ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Jèhófà Kan Ṣoṣo” Ń kó Ìdílé Rẹ̀ Jọ
    Ilé Ìṣọ́—2012 | July 15
    • 7. Kí ló túmọ̀ sí láti máa “pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́”?

      7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi, Jèhófà ti polongo àwọn ẹni àmì òróró rẹ̀ ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ọmọ, tó sì ti polongo àwọn àgùntàn mìíràn ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ rẹ̀, èdèkòyédè á ṣì máa wáyé níwọ̀n ìgbà tí èyíkéyìí nínú wa bá ṣì ń gbé láyé nínú ètò àwọn nǹkan yìí. (Róòmù 5:9; Ják. 2:23) Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, Ọlọ́run kò ní gbà wá nímọ̀ràn nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ká máa ‘fara dà á fún ara wa lẹ́nì kìíní kejì.’ Ṣùgbọ́n kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè máa wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ará wa? A gbọ́dọ̀ ní “ìrẹ̀lẹ̀ pátápátá ti èrò inú àti ìwà tútù.” Láfikún sí ìyẹn, Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé ká máa fi taratara sakun “láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.” (Ka Éfésù 4:1-3.) Ká lè máa fi ìmọ̀ràn yìí sílò, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa ká sì máa fi àwọn ànímọ́ rẹ̀ ṣèwà hù. Àwọn ànímọ́ tó jẹ́ apá kan èso ti ẹ̀mí yìí á jẹ́ ká yanjú èdèkòyédè tó bá wáyé láàárín àwa àtàwọn míì, ó sì yàtọ̀ sí àwọn iṣẹ́ ti ara tó máa ń fa ìpínyà.

  • “Jèhófà Kan Ṣoṣo” Ń kó Ìdílé Rẹ̀ Jọ
    Ilé Ìṣọ́—2012 | July 15
    • 9. Báwo la ṣe lè yẹ ara wa wò ká lè mọ̀ bóyá òótọ́ ni à ń “fi taratara sakun láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́”?

      9 Nítorí èyí, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ bi ara rẹ̀ pé: ‘Báwo ni mo ṣe ń fi taratara sakun tó “láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà”? Kí ni mo máa ń ṣe bí aáwọ̀ bá wà láàárín èmi àti ẹnì kan? Ṣé ńṣe ni mo máa ń rojọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ mi kí wọ́n lè gbè sẹ́yìn mi? Ṣé àwọn alàgbà ni mo máa ń retí pé kí wọ́n bá mi yanjú ọ̀ràn náà láìjẹ́ pé mo kọ́kọ́ lọ bá onítọ̀hún kí àwa méjèèjì sì yanjú ọ̀rọ̀ náà láàárín ara wa? Bí mo bá sì mọ̀ pé ẹnikẹ́ni ní ohun kan lòdì sí mi, ṣé mi ò kì í sá fún onítọ̀hún ká má bàa sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro náà?’ Bí a bá ń ṣe èyíkéyìí nínú àwọn ohun tá a mẹ́nu kàn yìí, ǹjẹ́ ó máa fi hàn pé à ń ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìpinnu Jèhófà láti tún kó ohun gbogbo jọ pọ̀ nínú Kristi?

      10, 11. (a) Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé ká wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará wa? (b) Irú ìwà wo ló máa mú ká wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn, ká sì máa rí ìbùkún Jèhófà gbà?

      10 Jésù sọ pé: “Nígbà náà, bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ, àti lẹ́yìn náà, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ. Bẹ̀rẹ̀ sí yanjú àwọn ọ̀ràn ní kíákíá.” (Mát. 5:23-25) Jákọ́bù kọ̀wé pé “èso òdodo ni a ń fún irúgbìn rẹ̀ lábẹ́ àwọn ipò tí ó kún fún àlàáfíà fún àwọn tí ń wá àlàáfíà.” (Ják. 3:17, 18) Torí náà, àyàfi tá a bá wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn nìkan la tó lè máa bá a nìṣó láti hùwà tó tọ́.

      11 Àpèjúwe kan rèé: Wọ́n fojú bù ú pé bí a bá pín gbogbo ilẹ̀ tó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè kan tí ogun ti ṣọṣẹ́ sí ọ̀nà mẹ́ta, ó ju ìdá kan lọ lára ilẹ̀ náà táwọn èèyàn lè máa fi ṣọ̀gbìn. Àmọ́, èyí kò ṣeé ṣe torí àwọn ohun abúgbàù tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ níbẹ̀. Bí ohun abúgbàù bá dún lórí ilẹ̀ táwọn àgbẹ̀ ti ń ṣọ̀gbìn, wọ́n á sá fi ibẹ̀ sílẹ̀, àtigbọ́bùkátà ìdílé á di ìṣòro fún wọn, ìyẹn á sì wá bẹ̀rẹ̀ sí í febi pa àwọn aráàlú. Lọ́nà kan náà, ó máa ṣòro láti mú kí àwọn ànímọ́ Kristẹni wa máa sunwọ̀n sí i bí ìwà wa bá mú kó ṣòro fún wa láti máa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará wa. Ṣùgbọ́n, tá a bá ń tètè dárí jini tá a sì ń ṣe ohun tó lè mú ká wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn, ńṣe là ń fira wa sípò táá mú ká máa rí ìbùkún Jèhófà gbà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́