Má Ṣe Di Kùnrùngbùn Sínú
YÍYẸRA fún dídi kùnrùngbùn sínú, nígbà tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá, lè dà bí ohun tí ó túbọ̀ peni níjà ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Bibeli ní ìmọ̀ràn tí ó ṣeé mú lò fún irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀. Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má sì ṣe ṣẹ̀; ẹ máṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín ninu ipò ìtánnísùúrù.”—Efesu 4:26.
Nígbà tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá, ó jẹ́ ìwà ẹ̀dá láti fi ìrunú hàn dé àyè kan. Sísọ tí Paulu sọ pé, “fi ìrunú hàn,” lè fi hàn pé ìbínú náà lè tọ́ nígbà míràn—bóyá ní ìhùwàpadà sí bíbáni lò lọ́nà àìtọ́ tàbí yíyí ìdájọ́ po. (Fi wé 2 Korinti 11:29.) Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá fi í sílẹ̀ láìyanjú rẹ̀, àní ìbínú tí ó tọ́ pàápàá lè ní àbáyọrí oníjàábá, tí ń yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀ ńláǹlà. (Genesisi 34:1-31; 49:5-7; Orin Dafidi 106:32, 33) Nítorí náà, kí ni o lè ṣe nígbà tí inú rẹ bá ru?
Nínú ọ̀pọ̀ ọ̀ràn tí ó ní ìrékọjá tí kò tó nǹkan nínú, o lè yanjú ọ̀ràn náà nínú ọkàn rẹ, “kí [o] sì dúró jẹ́ẹ́,” tàbí kí o tọ ẹni tí ó ṣẹ̀ ọ́ náà lọ, kí o sì jíròrò ọ̀ràn náà. (Orin Dafidi 4:4; Matteu 5:23, 24) Èyí ó wù kí ó jẹ́, ohun dídára jù lọ ni láti yanjú ọ̀rọ̀ náà kíákíá, kí kùnrùngbùn má baà lóyún, kí ó sì bí ìyọrísí bíbani nínú jẹ́.—Efesu 4:31.
Jehofa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wá fàlàlà, kódà àwọn tí àwa pàápàá nínú àìmọ̀kan wa lè má mọ̀ pé a dá. A kò ha lè dárí ìrékọjá kéékèèké ti àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa jì wọ́n bákan náà bí?—Kolosse 3:13; 1 Peteru 4:8.
Ó dùn mọ́ni pé, ní olówuuru, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà fún “dárí jì” túmọ̀ sí láti “jáwọ́.” Ìdáríjì kò béèrè pé kí a fojú kéré ìwà àìtọ́ tàbí kí a fàyè gbà á. Nígbà míràn, ó lè ní wíwulẹ̀ jáwọ́ nínú ọ̀ràn náà nínú, ní mímọ̀ pé dídi kùnrùngbùn sínú yóò wulẹ̀ dì kún ẹrù ìnira rẹ, yóò sì da ìṣọ̀kan ìjọ Kristian rú. Síwájú sí i, dídi kùnrùngbùn sínú lè kó bá ìlera rẹ!—Orin Dafidi 103:9.