ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ Máa Wáyè Gbọ́ Tàwọn Ọmọ
    Jí!—2005 | February 8
    • Bá A Ṣe Lè Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Láìmú Inú Bí Wọn

      Ọ̀mọ̀wé Robert Coles, ìlúmọ̀ọ́ká olùkọ́ àti olùṣèwádìí nípa àìsàn ọpọlọ, sọ nígbà kan pé: “Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ báwọn ọmọdé ṣe ń dàgbà ni wọ́n máa ń fẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́. Lérò tèmi, Ọlọ́run ló dá ìfẹ́ yìí mọ́ wọn, ìyẹn ni wọ́n fi máa ń fẹ́ kí wọ́n rẹ́ni tọ́ wọn sọ́nà.” Ta ni yóò wá fún àwọn ọmọ ní ìtọ́sọ́nà tó jẹ́ kòṣeémánìí yìí?

      Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú nínú Éfésù 6:4 pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí pé ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ ní pàtó pé ojúṣe baba ni pé kó kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì ní ìmọrírì tó jinlẹ̀ fún àwọn ìlànà Rẹ̀? Ní ẹsẹ kìíní nínú Éfésù orí 6, bàbá àti ìyá ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ‘kí àwọn ọmọ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí wọn.’a

      Àmọ́ ṣá o, bí baba ò bá sí níbẹ̀, a jẹ́ pé ọpọ́n sún kan ìyá nìyẹn láti ṣe ojúṣe gẹ́gẹ́ bí olórí. Ọ̀pọ̀ ìyá tó ń dá tọ́mọ, ti kẹ́sẹ járí nínú kíkọ́ àwọn ọmọ wọn nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà Ọlọ́run. Àmọ́, bí irú ìyá bẹ́ẹ̀ bá wà lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ, ọkọ ẹ̀ tó jẹ́ Kristẹni ló ní láti máa mú ipò iwájú. Ìyá sì gbọ́dọ̀ ṣe tán láti kọ́wọ́ ti ọkọ bó ṣe ń kọ́ àwọn ọmọ tó sì ń bá wọn wí.

      Báwo lo ṣe ń bá àwọn ọmọ rẹ wí, báwo lo sì ṣe ń kọ́ wọn láì ‘mú wọn bínú’? Kò sí idán kankan níbẹ̀, àgàgà níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kò sọ́mọ méjì tó rí bákan náà. Ṣùgbọ́n àwọn òbí gbọ́dọ̀ ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà bá àwọn ọmọ wí. Wọ́n gbọ́dọ̀ máa fìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ, kí wọ́n sì máa fọ̀wọ̀ wọn wọ̀ wọ́n ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ń bá wọn wí. Wẹ́kú ló sì ṣe pé Ìwé Mímọ́ tún sọ ọ́ nínú Kólósè 3:21 pé káwọn òbí má ṣe máa mú àwọn ọmọ bínú. Ohun tí ibẹ̀ tún sọ fún àwọn baba ni pé: “Ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má bàa soríkodò.”

      Àwọn òbí kan máa ń pariwo wọ́n sì tún máa ń lọgun lé àwọn ọmọ wọn lórí. Dájúdájú, èyí máa ń mú inú bí àwọn ọmọdé. Ṣùgbọ́n Bíbélì rọ̀ wá pé: “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Éfésù 4:31) Bíbélì tún sọ pé “kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn.”—2 Tímótì 2:24.

  • Ẹ Máa Wáyè Gbọ́ Tàwọn Ọmọ
    Jí!—2005 | February 8
    • a Níbí, ọ̀rọ̀ Gíríìkì, go·neuʹsin tó wá látara go·neusʹ, tó túmọ̀ sí “òbí” ni Pọ́ọ̀lù lò. Ṣùgbọ́n ní ẹsẹ kẹrin ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà pa·teʹres, tó túmọ̀ sí “àwọn bàbá” ló lò.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́