gbogbo aráyé ti sinmi lórí dídúró rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ sí Ọlọrun.—Romu 5:19-21.

Dájúdájú, àkókò kan nìyí fún Jesu láti bá Bàbá rẹ̀ ọ̀run sọ̀rọ̀. Nítorí náà, ó lọ gbàdúrà, ó sì sọ fún àwọn mẹ́ta nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa ṣọ́nà. Nígbà tí ó ṣe díẹ̀, ó wá, ó sì rí wọn tí wọ́n ń sùn. Nígbà náà ni ó sọ fún Peteru pé: “Ṣé ẹ̀yin kò tilẹ̀ lè ṣọ́nà pẹlu mi fún wákàtí kan péré ni?” Ìbáwí onífẹ̀ẹ́ yìí wá pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tí ó fi hàn pé ó lóye àìlera wọn. Ó wí pé: “Nítòótọ́, ẹ̀mí ń háragàgà, ṣugbọn ẹran-ara ṣe aláìlera.” Lẹ́yìn náà, Jesu tún padà wá, ó sì rí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n ń sùn. Ó fi inú rere bá wọn sọ̀rọ̀, “ó . . . lọ ó sì gbàdúrà ní ìgbà kẹta.”—Matteu 26:36-44.

Nígbà tí Jesu rí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n ń sùn nígbà kẹta, kò kanra mọ́ wọn, ṣùgbọ́n ó wí pé: “Ní irúfẹ́ àkókò yii ẹ̀yin ń sùn ẹ sì ń sinmi! Wò ó! Wákàtí naa ti súnmọ́lé tí a óò fi Ọmọkùnrin ènìyàn lé ọwọ́ awọn ẹlẹ́ṣẹ̀.” (Matteu 26:45) Kìkì ẹni tí ó ní ọkàn-àyà onífẹ̀ẹ́, pẹ̀lú ojúlówó ọkàn tútù àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, ni ó lè lo ahọ́n ní ọ̀nà yẹn ní irú àkókò oníhílàhílo bẹ́ẹ̀.—Matteu 11:29; Johannu 13:1.

Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn náà, a fàṣẹ ọba mú Jesu, a sì gbẹ́jọ́ rẹ̀. A kẹ́kọ̀ọ́ níhìn-ín pé, nígbà míràn ó dára jù lọ kí a má fọhùn, àní nígbà tí a bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian pàápàá. Pẹ̀lú èrò láti yí ẹ̀sùn mọ́ Jesu lẹ́sẹ̀, olórí àlùfáà kò ní ìfẹ́ ọkàn kankan nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, bí ó ti wù kí ó mọ. Nítorí náà, nínú àyíká ipò tí ó lè yọrí sí ìwà ipá yìí, Jesu kò fọhùn.—Fi wé Matteu 7:6.

Ṣùgbọ́n, Jesu kò ṣàìfọhùn nígbà tí àlùfáà àgbà náà béèrè pé: “Mo fi Ọlọrun alààyè fi ọ́ sábẹ́ ìbúra lati sọ fún wa yálà iwọ ni Kristi Ọmọkùnrin Ọlọrun!” (Matteu 26:63) Níwọ̀n bí a ti fi Jesu sábẹ́ ìbúra, àkókò ti tó fún un láti fọhùn. Nítorí náà, ó fèsì pé: “Iwọ fúnra rẹ wí i. Síbẹ̀ mo wí fún yín pé, Lati ìsinsìnyí lọ ẹ̀yin yoo rí Ọmọkùnrin ènìyàn tí yoo jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára tí yoo sì máa bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run.”—Matteu 26:64.

Ní ọjọ́ mánigbàgbé yẹn, Jesu lo àkóso pípé lórí ahọ́n rẹ̀. Nínú ọ̀ràn rẹ̀, ìfẹ́, inú tútù, àti ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ àwọn apá àbùdá àkópọ̀ ìwà rẹ̀. Báwo ni a ṣe lè lo àwọn ànímọ́ wọ̀nyí láti ṣàkóso ahọ́n wa nígbà tí a bá wà lábẹ́ pákáǹleke?

Ṣíṣàkóso Ahọ́n Wa Nígbà Tí A Bá Ń Bínú

Nígbà tí a bá ń bínú, a kì í sábà lè ṣàkóso ahọ́n wa mọ́. Fún àpẹẹrẹ, Paulu àti Barnaba ní èrò tí ó yàtọ̀ nígbà kan. “Barnaba pilẹ̀pinnu lati mú Johannu pẹlu dání, ẹni tí a ń pè ní Marku. Ṣugbọn Paulu kò ronú pé ó bẹ́tọ̀ọ́mu lati mú ẹni yii dání pẹlu wọn, nitori pé ó fi wọ́n sílẹ̀ lati Pamfilia kò sì bá wọn lọ sẹ́nu iṣẹ́. Látàrí èyí ìbújáde ìbínú mímúná ṣẹlẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n pínyà kúrò lọ́dọ̀ ara wọn lẹ́nìkínní kejì.”—Ìṣe 15:37-39.

Michael,a tí ó ti ṣiṣẹ́ ní ibi iṣẹ́ ìkọ́lé fún ọdún mélòó kan, sọ pé: “Ẹnì kan wà níbi ilẹ̀ ìkọ́lé náà tí mo mọ̀ dáradára, tí mo sì bọ̀wọ̀ fún. Ṣùgbọ́n ó dà bíi pé ó máa ń ṣe lámèyítọ́ iṣẹ́ mi nígbà gbogbo. Ó bí mi nínú, ó sì ru ìbínú mi sókè, ṣùgbọ́n mo pa á mọ́ra. Ní ọjọ́ kan, ọ̀rọ̀ náà dójú rẹ̀, nígbà tí ó ṣe lámèyítọ́ iṣẹ́ kan tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe.

“Mo sọ gbogbo ìmọ̀lára tí mo ti ń pa mọ́ra jáde. Nítorí inú tí ó bí mi, n kò kọ èrò búburú tí èyí lè mú wa sọ́kàn gbogbo àwọn tí ó wà láyìíká wa. Ní ìyókù ọjọ́ náà, n kò fẹ́ bá a sọ̀rọ̀ tàbí kí n tilẹ̀ fojú kàn án. Mo wá mọ̀ nísinsìnyí pé, n kò yanjú ìṣòrò náà lọ́nà yíyẹ. Ì bá ti sàn jù láti dákẹ́, kí n sì sọ̀rọ̀ nígbà tí ìbínú mí bá ti rọlẹ̀.”

Ó múni láyọ̀ pé, ìfẹ́ Kristian sún àwọn ẹnì méjì wọ̀nyí láti yanjú aáwọ̀ wọn. Michael ṣàlàyé pé: “Lẹ́yìn ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ aláìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, a túbọ̀ lóye ara wa sí i, a sì ní ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tí ó lágbára nísinsìnyí.”

Gẹ́gẹ́ bí Michael ṣe kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, bí a bá ń bínú, ó bọ́gbọ́n mu nígbà míràn láti má ṣe fọhùn. Owe 17:27 (NW) sọ pé: “Ẹni olùfòyemọ̀ . . . jẹ́ ẹlẹ́mìí tútù.” Ìfòyemọ̀ àti ìfẹ́ ará yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàkóso ìháragàgà wa láti sọ àwọn ohun tí ó lè fa ìbínú jáde. Bí a bá ṣẹ̀ wá, ẹ jẹ́ kí a bá ẹnì kejì náà sọ̀rọ̀ ní òun nìkan ṣoṣo pẹ̀lú ìwà tútù àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, pẹ̀lú èrò mímú àlàáfíà padà wá. Bí a bá ti tutọ́ sókè, tí a sì ti fojú gbà á ńkọ́? Nígbà náà, ìfẹ́ yóò sún wa láti ki ọwọ́ ìgbéraga wa bọlẹ̀, kí a sì fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ wá ọ̀nà láti ṣàtúnṣe. Àkókò láti fọhùn nìyí, láti sọ ìkábàámọ̀ wa jáde, kí a sì wo ọgbẹ́ tí ìbínú ti fà sàn nípa ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ olóòótọ́-ọkàn.—Matteu 5:23, 24.

Ìgbà Tí Dídákẹ́ Kì Í Ṣe Ojútùú

Ìbínú tàbí ìrunú lè mú kí a máa bá ẹni náà tí ó mú wa bínú yodì. Èyí lè bá nǹkan jẹ́. Maríab jẹ́wọ́ pé: “Ní ọdún àkọ́kọ́ ìgbéyàwó wa, àwọn àkókò kan wà tí èmi máa ń bá ọkọ mi yodì fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í ṣe nítorí àwọn ìṣòro ńlá ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, nítorí àwọn ìrunú kéékèèké tí ó kóra jọ. Mo ń ronú lórí gbogbo àwọn ìbínú wọ̀nyí títí wọ́n fi di ìṣòro tí ó dà bí òkè. Lẹ́yìn náà ni àkókò náà dé nígbà tí n kò lè fara dà á mọ́, mo sì bá ọkọ mí yodì títí ìbínú náà fi tán.”

María fi kún un pé: “Ẹsẹ Bibeli kan pàtó—‘má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá ọ nínú ipò ìtánnísùúrù’—ràn mí lọ́wọ́ láti tún èrò mi ṣe. Èmi àti ọkọ mi ṣiṣẹ́ kára láti lè mú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ sunwọ̀n sí i, kí ìṣòro má baà kóra jọ. Kò rọrùn rárá, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá ìgbésí ayé lọ́kọláya, mo láyọ̀ láti sọ pé àwọn sáà bíbáni yodì ti túbọ̀ ṣọ̀wọ́n. Bí ó ti wù kí ó rí, mo gbọ́dọ̀ gbà pé mo ṣì ń sapá láti lè ṣàkóso ìtẹ̀sí yìí.”—Efesu 4:26.

Bí María ṣe ṣàkíyèsí, nígbà tí gbún-úngbùn-ùngbún bá wà láàárín ènìyàn méjì, àìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ kì í ṣe ojútùú. Lábẹ́ àwọn àyíká ipò wọ̀nyẹn, kùnrùngbùn lè dàgbà, ipò ìbátan náà sì lè bà jẹ́. Jesu wí pé, a ní láti ‘máa yanjú àwọn ọ̀ràn ní kíákíá.’ (Matteu 5:25) “Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò rẹ̀” lè ràn wá lọ́wọ́ láti ‘máa lépa àlàáfíà.’—Owe 25:11; 1 Peteru 3:11.

A tún ní láti fọhùn nígbà tí a bá nílò ìrànlọ́wọ́. Bí a bá ń jìyà nítorí àwọn ìṣòro kan nípa tẹ̀mí, a lè lọ́ tìkọ̀ láti di ẹrù ìnira ru àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n bí a kò bá fọhùn, ìṣòro náà lè burú sí i. Àwọn alàgbà Kristian tí a yàn sípò lè bójú tó wa, bí a óò bá gbà kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, kò sí iyè méjì pé wọ́n ń hára gàgà láti ràn wá lọ́wọ́. Àkókò tí ó yẹ kí a fọhùn nìyí.—Jakọbu 5:13-16.

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó yẹ kí a bá Jehofa sọ̀rọ̀ déédéé nínú àdúrà àtọkànwá, gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ṣe. Ní tòótọ́, ẹ jẹ́ kí a ‘tú ọkàn wa jáde’ fún Bàbá wa ọ̀run.—Orin Dafidi 62:8; fi wé Heberu 5:7.

“Ìgba Fífọhùn” Nípa Ìjọba Ọlọrun

Iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian jẹ́ iṣẹ́ àṣẹ àtọ̀runwá kan tí a gbọ́dọ̀ ṣe parí ṣáájú kí òpin tó dé. Ju ti ìgbàkigbà rí lọ, ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé kí àwọn ìránṣẹ́ Jehofa polongo ìhìn rere Ìjọba náà. (Marku 13:10) Bí àwọn aposteli, àwọn Kristian tòótọ́ ‘kò lè’ wulẹ̀ ‘dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí wọ́n ti rí, tí wọ́n sì ti gbọ́.’—Ìṣe 4:20.

Àmọ́ ṣáá o, kì í ṣe ẹni gbogbo ní ń fẹ́ láti gbọ́ ìhìn rere náà. Ní tòótọ́, nígbà tí ó ń rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde láti wàásù, Jesu gbà wọ́n nímọ̀ràn láti ‘wá àwọn ẹni yíyẹ inú rẹ̀ kàn.’ Níwọ̀n bí Jehofa kò ti fipá mú ẹnì kankan láti jọ́sìn òun, a kì yóò máa bá a nìṣó ní fífipá bá ẹnì kan tí ó kọ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà délẹ̀délẹ̀ sọ̀rọ̀. (Matteu 10:11-14) Ṣùgbọ́n inú wá dùn láti sọ̀rọ̀ nípa ipò ọba Jehofa fún àwọn “tí wọ́n . . . ní ìtẹ̀sí ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.”—Ìṣe 13:48; Orin Dafidi 145:10-13.

Ìfẹ́, ìwà tútù, àti ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ àwọn ànímọ́ tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàkóso ìtẹ̀sí àìpé wa láti sọ̀rọ̀ láìní ìjánu tàbí kó sínú ọ̀fìn dídákẹ́ gbọ́nrin. Bí a ṣe ń dàgbà nínú àwọn ànímọ́ wọ̀nyí, a óò túbọ̀ mú wa gbara dì láti mọ àkókò tí ó tọ́ àti àkókò tí kò tọ́ láti fọhùn yàtọ̀.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kì í ṣe orúkọ rẹ̀ gan-an.

b Kì í ṣe orúkọ rẹ̀ gan-an.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

A lè yanjú àwọn ìṣòro nípasẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí ó gbámúṣé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́