-
Àwọn Ohun Arùfé-Ìṣekúṣe-Sókè—Ṣé Nǹkan Ṣeréṣeré Lásán ni Wọ́n?Jí!—2002 | July 8
-
-
Fífọkàn yàwòrán ìbálòpọ̀ lè ba ìjọsìn wa sí Ọlọ́run jẹ́. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín . . . di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà.”—Kólósè 3:5.
Níbẹ̀, Pọ́ọ̀lù so níní ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo mọ́ ojúkòkòrò, èyí tó jẹ́ níní ìfẹ́ àìníjàánu fún ohun tí kì í ṣe tẹni.a Ojúkòkòrò jẹ́ oríṣi ìbọ̀rìṣà kan. Kí nìdí? Nítorí pé olójú kòkòrò èèyàn máa ń fi ohun tó ń fẹ́ yẹn ṣáájú ohunkóhun mìíràn, títí kan Ọlọ́run. Àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè máa ń mú kéèyàn ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ohun téèyàn ò ní. Òǹkọ̀wé kan nípa ìsìn sọ pé: “Wàá fẹ́ láti mọ̀ nípa ọ̀nà táwọn ẹlòmíràn ń gbà ní ìbálòpọ̀. . . . Kò sóhun mìíràn tá á máa gbà ẹ́ lọ́kàn ju ìfẹ́ ọkàn àìníjàánu láti gbádùn ohun tí kì í ṣe tìẹ. . . . Ohun téèyàn bá ń nífẹ̀ẹ́ sí lójú méjèèjì ló máa di ọlọ́run tí onítọ̀hún ń jọ́sìn.”
-
-
Àwọn Ohun Arùfé-Ìṣekúṣe-Sókè—Ṣé Nǹkan Ṣeréṣeré Lásán ni Wọ́n?Jí!—2002 | July 8
-
-
a Ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ tó bójú mu kọ́ ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ níbí, ìyẹn ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ tó bójú mu pẹ̀lú ọkọ ẹni tàbí aya ẹni.
-