-
Rí Ààbò Láàárín Àwọn Ènìyàn ỌlọrunÌmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
-
-
“Ẹ FI ÌFẸ́ WỌ ARA YÍN LÁṢỌ”
9. Báwo ni Jehofa ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ ní fífi ìfẹ́ hàn?
9 Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nitori ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kolosse 3:14) Pẹ̀lú oore-ọ̀fẹ́, Jehofa ti pèsè aṣọ yìí fún wa. Ní ọ̀nà wo? Àwọn Kristian lè fi ìfẹ́ hàn nítorí pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èso tí Ọlọrun ń fifúnni ti ẹ̀mí mímọ́ Jehofa. (Galatia 5:22, 23) Jehofa fúnra rẹ̀ ti fi ìfẹ́ tí ó ga jùlọ hàn nípa rírán Ọmọkùnrin bíbí kanṣoṣo rẹ̀ wá kí á baà lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Johannu 3:16) Ìfihàn ìfẹ́ tí ó ga jùlọ yìí pèsè àwòṣe kan fún wa ní fífi ànímọ́ yìí hàn. Aposteli Johannu kọ̀wé pé: “Bí ó bá jẹ́ pé bayii ni Ọlọrun ṣe nífẹ̀ẹ́ wa, nígbà naa awa fúnra wa wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe lati nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nìkínní kejì.”—1 Johannu 4:11.
10. Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní láti ọ̀dọ̀ “gbogbo ẹgbẹ́ awọn ará”?
10 Lílọ tí o bá ń lọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba yóò fún ọ ní àǹfààní títayọlọ́lá láti fi ìfẹ́ hàn. Ìwọ yóò pàdé onírúurú ọ̀pọ̀ ènìyàn níbẹ̀. Kò sí iyèméjì pé púpọ̀ lára wọn yóò fà ọ́ mọ́ra lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Dájúdájú, àwọn ànímọ́ yàtọ̀ àní láàárín àwọn olùjọ́sìn Jehofa. Bóyá tẹ́lẹ̀ ìwọ wulẹ̀ ń yẹra fún àwọn ènìyàn tí kò ṣàjọpín ìwà-ànímọ́ rẹ tàbí àwọn ohun tí o lọ́kàn ìfẹ́ sí. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Kristian níláti “máa ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ awọn ará.” (1 Peteru 2:17) Nítorí náà, fi í ṣe góńgó rẹ láti di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí ó wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba—kódà àwọn tí ọjọ́-orí, ànímọ́, ẹ̀yà-ìran, tàbí ìpele ẹ̀kọ́ wọn lè yàtọ̀ sí tìrẹ. Ó ṣeé ṣe pé ìwọ yóò ríi pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn tayọ nínú àwọn ànímọ́ kan tí ń fanimọ́ra.
11. Èéṣe tí ìyàtọ̀ nínú ànímọ́ láàárín àwọn ènìyàn Jehofa kò fi yẹ kí ó kó ìdààmú bá ọ?
11 Ìyàtọ̀ àwọn ànímọ́ nínú ìjọ kò yẹ kí ó dà ọ́ láàmú. Láti ṣàpèjúwe, ronú pé ọ̀pọ̀ ọkọ ni ó ń rìnrìn-àjò lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ ní ojú títì. Kì í ṣe gbogbo wọn ní ń sáré bákan náà, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe gbogbo wọ́n ni ó dára bákan náà. Àwọn kan ti rìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ kìlómítà, ṣùgbọ́n bí ìwọ, àwọn kan ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni. Bí ó ti wù kí ó rí, láìka àwọn ìyàtọ̀ wọ̀nyí sí, gbogbo wọn ní wọ́n ń rìn lójú títì. Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó parapọ̀ di ìjọ kan. Kì í ṣe gbogbo wọn ni wọ́n mú àwọn ànímọ́ Kristian dàgbà lọ́nà kan náà. Síwájú sí i, kì í ṣe gbogbo wọn ni wọ́n rí bakan náà níti ara-ìyára àti ti èrò-inú. Àwọn kan ti ń jọ́sìn Jehofa fún ọ̀pọ̀ ọdún; àwọn kan ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Síbẹ̀, gbogbo wọn ń rìn lójú ọ̀nà tí ó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun, tí a so “pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí ninu èrò-inú kan naa ati ninu ìlà ìrònú kan naa.” (1 Korinti 1:10) Nítorí náà, wo àwọn ànímọ́ dídára àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú ìjọ kì í ṣe àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó wọn. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú ọkàn-àyà rẹ yọ̀, nítorí ìwọ yóò mọ̀ pé nítòótọ́ Ọlọrun wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Àti pé dájúdájú ibi tí o fẹ́ láti wà nìyí.—1 Korinti 14:25.
12, 13. (a) Bí ẹnì kan nínú ìjọ bá ṣẹ̀ ọ́, kí ni o lè ṣe? (b) Kí ni ìdí tí ó fi ṣe pàtàkì pé kí a máṣe gbin ìbínú sínú?
12 Níwọ̀n bí gbogbo ènìyàn ti jẹ́ aláìpé, nígbà mìíràn ẹnì kan nínú ìjọ lè sọ tàbí ṣe ohun kan tí ó bí ọ nínú. (Romu 3:23) Ọmọ-ẹ̀yìn náà Jakọbu sọ bí ó ti rí gan-an pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Bí ẹni kan kò bá kọsẹ̀ ninu ọ̀rọ̀, ẹni yii jẹ́ ènìyàn pípé.” (Jakọbu 3:2) Báwo ni ìwọ yóò ṣe hùwàpadà bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ ọ́? Òwe Bibeli kan sọ pé: “Ìmòye ènìyàn mú un lọ́ra àti bínú; ògo rẹ̀ sì ni láti ré ẹ̀ṣẹ̀ kọjá.” (Owe 19:11) Láti ní ìmòye túmọ̀ sí láti rí ju ohun tí ó hàn níta nínú ọ̀ràn kan, láti lóye àwọn ìdí tí ó mú kí ẹnì kan sọ̀rọ̀ tàbí hùwà ní ọ̀nà pàtó kan. Ọ̀pọ̀ jùlọ lára wa ń lo ìmòye láti fi wí àwíjàre fún àwọn àṣìṣe wa. Èéṣe tí a kò fi lò ó láti lóye kí a sì fi bo àwọn àìpé àwọn ẹlòmíràn?—Matteu 7:1-5; Kolosse 3:13.
13 Máṣe gbàgbé pé a gbọ́dọ̀ dáríji àwọn ẹlòmíràn bí àwa fúnra wa yóò bá gba ìdáríjì Jehofa. (Matteu 6:9, 12, 14, 15) Bí a bá ń ṣe òtítọ́, a óò bá àwọn ẹlòmíràn lò ní ọ̀nà onífẹ̀ẹ́. (1 Johannu 1:6, 7; 3:14-16; 4:20, 21) Nítorí náà, bí o bá bá ìṣòro pàdé pẹ̀lú ẹnì kan nínú ìjọ, jà lòdì sí gbígbin ìbínú sínú. Bí o bá wọ ìfẹ́ bí aṣọ, ìwọ yóò làkàkà láti yanjú ìṣòro náà, ìwọ kì yóò sì lọ́ra láti tọrọ àforíjì bí o bá ti ṣẹ àwọn ẹlòmíràn.—Matteu 5:23, 24; 18:15-17.
14. Àwọn ànímọ́ wo ni a gbọ́dọ̀ fi wọ ara wa ní aṣọ?
14 Aṣọ wa nípa tẹ̀mí níláti ní nínú àwọn ànímọ́ mìíràn tí ó sopọ̀ pẹ́kípẹ́kí mọ́ ìfẹ́. Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inúrere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú, ìwàtútù, ati ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.” Àwọn ìwà-ànímọ́ wọ̀nyí, tí ó rọ̀gbà yí ìfẹ́ ká, jẹ́ apá kan “àkópọ̀-ìwà titun” ti ìwà-bí-Ọlọ́run. (Kolosse 3:10, 12) Ìwọ yóò ha ṣe ìsapá náà láti wọ ara rẹ láṣọ ní ọ̀nà yìí? Ní pàtàkì bí ìwọ bá fi ìfẹ́ni ará wọ ará rẹ láṣọ ni ìwọ lè ní àmì ìdánimọ̀ ti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, nítorí òun wí pé: “Nipa èyí ni gbogbo ènìyàn yoo fi mọ̀ pé ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Johannu 13:35.
-
-
Rí Ààbò Láàárín Àwọn Ènìyàn ỌlọrunÌmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
-
-
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 165]
-