ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 2/1 ojú ìwé 32
  • “Agbara Ti Ó Rekọja Ti Ẹ̀dá”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Agbara Ti Ó Rekọja Ti Ẹ̀dá”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 2/1 ojú ìwé 32

“Agbara Ti Ó Rekọja Ti Ẹ̀dá”

BAWO ni ijiya ti Kristẹni kan lè farada ti pọ tó? Lonii, awọn Kristẹni yika ayé dojukọ òṣì, ìdàrú idile, ìdàrú ero imọlara, aisan, ogun, ati inunibini. O ha bọgbọnmu lati reti pe ki wọn pa iwatitọ mọ laika gbogbo eyi si bi? Apọsiteli Pọọlu sọ pe ó bọgbọnmu. Ó kọwe pe: “Mo ni okun fun ohun gbogbo nipa oun ẹni ti ń fi agbara fun mi.”—Filipi 4:13, NW.

Itan ti fihan pe okun lati ọdọ Jehofa ti tó nitootọ fun ohun gbogbo. Fun apẹẹrẹ, lakooko ijọba Nazi ni Germany, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jiya inunibini rírorò. Wọn ha farada a bi? Iwe naa Les Bibelforscher et le nazisme (Awọn Akẹkọọ Bibeli ati Ijọba Nazi) sọ pe: “Laika gbogbo awọn ìluni, ihalẹmọni ati ifofinde si, laika ìtẹ́nilógo itagbangba, ifinisẹwọn ati àhámọ́ ninu ibudo iṣẹniniṣẹẹ si, Awọn Akẹkọọ Bibeli [Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa] ko jẹ́ yọnda araawọn lati di ẹni ti a ‘ń tún kọ́.’”

Ninu awọn ibudo iṣẹniniṣẹẹ, awọn Ẹlẹ́rìí ni a fi iyatọ si nipa awọn ami onigun mẹta alawọ aluko lara apa aṣọ wọn a sì dá wọn ya sọtọ fun akanṣe ìroròmọ́ni. Eyi ha bà wọn jẹ́ bi? Afiṣemọronu-ẹda Bruno Bettelheim ṣakiyesi pe wọn “kò fi iyì eniyan ati ọna ihuwa rere giga ti ó ṣàrà ọtọ han nikan, ṣugbọn ó tun jọ pe a daabobo wọn lodisi iriri kan naa ninu ibudo ti kii pẹ ṣẹpa awọn eniyan tí emi ati ọrẹ mi onimọ ifiṣemọronu-ati-ihuwasi-ẹ̀dá kà si awọn ẹni ti wọn lè tete mu araawọn bá ipo ayika wọn mu daradara.”

Bẹẹni, wọn ni ‘okun fun ohun gbogbo.’ Eeṣe? Nitori pe wọn gbarale Jehofa. Pọọlu sọ pe: “Awa ni iṣura yii ninu awọn koto àfamọ̀ṣe, ki agbara ti o rekọja ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọrun ki ó maṣe jẹ́ eyi ti o ti ọdọ awa tikaraawa jade.” (2 Kọrinti 4:7, NW) Bi iwọ ba ṣalabaapade ipo ti ń dánniwò, fi igbọkanle gbarale Jehofa fun iranlọwọ. Bi a o ti fun ọ lokun nipa agbara ti o rekọja ti ẹdá ti oun ń pese, iwọ yoo lè farada a.—Luuku 11:13.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́